Wọ́n Rí I Pé Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Nìyí

Ìgbà tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù ni Juana Ventura bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1960 ní Odò Ozama. Lọ́jọ́ kan, pásítọ̀ ajíhìnrere kan nílùú Santo Domingo fẹ́ kí wọ́n fi í sí àtìmọ́lé, ó ní “ó ń kó àwọn ọmọ ìjọ òun lọ.” Àmọ́, torí kó lè mú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní onírọ́, kó sì tún dójú ti Juana, ó ní kó wá dáhùn àwọn ìbéèrè kan níwájú àwọn ọmọ ìjọ òun nípa ohun tuntun tó ń kọ́.

Juana sọ pé: “Ó bi mí ní ìbéèrè mẹ́ta.” Ó ní: “‘Kí ló dé tí ẹ kì í dìbò? Kí ló dé tí ẹ kì í jagun? Kí nìdí tí ẹ fi ń pera yín ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà?’ Gbogbo ọmọ ìjọ rẹ̀ ló ń ṣí Bíbélì wọn bí mo ṣe ń fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè náà lọ́kọ̀ọ̀kan, oun tí wọ́n kà níbẹ̀ sì yà wọ́n lẹ́nu. Ọ̀pọ̀ nínú wọn wá rí i pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ nìyí. Bí gbogbo wọn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn, àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] lára wọn sì ya ara wọn sí mímọ́.”  Ohun àrà ọ̀tọ̀ tó wáyé yìí mú kí iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ gbilẹ̀ nílùú Santo Domingo.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Múra Tán Láti Dúró sí Orílẹ̀-Èdè Dominican

Nǹkan ò rọgbọ rárá lágbo òṣèlú lẹ́yìn tí wọ́n pa Trujillo. Ìwé Ọdọọdún 1963 [Gẹ̀ẹ́sì] sọ pé: ‘Àwọn sójà kún ìgboro, léraléra làwọn èèyàn ń yanṣẹ́ lódì tí wọ́n sì ń da ìgboro rú.’ Láìka gbogbo rògbòdìyàn òṣèlú yìí sí, iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn kò dáwọ́ dúró. Nígbà tí ọdún iṣẹ́ ìsìn 1963 sì máa fi parí, iye akéde ti di ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà àti márùndínlọ́gọ́ta [1,155].

Nígbà tí Arákùnrin Nathan Knorr ti oríléeṣẹ́ wa wá sí Orílẹ̀-èdè Dominican ní ọdún 1962, ó ṣètò bí a ṣe máa ra ilẹ̀ tá a máa fi kọ́lé tó tóbi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ torí ìbísí tó ń yára kánkán lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Pẹ̀tẹ́ẹ̀sì alájà méjì àti Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ni wọ́n kọ́ sórí ilẹ̀ náà. Arákùnrin Frederick Franz tóun náà wá láti oríléeṣẹ́ wa ló sọ àsọyé ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun náà lọ́jọ́ Sátidé, October 12, ọdún 1963. Ó wá ṣe kedere pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti múra tán láti dúró sí Orílẹ̀-èdè Dominican. Kété lẹ́yìn tá a ya ẹ̀ka ọ́fíìsì náà sí mímọ́ ni Harry àti Paquita Duffield dé, àwọn ni míṣọ́nnárì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìjọba orílẹ̀-èdè Cuba lé kúrò gbẹ̀yìn.

Wọ́n Ń Gbèrú Láìka Rúkèrúdò Sí

Ní April 24, ọdún 1965, àwọn kan tún gbógun dìde láti gbàjọba lórílẹ̀-èdè náà. Láìka gbogbo rúkèrúdò tó wáyé lẹ́yìn náà sí, àwọn èèyàn Jèhófà ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Lọ́dún 1970, ìjọ mẹ́tàlélọ́gọ́ta [63] tí àròpọ̀ akéde wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta, ọ̀ọ́dúnrún àti méjìdínlọ́gọ́rin [3,378] ló ti wà lórílẹ̀-èdè náà. Ó lé ní ìdajì lára wọn tó wá sínú òtítọ́ láàárín ọdún 1965 sí 1970. Ìwé Ọdọọdún 1972 [Gẹ̀ẹ́sì] sọ pé: “Irú èèyàn tí wọ́n jẹ́ yàtọ̀ síra, àwọn mẹkáníìkì, àgbẹ̀, awakọ̀ èrò, àwọn tó ń ṣírò owó, kọ́lékọ́lé, káfíńtà, agbẹjọ́rò, dókítà eyín, títí kan àwọn tó fìgbà kan jẹ́ olóṣèlú pàápàá wà lára àwọn tó wá sínú òtítọ́. Ẹ̀kọ́ òtítọ́ àti ìfẹ́ tí gbogbo wọ́n ní fún Jèhófà ló mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan.”