A Ní Orúkọ Rere

Ó ti tó nǹkan bí àádọ́rin [70] ọdún báyìí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà ní Orílẹ̀-èdè Dominican. Ní gbogbo àkókò yìí, a ti ní orúkọ rere níbẹ̀. Àwọn èèyàn sábà máa ń fúnra wọn lọ bá àwọn ará tó wà lóde ẹ̀rí pé kí wọ́n fún wọn láwọn ìwé wa. Wọ́n sì sábà máa ń sọ pé: “Ẹ̀sìn yìí wù mí” tàbí “Ohun tí Bíbélì sọ làwọn èèyàn yín máa ń ṣe.”

Àpẹẹrẹ kan ni ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sórí ilẹ̀ tí arákùnrin kan fún ètò Ọlọ́run. Nígbà tí arákùnrin náà fẹ́ lọ ṣe ìwé ilẹ̀ ọ̀hún, ó rí i pé ẹnì kan ti gbọ̀nà ẹ̀bùrú ṣe ìwé náà, ẹni náà sì fẹ̀sùn kan arákùnrin wa pé ó fẹ́ gba ilẹ̀ mọ́ òun lọ́wọ́. Ni wọ́n bá gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́. Ẹjọ́ náà fẹ́ le díẹ̀ torí pé ọkùnrin náà kó ìwé tí wọ́n ṣe lórúkọ rẹ̀ jáde láti fi hàn pé òun ló ni ilẹ̀ náà.

Bí ẹjọ́ náà ṣe ń lọ lọ́wọ́, adájọ́ náà ní kí agbẹjọ́rò wa ṣàlàyé ẹni tó ń ṣojú fún. Nígbà tí agbẹjọ́rò náà ṣàlàyé pé àjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun ń ṣojú fún, adájọ́ náà fèsì pé: “Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kò yẹ ká ṣiyè méjì pé òótọ́ ni agbẹjọ́rò náà sọ. Mo mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì mọ̀ pé ẹ ò jẹ́ bá wọn nídìí ẹ̀tàn. Wọn ò jẹ́ lu ẹnikẹ́ni ní jìbìtì, kí wọ́n wá gba ohun tí kì í ṣe tiwọn.”

Nígbà tí ilé ẹjọ́ gbé gbogbo ẹ̀rí tó wà nílẹ̀ yẹ̀ wò, ó wá ṣe kedere pé ayédèrú ni ìwé ilẹ̀ tó wà lọ́wọ́ ẹni tó ń bá wa ṣẹjọ́. Torí náà, adájọ́ yìí dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre. Agbẹjọ́rò àwa Ẹlẹ́rìí wá sọ pé: “Kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ rèé tá a máa jàre nílé ẹjọ́. Tọ́rọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá dé ilé ẹjọ́ èyíkéyìí lórílẹ̀-èdè yìí, wọ́n sábà máa ń fi ọ̀wọ̀ wa wọ̀ wá.”

À Ń Retí Bí Ọjọ́ Ọ̀la Ṣe Máa Rí

A ò tíì mọ bí iye àwọn olódodo èèyàn tó máa wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látinú Bíbélì tí wọ́n sì máa jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́  ṣe máa pọ̀ tó. Àmọ́ ní báyìí, à ń sa gbogbo ipá wa láti wá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Orílẹ̀-èdè Dominican lo wákàtí tó lé ní mílíọ̀nù mọ́kànlá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lọ́dún 2013. Iye àwọn tí wọ́n kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànléláàádọ́rin, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún àti méjìlélógún [71,922]. Inú wa tún dùn láti rí i pé ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àti mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [9,776] làwọn tó kópa nínú onírúurú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà. Ní oṣù August ọdún yẹn kan náà, iye akéde tó ń wàásù déédéé jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì, ọ̀ọ́dúnrún àti mọ́kànlélọ́gbọ̀n [35,331]. Síbẹ̀, ẹ̀rí wà pé ó ṣeé ṣe kí ìbísí tó kàmàmà wà lọ́jọ́ iwájú torí pé iye àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínláàádóje, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àti mẹ́rìndínlógún [127,716].

Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ló ti wà nínú bí iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe ń lọ sí ní Orílẹ̀-èdè Dominican, tá a bá fi wéra pẹ̀lú bó ṣe rí lọ́jọ́ Sunday oṣù April ọdún 1945, nígbà tí Lennart àti Virginia Johnson kọ́kọ́ dé tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lórílẹ̀-èdè náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Orílẹ̀-èdè Dominican mọyì ogún tẹ̀mí wọn gan-an. Wọ́n mọyì bí àwọn olóòótọ́ olùjọ́sìn Ọlọ́run tó kọ́kọ́ wà ní orílẹ̀-èdè náà ṣe lo ìgboyà tí wọ́n sì yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún mọyì àǹfààní tí wọ́n ní báyìí láti máa ‘jẹ́rìí kúnnákúnná nípa ìjọba Ọlọ́run.’ (Ìṣe 28:23) Wọ́n ń retí ìgbà tí gbogbo àwọn ará tó wà ní erékùṣù yìí àtàwọn ará wọn kárí ayé máa pa ohùn wọn pọ̀ láti kọrin pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ti di ọba! Kí ilẹ̀ ayé kún fún ìdùnnú. Kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù máa yọ̀.”—Sáàmù 97:1.