Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Iwe Odoodun Awa Elerii Jehofa​—2015

 ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Alaye Soki Nipa Orile-Ede Dominican

Alaye Soki Nipa Orile-Ede Dominican

Ilẹ̀ Erékùṣù Hispaniola ni Orílẹ̀-èdè Dominican àti Haiti wà. Nǹkan bí ìdá méjì nínú mẹ́ta lára erékùṣù náà jẹ́ ti Orílẹ̀-èdè Dominican. Ìdá kan yòókù sì jẹ́ ti orílẹ̀-èdè Haiti. Ara onírúurú ohun tó tún wà níbẹ̀ ni àwọn igbó kìjikìji, àwọn òkè gíga, irà tó ní àwọn igi etídò àti aṣálẹ̀. Òkè Pico Duarte ló ga jù lára àwọn òkè tó wà lórílẹ̀-èdè náà, gíga rẹ̀ tó ilé alájà ẹgbẹ̀rún kan àti méjìlélógójì [1,042]. Yanrìn funfun tẹ́ rẹrẹ lọ láwọn etíkun orílẹ̀-èdè náà. Àwọn àfonífojì tó wà nínú ìlú náà sì dára fún ohun ọ̀gbìn. Ọ̀kan lára àwọn àfonífojì náà ni Àfonífojì Cibao.

Àwọn Èèyàn Ilẹ̀ Yúróòpù àti Áfíríkà ni ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà lórílẹ̀-èdè náà ti ṣẹ̀ wá. Àwọn ẹ̀yà kéréje mélòó kan sì tún wà níbẹ̀. Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Haiti ló pọ̀ jù lára wọn.

Èdè Èdè Sípáníìṣì ni èdè àjùmọ̀lò wọn.

Àwọn ará ń gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ alárinrin

 Iṣẹ́ Oúnjẹ Òòjọ́ Àwọn ilé iṣẹ́ tó ń mówó wọlé jù níbẹ̀ ni ilé iṣẹ́ ìwakùsà, ilé iṣẹ́ tó ń ṣe ṣúgà àti àwọn ilé iṣẹ́ tó ń ṣọ̀gbìn kọfí àti ewé tábà. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìgbafẹ́ àtàwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá míì níbẹ̀ ti jẹ́ kí ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè náà gbé pẹ́ẹ́lí sí i.

Ojú Ọjọ́ Ooru fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ máa ń mú ní gbogbo erékùṣù yìí jálẹ̀ ọdún. Òjò sábà máa ń rọ̀ gan-an lápá àríwá tó fi mọ́ ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè náà tí òkè pọ̀ sí, àmọ́ òjò kì í fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ láwọn àgbègbè tó sún mọ́ aṣálẹ̀. Ìjì líle àti ìjì òjò máa ń bì lu erékùṣù náà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.

Àṣà Ìrẹsì, ẹ̀wà àtàwọn ewébẹ̀ wà lára oúnjẹ tó wọ́pọ̀ níbẹ̀. Àwọn aráàlú Dominican tún fẹ́ràn èso, ata, dòdò, ẹja àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n ń pa nínú òkun. Ìwọ̀nyí sì máa ń wà nínú oúnjẹ tí wọ́n gbádùn jù lọ, èyí tí wọ́n ń pè é ní La Bandera Dominicana tó túmọ̀ sí àsíá Orílẹ̀-èdè Dominican. Àwọn tó ń gbé láwọn erékùṣù sábà máa ń gbádùn bọ́ọ̀lù tí wọ́n ń fi ọ̀pá gbá. Wọ́n tún máa ń gbádùn orin àti ijó, pàápàá ijó tí wọ́n ń pè ní merengue. Àwọn ohun èlò orin tó wọ́pọ̀ gan-an níbẹ̀ ni gìtá, onírúurú ìlú àti fèrè, títí kan marimba.