Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Iwe Odoodun Awa Elerii Jehofa​—2015

 ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

A Nilo Awon Oniwaasu Pupo Si I

A Nilo Awon Oniwaasu Pupo Si I

A Mú Ìhìn Rere Dé Àwọn Ibi Jíjìnnà Réré

Nígbà tó yá, àwọn míṣọ́nnárì míì tún dé, lára wọn ni Pete Paschal, Amos àti Barbara Parker pẹ̀lú Richard àti Belva Stoddard tí wọ́n ti sìn ní orílẹ̀-èdè Bòlífíà rí, títí kan Jesse àti Lynn Cantwell láti orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà. Àwọn míṣọ́nnárì yìí kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìwàásù tó ń yára gbèrú náà. Nígbà tó fi máa di ọdún 1973, iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ń lọ ní pẹrẹu láwọn ìlú kéékèèké àtàwọn ìlú ńláńlá káàkiri Orílẹ̀-èdè Dominican, àmọ́ iṣẹ́ ìwàásù ò tíì dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ń gbé láwọn ìgbèríko. Torí náà, a ṣètò bá a ṣe máa mú ìhìn rere dé àwọn ìgbèríko. Nígbà tí wọ́n ní kí àwọn èèyàn yọ̀ǹda ara wọn fún oṣù méjì láti lọ wàásù láwọn ìgbèríko yìí, àwọn aṣáájú-ọ̀nà mọ́kàndínlógún [19] ló yọ̀ǹda ara wọn. Ní oṣù December ọdún 1973 sí oṣù January ọdún 1977, wọ́n yan àwọn aṣáájú-ọ̀nà mélòó kan pa pọ̀ láti lọ wàásù láwọn ibi tí a kò tíì fi bẹ́ẹ̀ wàásù dé.

“Tá a bá fún wọn níwèé wa, a máa ń gba adìyẹ, ẹyin àti èso dípò owó”

Aṣáájú-ọ̀nà kan tó kópa nínú iṣẹ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí sọ pé: “Tá a bá ti báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ látinú Bíbélì tá a sì fún wọn níwèé lọ́jọ́ àkọ́kọ́, tó bá di ọjọ́ kejì, a máa ń pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Torí pé àwọn tó ń gbé láwọn ìgbèríko ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, nígbà tá a bá fún wọn níwèé wa, a máa ń gba adìyẹ, ẹyin àti èso dípò owó. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ebi ò fìgbà kankan pa wá.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí wọ́n máa gbọ́ kẹ́nì kan ka Bíbélì sí wọn létí. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tiẹ̀ ti sọ fáwọn kan  pé Jèhófà ni Èṣù. Ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Sáàmù 83:18 tó sọ pé: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé”! Láwọn ibì kan, àwọn èèyàn fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì débi pé a ṣètò ìpàdé fún gbogbo èèyàn.

Àwọn Míṣọ́nnárì Míì Dé, A sì Kọ́ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tuntun

Ní oṣù September ọdún 1979, Arákùnrin Abigail Pérez àti Georgina ìyàwó rẹ̀ dé sí orílẹ̀-èdè náà. Míṣọ́nnárì làwọn náà, iṣẹ́ alábòójútó àyíká ni wọ́n sì ń ṣe. Nígbà tó di ọdún 1987, Tom àti Shirley Dean tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ yege ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì wá ran àwọn ará lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣe àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí wọ́n wá láti erékùṣù Puerto Rico tún ṣèrànwọ́ gan-an. Ní oṣù August ọdún 1988, wọ́n rán Reiner àti Jeanne Thompson wá sí Orílẹ̀-èdè Dominican, ibẹ̀ sì ni orílẹ̀-èdè karùn-ún tí wọ́n ti wá ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì.

Lọ́dún 1989, ìpíndọ́gba iye akéde ti di ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá ó lé mọ́kànlélọ́gọ́rin [11,081], ẹ̀rí sì wà pé ìbísí ṣì máa wáyé torí pé iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ròyìn jẹ́ ọ̀kẹ́ kan, irínwó àti mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún [20,494]. Ìbísí tó wáyé yìí mú kí àwọn ohun kan pọn dandan. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀ka ọ́fíìsì tí à ń lò nígbà yẹn wúlò fún wa gan-an, àmọ́ nígbà tó fi máa di ọdún 1987 sí 1989, kò tó wá lò mọ́. Reiner Thompson sọ pé, “ibẹ̀ kún àkúnya débi pé ó wá di dandan pé ká wá àwọn ilé míì sí i, ká sì máa lo àwọn ilé ìkẹ́rùsí káàkiri ìlú náà.”

Reiner tún sọ pé: “Kò rọrùn rárá láti rí ilẹ̀ tó dáa tá a lè fi kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun. Àmọ́ ọ̀gbẹ́ni oníṣòwò kan tó gbọ́ pé à ń wá ilẹ̀ kàn sí wa. Ó sọ fún wa pé òun fẹ́ ta  àwọn ilẹ̀ kan tó dáa gan-an, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan lòun sì fẹ́ tà á fún. Ìgbà kan wà tó ​ń ṣòwò aṣọ rírán, Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni akọ̀wé rẹ̀ àtàwọn kan lára àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ nígbà yẹn. Ní gbogbo ọdún tó fi gbà wọ́n síṣẹ́, ó kíyè sí i pé wọ́n yàtọ̀ sáwọn òṣìṣẹ́ yòókù, olóòótọ́ èèyàn ni wọ́n, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fúnni. Ìyẹn wú u lórí gan-an. Torí pé kò kóyán àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kéré rárá, ó dín iye owó tó ta ilẹ̀ náà fún wa kù.” A ra ilẹ̀ ọ̀hún ní oṣù December ọdún 1988, a sì tún ra àwọn ilẹ̀ mẹ́ta míì nítòsí ibẹ̀ nígbà tó yá. Lápapọ̀, éékà ilẹ̀ méjìlélógún [22] ni wọ́n kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì náà àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí.

Ọ̀pọ̀ àwọn ará lórílẹ̀-èdè náà àti láti ilẹ̀ òkèèrè ló lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ kíkọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ tuntun náà. Ìgbà tí Arákùnrin Carey Barber, Theodore Jaracz àti Gerrit Lösch tí wọ́n wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí wá ní oṣù November ọdún 1996 la ya àwọn ilé náà sí mímọ́, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló sì kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Sátidé náà. Lọ́jọ́ kejì, a tún ṣe àwọn àkànṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ní méjì lára àwọn pápá ìṣeré tó tóbi jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà, àwọn tó rìn yí ká ọ́fíìsì tuntun yìí lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000].

Wọ́n “Rékọjá Wá sí Makedóníà”

Tí a kò bá sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ àwọn ará tó wá sí Orílẹ̀-èdè Dominican láti wá sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, a jẹ́ pé ìtàn àwa èèyàn Jèhófà lórílẹ̀-èdè náà kò tíì pé nìyẹn. Ṣe ló dà bíi pé wọ́n “rékọjá wá sí Makedóníà” bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kó wá síbẹ̀ lọ́dún 1987 sí 1989 nígbà tí wọ́n gbọ́ pé iṣẹ́ ìwàásù ń méso rere jáde níbẹ̀, àwọn á sì lè máa kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Ìṣe 16:9) Bí àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn yìí ṣe ń sọ fún àwọn míì nípa bí iṣẹ́ ìkórè tí wọ́n ń ṣe ní Orílẹ̀-èdè Dominican ṣe ń fún wọn láyọ̀, èyí mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ará tún ṣí wá síbẹ̀ lọ́dún 1990 sí ọdún 1999.

 Bí àpẹẹrẹ, látọdún 2001 ni Stevan àti Miriam Norager tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Denmark ti ń sìn ní Orílẹ̀-èdè Dominican. Ṣáájú ìgbà yẹn, Miriam àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin ti wá sìn lórílẹ̀-èdè náà fún ọdún kan àtààbọ̀. Kí ló mú kí tọkọtaya yìí kó lọ síbi tó jìnnà réré tí èdè àti àṣà ibẹ̀ yàtọ̀ sí tiwọn? Miriam sọ pé: “Inú ìdílé tó fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan tẹ̀mí ni wọ́n ti tọ́ wa dàgbà, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe làwọn òbí wa nígbà tí wọ́n ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, wọ́n sì di aṣáájú-ọ̀nà déédéé lẹ́yìn tí wọ́n bímọ. Gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń gbà wá níyànjú pé ká ṣe gbogbo nǹkan tá a bá lè ṣe fún Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.”

Stevan àti Miriam ti di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe látọdún 2006, wọ́n sì ti kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Stevan sọ pé: “Ìbùkún tá a rí níbẹ̀ kò lóǹkà. Àwọn ìṣòro tàbí àìlera wa kò tó nǹkan tá a bá fi wé àwọn ìrírí alárinrin tá a  ní àti ayọ̀ tá a rí bá a ṣe ń ran àwọn olóòótọ́ èèyàn lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. A tún ti láwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n dà bí ọmọ ìyá fún wa. Iṣẹ́ ìsìn tá a wá ṣe ní Orílẹ̀-èdè Dominican ti jẹ́ ká túbọ̀ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti sùúrù. Bá a sì ṣe jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ wa lọ́rùn ti fún ìgbàgbọ́ wa lókùn, ó sì ti jẹ́ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.”

Ó lé lógún ọdún ti Jennifer Joy ti wà níbẹ̀, ó ń ran àwọn tó ń lo èdè adití lọ́wọ́

Ọ̀kan lára àwọn arábìnrin tí kò lọ́kọ tí wọ́n wá sìn ní Orílẹ̀-èdè Dominican láti ilẹ̀ òkèèrè ni Jennifer Joy. Lọ́dún 1992 tí Jennifer wá kí Arábìnrin Edith White, tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀ tó sì ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì, ó gbádùn iṣẹ́ ìwàásù gan-an. Ó tún bá àwọn arábìnrin míì tó wá  láti ilẹ̀ òkèèrè pàdé táwọn náà wá sìn níbi tí wọ́n ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i. Jennifer sọ pé: “Ojú máa ń tì mí, mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ láyà. Àmọ́ mo wò ó pé, ‘Táwọn míì bá lè ṣe é, ó yẹ kémi náà lè ṣe é.’”

Ọdún kan péré ni Jennifer kọ́kọ́ rò pé òun máa lò ní Orílẹ̀-èdè Dominican, àmọ́ nígbà tó yá, ó pinnu pé òun á kúkú dúró. Ó ti lé ní ogún ọdún báyìí tó ti ń sìn níbẹ̀. Ó ti ran ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè di olùjọsìn Jèhófà. Jennifer tún gbádùn bó ṣe mú kí ìtẹ̀síwájú bá lílo èdè adití lórílẹ̀-èdè náà, ó sì tún lọ́wọ́ nínú bí wọ́n ṣe ṣètò kíkọ́ àwọn èèyàn ní èdè náà.

‘Jèhófà ló ń tọ́jú mi títí di báyìí, kí wá nìdí tí màá fi ṣiyè méjì pé ó máa tọ́jú mi lọ́dún tó ń bọ̀?’

Báwo ni Jennifer ṣe ń rówó wá jíjẹ mímu? Ó ní: “Mo máa ń pa dà lọ ṣiṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Kánádà fún oṣù mélòó kan lọ́dọọdún. Mo ti ṣe onírúurú iṣẹ́ látìgbà yẹn wá, irú bíi fífọ fọ́tò, yíya fọ́tò, kíkun ilé, gbígbá àti fífọ ọ́fíìsì, fífi ẹ̀rọ ṣe iná mọ́tò àti ṣíṣe kápẹ́ẹ̀tì. Mo tún ti ṣe iṣẹ́ fífi àwọn arìnrìn-àjò mọ̀nà, abánitòwé ìrìn àjò, olùkọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti ògbufọ̀.” Jennifer fi bí nǹkan ṣe rí fún un wé ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ wà nínú aginjù. Ó ní: “Ọ̀rọ̀ ẹnu Jèhófà ló mú kí wọ́n wà láàyè. Ó sọ fún wọn pé òun máa tọ́jú wọn, ohun tó sì ṣe nìyẹn. Wọ́n ń rí oúnjẹ jẹ lójoojúmọ́, aṣọ àti bàtà wọn kò sì gbó. (Diu. 8:3-4) Jèhófà ṣèlérí pé òun máa tọ́jú àwa náà. (Mát. 6:33) Òun ló ń tọ́jú mi títí di báyìí, kí wá nìdí tí màá fi ṣiyè méjì pé ó máa tọ́jú mi lọ́dún tó ń bọ̀?”

Àwọn ajíhìnrere tó yọ̀ǹda ara wọn tó ẹgbẹ̀rún kan, wọ́n sì wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tó yàtọ̀ síra, irú bí Amẹ́ríkà, Austria, Japan, Poland, Puerto Rico, Rọ́ṣíà, Sípéènì, Sweden àti Taiwan. Ó tó ọgbọ̀n [30] orílẹ̀-èdè táwọn tó wá sìn níbi tá a ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i ti wá, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ àwọn ìjọ tó ń lo Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà, Chinese, Gẹ̀ẹ́sì, èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti, Italian, Russian àti Sípáníìṣì. Wọ́n sọ bíi ti àpọ́sítélì Pétérù pé: “Wò ó! Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì ti ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”— Máàkù 10:28.