Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Iwe Odoodun Awa Elerii Jehofa​—2015

 ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

“A Maa Ri Won”

“A Maa Ri Won”

“A Máa Rí Wọn Lọ́jọ́ Kan”

Ní nǹkan bí ọdún 1935, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Pablo González bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì ní àgbègbè Àfonífojì Cibao ní Orílẹ̀-èdè Dominican. Ó lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì fúngbà díẹ̀, àmọ́ ó pa ibẹ̀ tì nígbà tó rí i pé ìwà wọn ò bá ohun tóun kà nínú Ìwé Mímọ́ mu. Síbẹ̀, kò dẹ́kun kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fúnra rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn ẹlòmíì. Ọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn aládùúgbò rẹ̀ ló ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn àdúgbò tó wà nítòsí. Ó ta oko àtàwọn màlúù rẹ̀, ó sì ń fi owó tó rí níbẹ̀ rìnrìn àjò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe.

Lọ́dún 1942, ó kéré tán igba [200] ìdílé ni Pablo ń bẹ̀ wò ní àgbègbè náà, ó sì máa ń bá wọn ṣèpàdé déédéé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì bá Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan pàdé. Ó máa ń gba àwọn èèyàn níyànjú pé kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n sì máa fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò. Ọ̀pọ̀ wọn ló fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n jáwọ́ nínú sìgá mímu àti àṣà ìkóbìnrinjọ.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Celeste Rosario wà lára àwọn tó fetí sí ọ̀rọ̀ tí Pablo bá wọn sọ látinú Bíbélì. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17],  Negro Jiménez tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n màmá mi wà nínú ọ̀kan lára àwùjọ tí Pablo González ń darí. Lọ́jọ́ kan, ó wá sílé wa, ó ka àwọn ẹsẹ kan látinú Bíbélì, ìyẹn sì ni mo gbọ́ tí mo fi pinnu láti fi Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì sílẹ̀. Èdè Látìn ni wọ́n máa ń kà fún wa ní ṣọ́ọ̀ṣì, ìyẹn ò sì yé wa rárá. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Pablo González wá sọ́dọ̀ wa tó sì gbà wá níyànjú. Ó sọ fún wa pé: ‘A kì í ṣe ara èyíkéyìí nínú ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn tó yí wa ká yìí, àmọ́ a ní àwọn arákùnrin kárí ayé. A ò tíì mọ̀ wọ́n, a ò sì tíì mọ orúkọ tí wọ́n ń jẹ́, àmọ́ a máa rí wọn lọ́jọ́ kan.’”

Pablo ti ní àwùjọ tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí ìlú Los Cacaos Salcedo, Monte Adentro, Salcedo àti Villa Tenares. Lọ́dún 1948, nígbà tó wá wọkọ̀ nílùú Santiago, ó rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mélòó kan tí wọ́n ń wàásù lójú pópó, wọ́n sì fún un ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́. Nígbà tí Pablo tún pa dà wá sí Santiago, arábìnrin kan fún un ní ìwé méjì, ó sì pè é wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Ohun tó gbọ́ níbi Ìrántí Ikú Kristi yẹn wú u lórí gan-an, ó sì mú kó parí èrò pé òun ti rí òtítọ́ àti pé àwọn tí òun rí níbi ìpàdé yẹn gan-an làwọn tí òun ti ń wá látọjọ́ yìí.

Àwọn míṣọ́nnárì wa lọ bẹ àwọn tí Pablo ti ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wò. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀kan lára ibi tí wọ́n lọ, èèyàn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] ti ń dúró dè wọ́n níbẹ̀, inú àwọn tó wà níbẹ̀ sì dùn láti rí wọn. Lára wọn ti rin ìrìn àjò kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] kí wọ́n tó débẹ̀, àwọn tó gun ẹṣin rin ìrìn àádọ́ta [50] kìlómítà! Àwọn méjìdínlọ́gọ́rin [78] ló pésẹ̀ síbi tí wọ́n lọ lẹ́yìn náà, wọ́n sì tún lọ pàdé àwọn mọ́kàndínláàádọ́rin [69] níbòmíì.

Pablo kọ orúkọ nǹkan bí àádọ́jọ [150] èèyàn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì fún àwọn míṣọ́nnárì náà. Àwọn èèyàn yìí lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ìjọsìn Ọlọ́run, wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ti ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò. Ohun tí wọ́n nílò báyìí ò ju pé kí wọ́n wà létòlétò, kí wọ́n sì máa rí ìtọ́ni gbà. Celeste sọ pé: “A ṣèpàdé nígbà táwọn míṣọ́nnárì yẹn bẹ̀ wá wò. Wọ́n sì ṣètò bá a ṣe máa ṣèrìbọmi. Èmi ni wọ́n kọ́kọ́ rì bọmi nínú ìdílé wa. Lẹ́yìn náà ni wọ́n ṣèrìbọmi fún màmá mi, Fidelia Jiménez àti Carmen àbúrò mi.”

Ní September 23 sí 25, ọdún 1949, a ṣe àpéjọ àyíká àkọ́kọ́ nílùú Santiago ní Orílẹ̀-èdè Dominican. Àpéjọ yẹn mú ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣe kàyéfì nípa wa ló wá sí àpéjọ náà, èyí sì mú kí iye àwọn tó wá gbọ́ àsọyé fún gbogbo ènìyàn lọ́jọ́ Sunday wọ ọ̀tà-lé-rúgba [260]. Àwọn méjìdínlọ́gbọ̀n [28] ló ṣèrìbọmi. Àpéjọ ọlọ́jọ́ mẹ́ta yẹn mú kó túbọ̀ dá ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun lójú pé ètò yìí ni Ọlọ́run ń lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.