ÌWÉ ìròyìn Ilé Ìṣọ́ March 1, 1915 [Gẹ̀ẹ́sì] sọ pé: “Àsìkò ìdánwò la wà yìí. Ṣé torí ìyípadà ológo tí à ń wọ̀nà fún ní 1914, Ọdún Olúwa Wa, la ṣe ń ṣakitiyan àbí torí ìfẹ́ àti ìdúróṣinṣin tá a ní fún OLÚWA àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ àti àwọn ará wa!” Ní ọdún 1915, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan dààmú torí pé nǹkan ò rí bí wọ́n ṣe fẹ́ kó rí. Àmọ́, ogun tó ń lọ lọ́wọ́ ló fa ìdààmú fún ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn.

Ogun Ńlá tá a wá mọ̀ sí Ogun Àgbáyé Kìíní ti ń yí ilẹ̀ Yúróòpù ká. Ọwọ́ ogun náà tún lé sí i nígbà náà torí pé wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn ẹ̀rọ ogun. Ogun sì ń pa ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú nípakúpa. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1915, àwọn ará Jámánì ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọkọ̀ abẹ́ omi rìn káàkiri inú omi òkun tó yí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ká. Ní May 7, ọdún 1915, ọ̀kan lára àwọn ọkọ̀ abẹ́ omi yìí ri ọkọ̀ táwọn ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi ń kérò, èyí tí wọ́n ń pè ní Lusitania. Ẹ̀mí tó bá a rìn sì lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà [1,100].

A Kì Í Lọ́wọ́ sí Ogun

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kò fẹ́ lọ́wọ́ sí ogun yìí, àmọ́ wọn ò tíì fi bẹ́ẹ̀ lóye tó kún rẹ́rẹ́ nípa bó ṣe yẹ káwa Kristẹni ta kété sí ogun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fínnú fíndọ̀ wọṣẹ́ ológun, àwọn kan lára wọn ò kọ̀ jálẹ̀ nígbà tí wọ́n fipá mú wọn, wọ́n sì gbìyànjú láti máa ṣiṣẹ́ tí kò jẹ mọ́ ogun jíjà. Tí wọ́n bá fipá mú wọn lọ sójú ogun, àwọn kan gbà pé àwọn lè “yìnbọn gba orí àwọn ọ̀tá kọjá.”

Ilé Ìṣọ́ July 15, ọdún 1915 [Gẹ̀ẹ́sì], sọ ìtàn sójà ọmọ ilẹ̀ Hungary kan tó ṣèrìbọmi nígbà tí ọgbẹ́ tó fara gbà lójú ogun ń jinná lọ, tó sì pa dà síbi tí ogun ti le nígbà tó yá. Ìtàn náà sọ pé: “Àlàfo tó wà láàárín [àwọn sójà ọmọ ilẹ̀ Hungary] àtàwọn ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà kò ju ẹgbẹ̀rin [800] ẹsẹ̀ bàtà lọ. Wọ́n wá pàṣẹ fún wọn pé, ‘Ẹ máa fi ọ̀bẹ aṣóró tó wà lára ìbọn gún àwọn ọ̀tá.’ Ìpẹ̀kun apá òsì ni arákùnrin tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Hungary náà wà. Ó ń wá bó ṣe máa dáàbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, torí náà ohun tó lè ṣe kò ju pé kó fi ìbọn ọwọ́ rẹ̀ gbá ọ̀bẹ  aṣóró tó wà lọ́wọ́ ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà tó dojú kọ ọ́ dà nù. Àmọ́ ó kíyè sí i pé ohun tí ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà náà ń gbìyànjú láti ṣe nìyẹn . . . Ṣe ni ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà náà jẹ́ kí ọ̀bẹ náà bọ́ sílẹ̀, ó sì ń sunkún. Nígbà tí arákùnrin yìí tẹjú mọ́ ‘ọ̀tá’ tó ń bá jà, ó kíyè sí àmì ‘Àgbélébùú àti Adé’ tó fi ṣe ọ̀ṣọ́ sára ẹ̀wù rẹ̀! Ó wá rí i pé arákùnrin òun nínú Olúwa ni ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà náà!” *

Àpilẹ̀kọ kan tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Ojúṣe Kristẹni àti Ogun,” tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ September 1, 1915 [Gẹ̀ẹ́sì], sọ nípa bí àwa Kristẹni kì í ṣeé lọ́wọ́ sí ogun. Ó ní: “Téèyàn bá wọṣẹ́ ológun, tó sì wọ aṣọ ológun, ìyẹn fi hàn pé ó ti múra tán láti ṣe ojúṣe àti iṣẹ́ táwọn ọmọ ogun gbà láti ṣe, tá a sì mọ̀ mọ́ wọn. . . . Ǹjẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ní mú kí Kristẹni kan ṣe ohun tí kò tọ́?” Ó wá ṣe kedere nígbà tó yá pé kò yẹ kí àwa Kristẹni máa lọ́wọ́ sí ogun rárá.

Ìyípadà Tó Wáyé ní Oríléeṣẹ́ Wa

Ní ọdún 1915, a sọ fún àádọ́rin [70] lára àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní ìlú New York pé torí ipò ìṣúnná owó, wọ́n máa ní láti fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀ kí wọ́n sì máa bá iṣẹ́ ìsìn wọn lọ ní pápá. A sọ fún wọn pé: “Kò yẹ ká jẹ gbèsè, kò sì yẹ ká ṣàkóbá kankan fún iṣẹ́ yìí lápapọ̀; torí náà a pinnu láti dín ìnáwó kù nínú ohun gbogbo.”

Arákùnrin Clayton J. Woodworth àtàwọn arákùnrin méjì míì ló jọ fọwọ́ sí ìwé tí wọ́n kọ lórúkọ gbogbo “Àwọn Àádọ́rin Tó Ń Lọ” náà. A gbé lẹ́tà náà jáde nínú Ilé Ìṣọ́ May 1, 1915 [Gẹ̀ẹ́sì]. Àwọn tó ń lọ yìí sọ pé ‘inú àwọn dùn, àwọn sì dúpẹ́ fún ọ̀pọ̀ yanturu ìbùkún àti àǹfààní’ táwọn ti ní “gẹ́gẹ́ bí ara ‘Ìdílé Bẹ́tẹ́lì.’”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyípadà yìí kò rọrùn, ó jẹ́ káwọn ará yìí lè fi hàn bóyá lóòótọ́ ni wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin. Ṣé wọ́n á máa bá a  nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run ni àbí wọ́n á bínú? Arákùnrin Woodworth ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ, ó sì pa dà sí Bẹ́tẹ́lì nígbà tó yá. Lọ́dún 1919, òun ni olóòtú àkọ́kọ́ fún ìwé ìròyìn The Golden Age, tá a wá mọ̀ sí ìwé ìròyìn Jí! báyìí. Ó sì ṣe olóòtú ìwé ìròyìn náà títí di ọdún 1946.

Àǹfààní Láti Jára Mọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù

Jálẹ̀ ọdún tí nǹkan fi le koko yẹn, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ rọ àwọn ará wa pé kí wọ́n má ṣe dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró. Gbogbo àwọn tó ti gbọ́rọ̀ wa rí la tún pa dà fún láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. Ilé Ìṣọ́ December 15, 1915 [Gẹ̀ẹ́sì] sọ pé: “A ní àkọsílẹ̀ àwọn èèyàn jákèjádò orílẹ̀-èdè, tí wọ́n fi káàdì ránṣẹ́ láti béèrè fún ìwé wa. À dá a lábàá pé kẹ́ ẹ pa dà lọ wò wọ́n . . . kó máà jẹ́ pé wọ́n tún ti ronú gba ibòmíì.” Ìdí tá a sì fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká lè “koná mọ́ ìtara tí wọ́n ní fún Ọlọ́run àti fún Òtítọ́.”

Bíi ti òde òní, ó ṣe pàtàkì pé káwọn Kristẹni gbájú mọ ire Ìjọba Ọlọ́run nígbà yẹn. Ilé Ìṣọ́ February 15, ọdún 1915 [Gẹ̀ẹ́sì] sọ pé: “Ó yẹ kí àwa tá a wà lójúfò báyìí jẹ́ akíkanjú, ká sì máa lo okun wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.” Àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò. Ilé Ìṣọ́ yẹn tún sọ pé: “A ní láti máa ṣọ́nà. Kí la ó máa ṣọ́nà fún? Tá a bá ń ṣọ́nà, ó gba pé ká máa ṣọ́ ara wa ní pàtàkì jù lọ, ká má bàa kó sí àwọn ìdẹkùn òde ìwòyí.”

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 1916 gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n máa bá a nìṣó láti jẹ́ ẹni tó “le ní ìgbàgbọ́,” gẹ́gẹ́ bí Róòmù 4:20 ṣe sọ nínú Bíbélì Mímọ́. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ṣì ń bọ̀ wá fún àwọn olóòótọ́ níṣìírí lọ́dún 1916, torí ọdún náà ní àwọn àdánwò tó bá a rìn.

^ ìpínrọ̀ 4 Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi ń fi ohun ọ̀ṣọ́ tó ní àgbélébùú àti adé sí ara aṣọ wọn láti fi dá wọn mọ̀. Àmì yìí sì wà lójú ìwé àkọ́kọ́ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Nígbà tó fi máa di ọdún 1935, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò lo àmì àgbélébùú àti adé náà mọ́.