Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lẹ́yìn tó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní Òkun Pupa. Ó yẹ káwa pẹ̀lú máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Òótọ́ ni pé a lè rẹ̀wẹ̀sì tí ìṣòro bá dé bá wa. Ohun tó máa fún wa lókun tó sì máa tù wá nínú nírú àkókò bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa ronú lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa.

 Pàtàkì jù lọ lára àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa ni ìrètí tó dájú tá a ní pé ó máa mú gbogbo ohun tó ń fa ìrora àti ìbànújẹ́ kúrò. Ìṣòro yòówù ká ní, a mọ̀ pé Jèhófà kò ní fi wá sílẹ̀. Olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ wa ni Jèhófà, ó sì máa ń pèsè gbogbo ohun tá a nílò ká lè máa sìn ín tọkàntọkàn. Kì í já wa kulẹ̀ rárá torí pé òun ni “ibi ìsádi àti okun fún wa, ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.” (Sm. 46:1) Tá a bá ń ronú lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, a ó lè fara da ìṣòro tó le jù lọ pàápàá. Jálẹ̀ ọdún 2015, ẹ jẹ́ ká kún fún ayọ̀ bá a ṣe ń ronú lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, ká sì máa tipa bẹ́ẹ̀ “fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere; nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sm. 106:1.