Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Iwe Odoodun Awa Elerii Jehofa​—2015

 ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

Iyasimimo Eka Ofiisi Orile-Ede Siri Lanka

Iyasimimo Eka Ofiisi Orile-Ede Siri Lanka

ÀWỌN ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní orílẹ̀-èdè Siri Láńkà wọ aṣọ ìbílẹ̀ wọn, wọ́n sì ń kí àwọn àlejò káàbọ̀. Ilẹ̀ mọ́kàndínlógún [19] làwọn àlejò tí wọ́n jẹ́ àádóje [130] yìí ti wá, wọ́n wá ṣe ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní erékùṣù tó fani mọ́ra yìí. Àwọn ọmọdé mélòó kan kọ orin Ìjọba Ọlọ́run, gbogbo àwọn tó pésẹ̀ sì jọ gbádùn àṣà ìbílẹ̀ tí wọ́n fi dá wọn lára yá, oúnjẹ ìbílẹ̀, orin tó dùn létí àti àjọṣe ọlọ́yàyà láàárín àwa Kristẹni.

A ya ilé tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ yìí pẹ̀lú ti tẹ́lẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà ní ọjọ́ Sátidé, January 11, ọdún 2014. Ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún [893] làwọn tó wà níbẹ̀, wọ́n sì gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní èdè mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àtẹ́wọ́ dún ní àdúntúndún nígbà tí Arákùnrin Mark Sanderson tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí béèrè pé, “Ǹjẹ́ ó wù yín láti ya àwọn ilé tuntun yìí sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run?”

 Ẹgbẹ̀rún méje àti mọ́kàn-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [7,701] làwọn tó pésẹ̀ lọ́jọ́ kejì láti gbọ́ ohun tó wáyé ní ọjọ́ Sátidé àti àsọyé tí Arákùnrin Sanderson fi fún wọn níṣìírí. Wọ́n ṣe àtagbà ìpàdé yìí sí ibi márùn-ún míì tó tóbi ní orílẹ̀-èdè náà. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí àtagbà fídíò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ará jákèjádò erékùṣù náà láti rí ara wọn, kí wọ́n sì gbóhùn ara wọn bí wọ́n ṣe ń kọrin Ìjọba Ọlọ́run. Ó dájú pé ìkórajọpọ̀ mánigbàgbé yìí mú kí wọ́n ní “ìdùnnú ńláǹlà.”—Neh. 12:43.