Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

‘A Ti Ri Awon Ohun Agbayanu’

‘A Ti Ri Awon Ohun Agbayanu’

Arákùnrin kan tó jẹ́ afọ́jú ṣèrìbọmi

NÍ ÌGBÀ kan tí Jésù wo ọkùnrin kan tó jẹ́ arọ sàn, “ayọ̀ púpọ̀ jọjọ kún inú gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì kún fún ìbẹ̀rù, wọ́n wí pé: ‘Àwa ti rí ohun [àgbàyanu] lónìí!’” (Lúùkù 5:25, 26) Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run ń gbé ṣe lónìí nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n, ẹrú olóòótọ́ àti olóye àtàwọn olùjọsìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ jákèjádò ayé mú ká ní ìdí tó túbọ̀ pọ̀ sí i láti sọ ní àsọtúnsọ pé: ‘A ti rí àwọn ohun àgbàyanu.’