SÍTÉFÁNÙ ni ọkùnrin tó kúnlẹ̀ yìí. Ọmọ ẹyìn Jésù ni Sítéfánù, olóòótọ́ èèyàn sì ni. Ṣùgbọ́n wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí i nínú àwòrán yìí! Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń ju òkúta ńláńlá lù ú. Kí ló dé tí wọ́n fi kórìíra Sítéfánù tó bẹ́ẹ̀, débi tí wọ́n fi ń ṣe ohun búburú yìí sí i? Jẹ́ ká wò ó ná.

Ọlọ́run ti ń lo Sítéfánù láti ṣiṣẹ́ ìyanu. Èyí ń bí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí nínú, nítorí náà wọ́n ń bá a ṣawuyewuye nítorí pé ó ń kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún Sítéfánù ní ọgbọ́n tó pọ̀ gan-an, ó sì lo ọgbọ́n náà láti fi han àwọn ọkùnrin wọ̀nyí pé ẹ̀kọ́ èké ni wọ́n fi ń kọ́ àwọn èèyàn. Ìyẹn túbọ̀ mú kí inú bí wọn. Nítorí náà, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì ní káwọn èèyàn parọ́ mọ́ ọn.

Àlùfáà àgbà béèrè lọ́wọ́ Sítéfánù pé: ‘Ṣé lóòótọ́ làwọn nǹkan wọ̀nyí rí bẹ́ẹ̀?’ Àsọyé tó fa kíki látinú Bíbélì ni Sítéfánù fi dáhùn. Níparí àsọyé rẹ̀, ó sọ báwọn èèyàn búburú ṣe kórìíra àwọn wòlíì Jèhófà láyé àtijọ́. Ó wá sọ pé: ‘Bí àwọn èèyàn yẹn gẹ́lẹ́ lẹ̀yin náà ṣe rí. Ẹ pa Jésù ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ẹ kò sì pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́.’

Èyí mú kí àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyí bínú gidigidi! Wọ́n bínú débi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í payín keke. Ìgbà yẹn gan-an ní Sítéfánù gbé orí rẹ̀ sókè, ó sì wí pé: ‘Wò ó! Mo rí Jésù tó dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run ní ọ̀run.’ Bó ṣe sọ bẹ́ẹ̀ tán, àwọn ọkùnrin náà fi ọwọ́ di etí wọn, wọ́n sì rọ́ lu Sítéfánù. Wọ́n gbá a mú, wọ́n sì fà á jáde kúrò nílùú.

Lẹ́yìn odi ìlú, wọ́n bọ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn, wọ́n sì kó o síkàáwọ́ Sọ́ọ̀lù pé kó máa ṣọ́ ọ. Ṣó o rí Sọ́ọ̀lù níbi tó dúró sí? Lẹ́yìn náà làwọn kan lára àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í ju òkúta lu Sítéfánù. Sítéfánù ló wà lórí ìkúnlẹ̀ yìí, ó ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: ‘Jèhófà, má ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.’ Ó mọ̀ pé àwọn aṣáájú ìsìn ló tan àwọn kan nínú wọn. Lẹ́yìn náà ni Sítéfánù kú.

Bí ẹnì kan bá ṣe ẹ́ níkà, ṣó o máa ń fẹ́ ṣe tìẹ padà, àbí ṣe ni wàá sọ fún Ọlọ́run pé kó ṣe ẹni náà níkà? Sítéfánù àti Jésù ò ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n jẹ́ onínúure àní sí àwọn tí kò fi inú rere hàn sí wọn pàápàá. Jẹ́ ká gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.