Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

 ÌTÀN 113

Pọ́ọ̀lù Ní Róòmù

Pọ́ọ̀lù Ní Róòmù

WO ṢẸKẸ́ṢẸKẸ̀ ní ọwọ́ Pọ́ọ̀lù, sì wo ọmọ ogun Róòmù tó ń ṣọ́ ọ. Ẹlẹ́wọ̀n ni Pọ́ọ̀lù ní Róòmù. Ó ń dúró dìgbà tí Késárì olú ọba Róòmù á pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe fún un. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń ṣẹ̀wọ̀n lọ́wọ́, wọ́n gba àwọn èèyàn láyè láti máa wá bẹ̀ ẹ́ wò.

Lọ́jọ́ kẹta lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù dé Róòmù ó ránṣẹ́ sí díẹ̀ lára aṣáájú àwọn Júù pé kí wọ́n wá rí òun. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù tó wà ní Róòmù lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù wàásù fún wọn nípa Jésù àti Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn kan gbà gbọ́ wọ́n sì di Kristẹni, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn ò gbà á gbọ́.

Pọ́ọ̀lù sì tún wàásù fún onírúuru àwọn ọmọ ogun tí wọ́n yàn pé kí wọ́n máa sọ́ ọ. Fún ọdún méjì tó fi wà ní Róòmù gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, ó ń wàásù fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣáà ti rí. Nítorí èyí, àní agbo ilé Késárì pàápàá gbọ́ nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, àwọn kan lára wọn sì di Kristẹni.

Ṣùgbọ́n ta ni àlejò tó ń kọ̀wé lórí tábìlì yìí? Ṣó o lè gbìyànjú wò bóyá wà á mọ̀ ọ́n? Bẹ́ẹ̀ ní, Tímótì ni. Tímótì pàápàá ti dèrò ẹ̀wọ̀n nítorí wíwàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n tún dá a sílẹ̀. Ìyẹn ló ṣe lè wá síbí láti wá ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́. Ṣó o mọ ohun tí Tímótì ń kọ? Jẹ́ ká wò ó ná.

Ṣó o rántí àwọn ìlú bíi Fílípì àti Éfésù nínú Ìtàn 110? Pọ́ọ̀lù ṣèrànwọ́ láti dá ìjọ sílẹ̀ láwọn ìlú wọ̀nyẹn. Ní báyìí, tó ṣì wà lẹ́wọ̀n, ó kọ lẹ́tà sáwọn ìjọ wọ̀nyẹn. Àwọn lẹ́tà náà wà nínú Bíbélì, àwọn là ń pè ní Éfésù àti Fílípì. Pọ́ọ̀lù ń sọ ohun tí Tímótì máa kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Fílípì fún un.

Àwọn ará Fílípì fi inúure hàn sí Pọ́ọ̀lù. Wọ́n fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí i nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, nítorí náà Pọ́ọ̀lù ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn. Ẹpafíródítù ni ọkùnrin tó mú ẹ̀bùn náà wá. Ṣùgbọ́n ó ṣàìsàn ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. Ara rẹ̀ ti yá báyìí, ó sì ti múra tán láti padà lọ sílé. Òun ló máa mú lẹ́tà tí Tímótì bá Pọ́ọ̀lù kọ yìí dání nígbà tó bá ń lọ sí Fílípì.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ṣì wà lẹ́wọ̀n, ó kọ lẹ́tà méjì míì tó wà nínú Bíbélì. Ó kọ ọ̀kan lára rẹ̀ sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè. Ṣó o mọ orúkọ tó pe lẹ́tà náà? Kólósè ni. Èkejì jẹ́ lẹ́tà tó kọ sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ tó ń jẹ́ Fílémónì, tóun náà ń gbé ní Kólósè. Lẹ́tà náà dá lórí ìránṣẹ́ Fílémónì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ónẹ́símù.

Ónẹ́símù sá kúrò lọ́dọ̀ Fílémónì ó sì wá sí Róòmù. Nígbà tó dé Róòmù, ó gbọ́ pé Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n níbẹ̀. Ó lọ bẹ Pọ́ọ̀lù wò, Pọ́ọ̀lù sì wàásù fún un. Láìpẹ́ Ónẹ́símù di Kristẹni. Ìgbà yẹn ló tó wá ń dùn ún pé òun sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá òun. Ṣó o tiẹ̀ mọ ohun tó wà nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Fílémónì?

Pọ́ọ̀lù sọ fún Fílémónì pé kó dárí ji Ónẹ́símù. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: ‘Èmi ń rán an padà sí ọ. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí òun kì í ṣe ìránṣẹ́ rẹ nìkan. Ó tún jẹ́ Kristẹni arákùnrin rere.’ Nígbà tí Ónẹ́símù ń padà lọ sí Kólósè ó mú àwọn lẹ́tà méjì náà dání, ó máa fún àwọn ará Kólósè ní ọ̀kan á sì fún Fílémónì ní èkejì. Ó dájú pé inú Fílémónì á dùn gan-an nígbà tó bá gbọ́ pé ìránṣẹ́ òun ti di Kristẹni.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn ará Fílípì àti sí Fílémónì, ó ní ìhìn rere tó fẹ́ kí wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀ lóòótọ́. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Fílípì pé: ‘Mò ń rán Tímótì bọ̀ lọ́dọ̀ yín. Ṣùgbọ́n èmi náà á wá bẹ̀ yìn wò láìpẹ́.’ Ó sì kọ̀wé sí Fílémónì pé: ‘Wá àyè ibì kan sílẹ̀ dè mí láti dé sí.’

Nígbà tí wọ́n dá Pọ́ọ̀lù sílẹ̀, ó bẹ àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ wò ní àwọn ibi púpọ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà, wọ́n tún sọ Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n ní Róòmù. Lọ́tẹ̀ yìí, ó mọ̀ pé pípa ni wọ́n máa pa òun. Nítorí náà, ó kọ̀wé sí Tímótì ó sì sọ fún un pé kó tètè wá. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: ‘Mo ti ṣe olóòótọ́ sí Ọlọ́run, òun yóò sì san èrè fún mi.’ Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n pa Pọ́ọ̀lù ni Jerúsálẹ́mù pa run. Àwọn ará Róòmù ló pa á run lọ́tẹ̀ yìí.

Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ nǹkan ṣì wà nínú Bíbélì. Jèhófà mú kí àpọ́sítélì Jòhánù kọ àwọn ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì, títí kan ìwé Ìṣípayá. Ìwé Bíbélì yìí sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la. Ní báyìí, jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí.