Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÌTÀN 112

Ọkọ̀ Rì Ní Erékùṣù Kan

Ọkọ̀ Rì Ní Erékùṣù Kan

WO NǸKAN! ọkọ̀ yìí ti fẹ́ rì sómi! Ó ti ń fọ́ sí wẹ́wẹ́! Ṣó o rí àwọn èèyàn tí wọ́n ti kó sómi? Àwọn kan tiẹ̀ ti wẹ̀ dé etí omi. Ṣé Pọ́ọ̀lù ló wà lọ́hùn-ún yẹn? Jẹ́ ká wádìí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí i.

Rántí pé, ọdún méjì ni Pọ́ọ̀lù fi ṣẹ̀wọ̀n ní Kesaréà. Lẹ́yìn náà ni wọ́n kó òun àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn sínú ọkọ̀ kí wọ́n bàa lè gbé wọn wá sí Róòmù. Nígbà tí wọ́n gba ìtòsí erékùṣù Kírétè kọjá, ìjì ńlá kan kọ lù wọ́n. Ọwọ́ ìjì náà le débi pé àwọn ọkùnrin náà ò lè tu ọkọ̀ náà mọ́. Wọn ò rí oòrùn mọ́ lọ́sàn-án, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì rí àwọn ìràwọ̀ mọ́ lóru. Lẹ́yìn tí nǹkan ti rí báyìí fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, àwọn tó wà nínú ọkọ̀ ti gbà pé ikú ló kàn.

Ni Pọ́ọ̀lù bá dìde dúró, ó sì sọ pé: ‘Kò sí ọ̀kan nínú yín tó máa kú; ọkọ̀ yìí nìkan la máa pàdánù. Nítorí pé ní òru àná ni áńgẹ́lì Ọlọ́run tọ̀ mí wá tó sì sọ pé, “Má bẹ̀rù, Pọ́ọ̀lù! O gbọ́dọ̀ dúró níwájú Késárì alákòóso Róòmù. Ọlọ́run á sì gba gbogbo àwọn tó bá ọ wọ ọkọ̀ pọ̀ là.”’

Ní nǹkan bí ọ̀gànjọ́ òru ọjọ́ kẹrìnlá tí ìjì náà ti bẹ̀rẹ̀, àwọn atukọ̀ ṣàkíyèsí pé omi náà ò fi bẹ́ẹ̀ jìn mọ́! Nítorí ìbẹ̀rù kí wọ́n má kọ lu òkúta lóru, wọ́n ju àwọn ìdákọ̀ró wọn sínú òkun. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì wọ́n rí ibì kan létí òkun tí wọ́n lè darí ọkọ̀ náà sí. Wọ́n gbìyànjú láti tukọ̀ wọn tààràtà lọ sí etíkun yẹn.

Ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n túbọ̀ ń sún mọ́ etíkun, ọkọ́ náà kọ lu òkìtì yanrìn, kò sì le lọ mọ́. Ìgbì òkun wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lù ú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fọ́ sí wẹ́wẹ́. Ọ̀gágun tó jẹ́ alábòójútó sọ pé: ‘Gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ẹ bá mọ̀wẹ̀, ẹ kọ́kọ́ bẹ́ sínú omi kẹ́ ẹ sì wẹ̀ lọ sí èbúté. Kí ẹ̀yin tó kù bẹ́ sínú omi kí ẹ sì di àwọn àfọ́kù igi ọkọ̀ mú.’ Ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn. Nípa báyìí gbogbo àwọn igba ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [276] èèyàn tó wà nínú ọkọ̀ náà dé èbúté ní àlááfíà, bí áńgẹ́lì náà ti ṣèlérí.

Málítà ní wọ́n ń pe erékùṣù náà. Àwọn èèyàn ibẹ̀ jẹ́ onínúure, wọ́n sì ṣètọ́jú àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà. Nígbà tí ojú ọjọ́ sì tún dára, wọ́n fi Pọ́ọ̀lù sínú ọkọ̀ mìíràn, wọ́n sì wà á lọ sí Róòmù.