Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

 ÌTÀN 102

Jésù Jíǹde

Jésù Jíǹde

ǸJẸ́ o mọ obìnrin àtàwọn ọkùnrin méjì tó wà níbí yìí? Ọ̀rẹ́ Jésù ni obìnrin yẹn, Màríà Magidalénì lorúkọ rẹ̀. Áńgẹ́lì làwọn ọkùnrin tó wọṣọ funfun yẹn. Yàrá kékeré tí Màríà ń yọjú wò yẹn ni wọ́n tẹ́ òkú Jésù sí lẹ́yìn tó kù. Ibojì ni wọ́n ń pè é. Àmọ́, òkú Jésù ò sí níbẹ̀ mọ́ báyìí! Ta ló gbé e? Jẹ́ ká wo bọ́rọ̀ náà ṣe jẹ́.

Lẹ́yìn ikú Jésù, àwọn àlùfáà sọ fún Pílátù pé: ‘Kí Jésù tó kú, ó sọ pé òun máa jíǹde lọ́jọ́ kẹta. Nítorí náà, pàṣẹ pé kí àwọn olùṣọ́ máa ṣọ́ ibojì náà. Ìyẹn ò ní jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ jí òkú rẹ̀ gbé kí wọ́n wá máa sọ pé ó ti jíǹde!’ Nítorí náà, Pílátù sọ fáwọn àlùfáà pé kí wọ́n sọ fáwọn ọmọ ogun kan pé kí wọ́n lọ máa ṣọ́ ibojì náà.

Ṣùgbọ́n ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ kẹta tí Jésù ti kú, áńgẹ́lì Jèhófà kan dé lójijì. Ó yí òkúta tí wọ́n fi dí ibojì náà kúrò. Àyà àwọn ọmọ ogun náà já débi pé wọn ò lè mira. Nígbà tí wọ́n sì jàjà wo inú ibojì náà, wọn ò rí òkú Jésù níbẹ̀ mọ́! Àwọn kan lára àwọn ọmọ ogun náà gba inú ìlú lọ láti sọ fáwọn àlùfáà. Ṣó o mọ ohun táwọn àlùfáà búburú náà ṣe? Wọ́n fún àwọn ọmọ ogun náà lówó kí wọ́n lè parọ́ pé: ‘Nígbà tá à ń sùn lóru, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá, wọ́n sì jí òkú rẹ̀ gbé lọ.’

Ibi tí wọ́n ti ń gbèrò láti parọ́ yìí làwọn obìnrin kan tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù ti gba ibi ibojì náà lọ. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, ẹnu yà wọ́n láti rí i pé ibojì náà ti ṣófo. Lójú ẹsẹ̀ làwọn áńgẹ́lì méjì kan tí aṣọ wọn ń tàn yòò dé! Wọ́n bi àwọn obìnrin náà pé: ‘Kí ló dé tí ẹ̀ ń wá Jésù níbí yìí? Ọlọ́run ti jí i dìde. Ẹ tètè lọ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.’ Eré tete làwọn obìnrin náà fi gé e! Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń sáré lọ, ọkùnrin kan dá wọn dúró lójú ọ̀nà. Ṣó o mọ ọkùnrin náà? Jésù ni! Ó sọ fáwọn obìnrin náà pé: ‘Ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi.’

Nígbà táwọn obìnrin náà sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn pé Jésù ti jíǹde àti pé àwọn rí i, ó ṣòro fún wọn láti gbà gbọ́. Pétérù àti Jòhánù sáré lọ síbi ibojì náà kí wọ́n lè fojú ara wọn rí i, àmọ́ ibojì náà ṣófo! Nígbà tí Pétérù àti Jòhánù kúrò níbẹ̀, Màríà Magidalénì ṣì dúró síbẹ̀. Ìgbà yẹn ló wo inú ibojì yẹn tó sì rí àwọn áńgẹ́lì méjì náà.

Ṣó o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ara Jésù tí wọ́n tẹ́ sínú ibojì náà? Ọlọ́run ló jẹ́ kó pòórá. Ọlọ́run ò jí Jésù dìde pẹ̀lú ẹran ara tó ní kó tó kú. Ńṣe ló fún un ní ara míì tó jẹ́ ara ẹ̀mí, irú tàwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run. Àmọ́, Jésù lè gbé ara tí èèyàn lè fojú rí wọ̀ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lè mọ̀ pé ó ti jí dìde. A óò rí bó ṣe ṣe bẹ́ẹ̀.