Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

 ÌTÀN 105

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dúró Sí Jerúsálẹ́mù

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dúró Sí Jerúsálẹ́mù

ỌMỌLẸ́YÌN Jésù ni gbogbo àwọn tó ò ń wò yìí. Wọ́n ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé kí wọ́n dúró sí Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí gbogbo wọn jọ wà pa pọ̀, ariwo ńláǹlà kan kún gbogbo ilé náà. Ó dún bí ariwo ẹ̀fúùfù líle. Ẹ̀là iná tó dà bí ahọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Ṣó o rí ẹ̀là iná náà lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn? Kí tiẹ̀ ló túmọ̀ sí gan-an?

Iṣẹ́ ìyanu gbáà ni! Jésù ti padà sọ́run lọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀, òun ló sì ń tú ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí ẹ̀mí náà mú kí wọ́n máa ṣe? Ó mú kí gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ oríṣiríṣi èdè.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ní Jerúsálẹ́mù ló gbọ́ ariwo náà tó dún bí ẹ̀fúùfù líle, wọ́n sì wá láti wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Láti orílẹ̀-èdè míì làwọn kan lára àwọn èèyàn wọ̀nyí ti wá, wọ́n wá bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àjọ̀dún Pẹ́ńtíkọ́sì. Nǹkan ìyanu làwọn èèyàn yìí mà rí o! Olúkúlùkù wọn gbọ́ táwọn ọmọ ẹ̀yìn ń fi èdè wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun ìyanu tí Ọlọ́run ti ṣe.

Àwọn àlejò náà sọ pé: ‘Láti Gálílì làwọn ará ibí yìí ti wá. Báwo ló ṣe jẹ́ tí olúkúlùkù wa ń gbọ́ èdè àbínibí wa lẹnu wọn?’

Pétérù wá dìde láti ṣàlàyé fún wọn. Ó gbé ohùn rẹ̀ sókè ó sì sọ fún wọn bí wọ́n ṣe pa Jésù tí Jèhófà sì gbé e dìde kúrò nínú òkú. Pétérù wá sọ pé: ‘Nísinsìnyí Jésù wà ní ọ̀run ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Ó sì ti tú ẹ̀mí mímọ́ tó ṣèlérí jáde. Ìdí nìyẹn tẹ́ ẹ fi rí tẹ́ ẹ sì gbọ́ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí.’

Nígbà tí Pétérù sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, púpọ̀ lára àwọn èèyàn náà káàánú nípa ohun tí wọ́n ṣe sí Jésù. Wọ́n béèrè pé: ‘Kí ni kí àwa ṣe?’ Pétérù sọ fún wọn pé: ‘Ẹ ní láti yí ọ̀nà yín padà kí a sì batisí yín.’ Nítorí náà ní ọjọ́ yẹn gan-an, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] èèyàn ni wọ́n rì bọmi tí wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn Jésù.