Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÌTÀN 85

Wọ́n Bí Jésù Sí Ibùso Ẹran

Wọ́n Bí Jésù Sí Ibùso Ẹran

ǸJẸ́ o mọ ẹni tí ọmọ ọwọ́ yìí jẹ́? Tó o bá sọ pé Jésù ni, o gbà á. Màríà ṣẹ̀ṣẹ̀ bí i sí ibùso ẹran ni. Ibí yìí ni wọ́n ti máa ń tọ́jú àwọn ẹran. Ó fẹ́ tẹ́ Jésù sínú ibùjẹ ẹran, ìyẹn ibi tí wọ́n máa ń kó oúnjẹ àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí àwọn ẹran mìíràn sí. Ṣùgbọ́n kí nìdí tí Màríà àti Jósẹ́fù fi wà nínú ilé àwọn ẹran? Kì í ṣe irú ilé yìí ni wọ́n ti máa ń bí ọmọ, àbí ibẹ̀ ni?

Rárá, ibẹ̀ kọ́ ló yẹ kí wọ́n bí ọmọ sí. Ohun tó gbé wọn débí rèé: Alákòóso ilẹ̀ Róòmù tó ń jẹ́ Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì ṣòfin kan pé kí gbogbo èèyàn padà lọ sí ìlú tí wọ́n ti bí wọn kí wọ́n lọ fi orúkọ sílẹ̀ níbẹ̀. Ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù níbí ni wọ́n sì ti bí Jósẹ́fù. Àmọ́ nígbà tí òun àti Màríà dé, kò sí àyè kankan fún wọn. Torí náà, wọ́n ní láti wá sí ibi tí wọ́n ń so àwọn ẹran mọ́ yìí. Ọjọ́ tí wọ́n débẹ̀ yìí gan-an ni Màríà sì bí Jésù! Àmọ́ gẹ́gẹ́ bó o ti rí i nínú àwòrán, kò sí ohun tó ṣe ọmọ yìí.

Ṣé o rí àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyẹn tí wọ́n ń bọ̀ wá wo Jésù? Inú pápá ni wọ́n wà ní òru tí wọ́n ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn nígbà tí ìmọ́lẹ̀ kan tàn yòò yí wọn ká. Áńgẹ́lì kan ló yọ sí wọn! Ẹ̀rù ba àwọn olùṣọ́ àgùntàn yẹn gidigidi. Àmọ́ áńgẹ́lì yẹn sọ pé: ‘Ẹ má bẹ̀rù! Ìhìn rere ni mo mú tọ̀ yín wá. Lónìí ni wọ́n bí Kristi Olúwa sí ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Òun ló máa gba àwọn èèyàn là! Ẹ máa rí i níbi tí wọ́n ti fi ọ̀já wé e, tí wọ́n gbé e sí ibùjẹ ẹran.’ Òjijì ni ọ̀pọ̀ àwọn áńgẹ́lì dé tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo. Nítorí náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyí ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá Jésù, wọ́n sì ti rí i báyìí.

Ǹjẹ́ o mọ ìdí rẹ̀ tí Jésù fi jẹ́ ẹni pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an? Rántí pé nínú ìtàn àkọ́kọ́ tá a kà nínú ìwé yìí, a gbọ́ nípa Ọmọkùnrin àkọ́kọ́ fún Ọlọ́run. Ọmọkùnrin yìí bá Jèhófà ṣiṣẹ́ láti dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo mìíràn. Òun gan-an ni Jésù!

Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà mú ìwàláàyè Ọmọ rẹ̀ kúrò ní ọ̀run ó sì fi í sínú Màríà. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ọmọ kékeré kan bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ṣe máa ń dàgbà nínú ìyá wọn. Ṣùgbọ́n ọmọ Ọlọ́run ni èyí. Nígbà tó yá, Màríà bí Jésù sí ibùso ẹran níbí ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Ṣé o wá lè rí ìdí tí inú àwọn áńgẹ́lì fi dùn jọjọ láti sọ fún àwọn èèyàn pé a ti bí Jésù?