Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

 ÌTÀN 99

Nínú Yàrá Kan Lórí Òkè Pẹ̀tẹ́ẹ̀sì

Nínú Yàrá Kan Lórí Òkè Pẹ̀tẹ́ẹ̀sì

ALẸ́ ọjọ́ Thursday ni báyìí, tí í ṣe ọjọ́ kẹta. Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá ti wà nínú yàrá ńlá yìí tó wà lórí òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì láti jẹ oúnjẹ Ìrékọjá. Ọkùnrin tó o rí tó ń jáde lọ yẹn ni Júdásì Ísíkáríótù. Ó ń lọ sọ fún àwọn àlùfáà bí wọ́n ṣe máa mú Jésù.

Ní ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ yẹn ni Júdásì tọ̀ wọ́n lọ tó sì béèrè pé: ‘Kí lẹ máa fún mi bí mo bá ràn yín lọ́wọ́ láti rí Jésù mú?’ Wọ́n sọ pé: ‘Ọgbọ̀n owó fàdákà.’ Ní báyìí, Júdásì ń lọ sọ́dọ̀ wọn láti mú wọn wá sọ́dọ̀ Jésù. Ǹjẹ́ èyí ò wa burú bí?

Oúnjẹ Ìrékọjá ti parí. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí Jésù tún bẹ̀rẹ̀ oúnjẹ àkànṣe míì. Ó fi ìṣù àkàrà lé àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì wí pé: ‘Ẹ jẹ ẹ́, nítorí pé èyí túmọ̀ sí ara mi tí a ó fi fún yín.’ Lẹ́yìn náà, ó gbé ife wáìnì kan lé wọn lọ́wọ́ ó sì wí pé: ‘Ẹ mu ún, nítorí pé èyí túmọ̀ sí ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ó ta sílẹ̀ fún yín.’ Bíbélì pè é ní ‘Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.’

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń jẹ àsè Ìrékọjá láti rán wọn létí ìgbà tí áńgẹ́lì ‘ré kọjá’ ilé wọn ní Íjíbítì, tó sì pa àwọn àkọ́bí nínú ilé àwọn ará Íjíbítì. Ṣùgbọ́n ní báyìí, Jésù fẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa rántí òun, àti bí òun ṣe fi ẹ̀mí òun lélẹ̀ fún wọn. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tó fi sọ fún wọn pé kí wọ́n máa ṣe ìrántí oúnjẹ àkànṣe yìí lọ́dọọdún.

Lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tán, Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n ní ìgboyà kí wọ́n sì jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́. Níkẹyìn wọ́n kọrin sí Ọlọ́run, wọ́n sì jáde lọ. Ilẹ̀ ti ṣú gan-an nísinsìnyí, ó ṣeé ṣe kí aago méjìlá òru ti kọjá. Jẹ́ ká wo ibi tí wọ́n lọ.