Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

 ÌTÀN 88

Jòhánù Batisí Jésù

Jòhánù Batisí Jésù

WO ẸYẸ àdàbà tó ń sọ̀ kalẹ̀ wá sórí ọkùnrin yìí. Jésù nìyí. Ó ti tó ẹni ọgbọ̀n ọdún nísinsìnyí. Jòhánù ni ọkùnrin kejì tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ yẹn. A ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ rí. Ṣó o rántí ìgbà tí Màríà lọ sọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì ìbátan rẹ̀, tí ọmọ tó wà nínú Èlísábẹ́tì sì sọ kúlú fún ayọ̀? Ọmọ tó wà nínú Èlísábẹ́tì nígbà yẹn ni Jòhánù. Ṣùgbọ́n kí ni Jòhánù àti Jésù ń ṣe nísinsìnyí?

Jòhánù ṣẹ̀ṣẹ̀ ri Jésù bọnú omi Odò Jọ́dánì tán ni. Bá a ṣe máa ń batisí èèyàn nìyẹn. A óò kọ́kọ́ ri ẹni ọ̀hún bọ inú omi, a óò wá gbé e sókè lẹ́yìn náà. Torí pé ohun tí Jòhánù máa ń ṣe fún àwọn èèyàn rèé ni wọ́n ṣe ń pè é ní Jòhánù Arinibọmi. Ṣùgbọ́n kí nìdí tí Jòhánù fi batisí Jésù?

Ìdí tí Jòhánù fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé Jésù wá ó sì sọ fún Jòhánù pé kó batisí òun, ìyẹn ni pé kó ri òun bọmi. Àwọn èèyàn tó fẹ́ fi hàn pé àwọn kábàámọ̀ ohun búburú tí àwọn ti ṣe ni Jòhánù máa ń batisí. Ṣé Jésù ti ṣe ohun búburú kan tó yẹ kó kábàámọ̀ rẹ̀ ni? Rárá o, Ọmọ Ọlọ́run tó wá láti ọ̀run ni. Nítorí náà, ìdí ọ̀tọ̀ ni Jésù fi sọ pé kí Jòhánù batisí òun. Jẹ́ ká wo ìdí rẹ̀.

Kí Jésù tó wá bá Jòhánù, iṣẹ́ káfíńtà ni Jésù ń ṣe. Ẹni tó máa ń fi igi ṣe àwọn nǹkan bíi tábìlì, àga, àti bẹ́ǹṣì ni wọ́n ń pè ní káfíńtà. Káfíńtà ni Jósẹ́fù, ọkọ Màríà, òun ló sì kọ́ Jésù ní iṣẹ́ yẹn. Ṣùgbọ́n kì í ṣe iṣẹ́ káfíńtà ni Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá ṣe láyé. Iṣẹ́ pàtàkì kan wà tó ní kó wá ṣe, àkókò sì ti tó fún Jésù láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yẹn. Nítorí náà, láti fi hàn pé òun ti dé nísinsìnyí láti ṣe ìfẹ́ Bàbá òun, Jésù sọ fún Jòhánù pé kó batisí òun. Ǹjẹ́ inú Ọlọ́run dùn sí ohun tí Jésù ṣe yìí bí?

Bẹ́ẹ̀ ni, inú rẹ̀ dùn sí i, nítorí pé, lẹ́yìn tí Jésù jáde kúrò nínú omi, ohùn kan dún láti ọ̀run pé: ‘Èyí ni Ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó dà bí pé ọ̀run ṣí sílẹ̀ tí ẹyẹ àdàbà sì sọ̀ kalẹ̀ wá sórí Jésù. Ṣùgbọ́n kì í ṣe ẹyẹ àdàbà gidi. Ó wulẹ̀ jọ ọ́ ni. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gan-an ni.

Ní báyìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jésù ní láti ronú lé lórí, nítorí náà, ó dá nìkan lọ sí ibi ìkọ̀kọ̀ kan fún ogójì [40] ọjọ́. Ibẹ̀ ni Sátánì ti tọ̀ ọ́ wá. Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Sátánì gbìyànjú láti mú kí Jésù ṣe ohun kan tó lòdì sí òfin Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n Jésù kò ṣe ohun tí Sátánì wí.

Lẹ́yìn èyí, Jésù padà, ó sì pàdé àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àkọ́kọ́. Orúkọ díẹ̀ nínú wọn ni Áńdérù, Pétérù (tí wọ́n tún ń pè ní Símónì), Fílípì àti Nàtáníẹ́lì (tí wọ́n tún ń pè ní Batólómíù). Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun wọ̀nyí forí lé àgbègbè Gálílì. Ní Gálílì, wọ́n dúró ní Kánà ní ìlú ìbílẹ̀ Nàtáníẹ́lì. Ibẹ̀ ni Jésù ti lọ sí ibi àsè ìgbéyàwó ńlá kan, tó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣe? Ó sọ omi di ọtí wáìnì.