BÌ JÉSÙ ṣe ń rìnrìn àjò káàkiri ilẹ̀ náà, ó ń wo àwọn aláìsàn sàn. Ìròyìn àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí ti bẹ̀rẹ̀ sí í tàn káàkiri àwọn abúlé àti ìlú tó wà lágbègbè ibẹ̀. Nítorí náà àwọn èèyàn ń gbé àwọn arọ àti afọ́jú àti adití tọ̀ ọ́ wá, àti púpọ̀ àwọn tó ń ṣàìsàn. Jésù sì wo gbogbo wọn sàn.

Ó ju ọdún mẹ́ta sẹ́yìn nísinsìnyí tí Jòhánù ti batisí Jésù. Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé láìpẹ́ òun á lọ sí Jerúsálẹ́mù, níbi tí wọ́n á ti pa òun, tí òun sì máa jí dìde. Àmọ́ kó to dìgbà yẹn, Jésù ń ṣe ìwòsàn nìṣó.

Lọ́jọ́ sábáàtì kan Jésù ń kọ́ni. Ọjọ́ sábáàtì jẹ́ ọjọ́ ìsinmi fún àwọn Júù. Obìnrin tó ò ń wò níbí yìí ń ṣàìsàn gan-an ni. Fún ọdún méjìlélógún [18] ni ẹ̀yìn rẹ̀ fi tẹ̀, tí kó sì lè nàró dáadáa. Nítorí náà, Jésù gbé ọwọ́ lé e, ó sì nàró ṣánṣán. Ara rẹ̀ ti yá!

Èyí bí àwọn aṣáájú ìsìn nínú. Ọ̀kan nínú wọn ń kígbe bó ṣe ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀, ó ní: ‘Ọjọ́ mẹ́fà ló wà nínú ọ̀sẹ̀ téèyàn fi lè ṣiṣẹ́. Ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ yẹn ni kẹ́ ẹ wá gba ìwòsàn, kì í ṣe ní ọjọ́ Sábáàtì!’

Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn pé: ‘Ẹ̀yin ìkà èèyàn yìí. Kò séyìí tí kì í tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lórí ìso, kó sì mú un lọ láti fún un ní omi ní ọjọ́ Sábáàtì? Ṣé kò wá yẹ fún obìnrin yìí ẹni tó ti ń ṣàìsàn fún ọdún méjìdínlógún [18], pé kó rí ìwòsàn ní ọjọ́ Sábáàtì?’ Ìdáhùn Jésù dójú ti àwọn ìkà yìí.

Lẹ́yìn náà Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ rin ìrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù. Bí wọ́n ti kúrò ní Jẹ́ríkò, àwọn afọ́jú alágbe méjì kan gbọ́ pé Jésù ń kọjá lọ. Nítorí náà wọ́n kígbe pé: ‘Jésù, ṣàánú fún wa!’

Jésù pe àwọn afọ́jú yẹn pé kí wọ́n wá, ó sì béèrè pé: ‘Kí lẹ fẹ́ kí n ṣe fún yín?’ Wọ́n dáhùn pé: ‘Olúwa, jẹ́ kí ojú wa là.’ Jésù fọwọ́ kan ojú wọn, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n sì ríran! Ǹjẹ́ o mọ ìdí rẹ̀ tí Jésù fi ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu yìí? Ó jẹ́ nítorí pé ó fẹ́ràn àwọn èèyàn, ó sì fẹ́ pé kí wọ́n gba òun gbọ́. Èyí mú un dá wa lójú pé kò ní sí ẹ̀dà èèyàn kankan láyé yìí mọ́ táá máa ṣàìsàn nígbà tí Jésù bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba.