Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

 ÌTÀN 87

Jésù Ọ̀dọ́mọdé Nínú Tẹ́ńpìlì

Jésù Ọ̀dọ́mọdé Nínú Tẹ́ńpìlì

WO Ọ̀DỌ́MỌKÙNRIN yìí tó ń bá àwọn àgbà-àgbà ọkùnrin wọ̀nyí sọ̀rọ̀. Olùkọ́ni ni wọ́n nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù. Jésù ni Ọmọkùnrin yẹn. Ó ti dàgbà díẹ̀. Ọmọ ọdún méjìlá [12] ni nísinsìnyí.

Ẹnu ya àwọn olùkọ́ni yẹn púpọ̀ pé ohun tí Jésù mọ̀ pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nípa Ọlọ́run àtàwọn ohun tí wọ́n kọ sínú Bíbélì. Ṣùgbọ́n kí ló dé tí Jósẹ́fù àti Màríà kò fi sí níbí pẹ̀lú Jésù? Ibo làwọn wà? Jẹ́ ká wò ó.

Ọdọọdún ni Jósẹ́fù máa ń kó àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù fún àjọyọ̀ pàtàkì kan tó ń jẹ́ Ìrékọjá. Ìrìn àjò gígùn láti Násárétì sí Jerúsálẹ́mù ni. Kò sẹ́ni tó ní mọ́tò tàbí ọkọ̀ ojú irin. Kò tíì sóhun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ láyé ìgbà yẹn. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn ló máa ń fẹsẹ̀ rìn, ó sì ń gbà wọ́n tó nǹkan bí ọjọ́ mẹ́ta kí wọ́n tó lè dé Jerúsálẹ́mù.

Lákòókò yìí, Jósẹ́fù ti bí ọmọ púpọ̀. Nítorí ìdí èyí àwọn àbúrò Jésù lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti wà láti bójú tó. Ní ọdún yìí, Jósẹ́fù àti Màríà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn gbéra láti rin ìrìn àjò gígùn yẹn padà sí ìlú wọn ní Násárétì. Èrò wọn ni pé Jésù ti ń bá àwọn mìíràn kẹ́sẹ̀ rìn. Àmọ́ nígbà tí wọ́n dúró ní òpin ọjọ́ yẹn, wọn ò rí Jésù. Wọ́n wá a kiri láàárín àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ wọn, ṣùgbọ́n wọn ò rí i lọ́dọ̀ wọn! Nítorí náà, wọ́n wá a padà lọ sí Jerúsálẹ́mù.

Níkẹyìn, wọ́n rí Jésù lọ́dọ̀ àwọn olùkọ́ni ní Jerúsálẹ́mù. Ó ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè. Ẹnu ya gbogbo èèyàn láti rí bí Jésù ti gbọ́n tó. Ṣùgbọ́n Màríà wí pé: ‘Ọmọ, kí ló dé tó o fi ṣe eléyìí sí wa? Èmi àti bàbá rẹ ti ṣe wàhálà níbi tá a ti ń wá ọ kiri.’

Jésù dáhùn pé: ‘Kí ló dé tẹ́ ẹ fi ń wá mi kiri? Ṣé ẹ ò mọ̀ pé mo ní láti wà nínú ilé Bàbá mi ni?’

Òótọ́ ni, Jésù fẹ́ láti wà ní ibi táá ti lè máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Ṣé kò yẹ kó máa wu àwa náà bẹ́ẹ̀? Ní ìlú wọn ní Násárétì, Jésù máa ń lọ sí àwọn ìpàdé fún ìjọsìn ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Nítorí pé ó máa ń fetí sílẹ̀ nígbà gbogbo, ó mọ ohun púpọ̀ nínú Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká dà bíi Jésù ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.