Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÌTÀN 93

Jésù Bọ́ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Èèyàn

Jésù Bọ́ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Èèyàn

OHUN búburú kan ti ṣẹlẹ̀. Wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa Jòhánù Arinibọmi ni. Hẹrodíà aya ọba ò fẹ́ràn rẹ̀. Ó sì ṣeé ṣe fún un láti mú kí ọba bẹ́ Jòhánù lórí.

Nígbà tí Jésù gbọ́ nípa rẹ̀, inú rẹ̀ bà jẹ́ gidigidi. Òun nìkan lọ sí ibì kan tó dá. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn tẹ̀ lé e. Nígbà tí Jésù rí ọ̀pọ̀ èèyàn, àánú wọ́n ṣe é. Nítorí náà ó bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó sì wo àwọn aláìsan sàn.

Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ rẹ̀ wọ́n sì sọ pé: ‘Ilẹ̀ ti ṣú, ibí yìí sì dá. Jẹ́ káwọn ogunlọ́gọ̀ yìí lọ kí wọ́n lè lọ sínú àwọn abúlé tó wà nítòsí kí wọ́n sì ra àwọn oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ.’

Jésù dáhùn pé: ‘Kò pọn dandan pé kí wọ́n lọ. Ẹ fún wọn ní nǹkan tí wọ́n á jẹ.’ Jésù yíjú sí Fílípì, ó sì béèrè pé: ‘Ibo la tì lè rí oúnjẹ tó tó rà láti fí bọ́ gbogbo àwọn èèyàn yìí?’

Fílípì dá a lóhùn pé: ‘Ó máa ná wa lówó tó pọ̀ gan-an kí gbogbo èèyàn wọ̀nyí tó lè rí oúnjẹ díẹ̀díẹ̀ jẹ.’ Áńdérù sì dáhùn pé: ‘Ọmọkùnrin tó ń tọ́jú oúnjẹ wa ní àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì. Ṣùgbọ́n kò tiẹ̀ lè débì kankan láàárín gbogbo àwọn èèyàn wọ̀nyí.’

Jésù sọ́ pé: ‘Ẹ sọ fún àwọn èèyàn pé kí wọ́n jókòó sórí koríko.’ Lẹ́yìn náà ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oúnjẹ yẹn, ó sì bù ú sí wẹ́wẹ́. Nígbà náà láwọn ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í fún gbogbo èèyàn ní àkàrà àti ẹja. Ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọkùnrin ló wà níbẹ̀, ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé ló sì tún wà níbẹ̀. Gbogbo wọn ní wọ́n jẹ jẹ jẹ títí wọ́n fi yó. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì kó ìyókù jọ, ẹ̀kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá ló ṣẹ́ kù!

Jésù wá ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ láti ré Òkun Gálílì kọjá. Ìjì ńlá kan dé ní òru, ìgbì omi òkun sì ń bi ọkọ̀ síwá sẹ́yìn. Ẹ̀rù ba àwọn ọmọ ẹ̀yìn gidigidi. Nígbà tó yá, ní ọ̀gànjọ́ òru, wọ́n rí ẹnì kan tó ń rìn lórí omi bọ̀ wá sọ́dọ̀ wọn. Ẹ̀rù bà wọ́n, ni wọ́n bá figbe ta, torí pé wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń rí.

Jésù sọ pé: ‘Ẹ má bẹ̀rù. Èmi ni!’ Síbẹ̀ wọn ò gbà á gbọ́. Nítorí náà, Pétérù sọ pé: ‘Bó bá jẹ́ pé ìwọ́ ni lóòótọ́, Olúwa, sọ fún mi pé kí èmi náà máa rìn lórí omi bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ.’ Jésù dáhùn pé: ‘Máa bọ̀!’ Pétérù sì jáde, ó sì ń rìn lórí omi! Ẹ̀yìn náà ni ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì, ṣùgbọ́n Jésù gbà á là.

Lẹ́yìn èyí, Jésù tún bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn. Lọ́tẹ̀ yìí àkàrà méje àti ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ ló fi bọ́ wọn. Bákan náà, oúnjẹ tún ṣì pọ̀ nílẹ̀ fún gbogbo èèyàn láti jẹ. Ṣé kò yà ọ́ lẹ́nu bí Jésù ṣe ń bojú tó àwọn èèyàn? Nígbà tó bá ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Ọlọ́run fi jẹ, a ò ní dààmú nípa ohunkóhun mọ́!