Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

 ÌTÀN 84

Áńgẹ́lì Kan Bẹ Màríà Wò

Áńgẹ́lì Kan Bẹ Màríà Wò

MÀRÍÀ ni orúkọ arẹwà obìnrin yìí. Ọmọ Ísírẹ́lì kan tó ń gbé ní ìlú Násárétì ni. Ọlọ́run mọ̀ pé èèyàn rere ni. Ìdí nìyí tó fi rán áńgẹ́lì rẹ̀ tó ń jẹ́ Gébúrẹ́lì sí i láti bá a sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Gébúrẹ́lì wá sọ fún Màríà? Jẹ́ ká wò ó.

Gébúrẹ́lì wí fún un pé: ‘O kú déédéé ìwòyí o, ìwọ ẹni tá a kọjú sí ṣe lóore. Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.’ Màríà ò tíì rí ẹni yìí rí. Ó jọ ọ́ lójú torí pé kò mọ ìtumọ̀ ohun tó sọ. Àmọ́ lójú ẹsẹ̀ ni Gébúrẹ́lì fọkàn rẹ̀ balẹ̀.

Ó wí pé: ‘Má bẹ̀rù Màríà. Inú Jèhófà dùn sí ọ. Ìdí nìyí tó fi fẹ́ ṣe ohun ìyanu fún ọ. O ò ní í pẹ́ bí ọmọ kan. Kó o pe orúkọ ọmọ náà ní Jésù.’

Gébúrẹ́lì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: ‘Ẹni ńlá ni ọmọ yìí á jẹ́, a ó sì máa pè é ní Ọmọ Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ. Jèhófà á ṣe é ní ọba, bíi ti Dáfídì. Ṣùgbọ́n títí láé ni Jésù máa jọba, ìjọba rẹ̀ ò sì ní dópin!’

Màríà béèrè pé: ‘Báwo ni èyí ṣe lè rí bẹ́ẹ̀? Èmi tí mi ò tiẹ̀ lọ́kọ. Mi ò tíì bá ọkùnrin gbé rí, báwo ni mo sì ṣe lè bímọ?’

Gébúrẹ́lì fèsì pé: ‘Agbára Ọlọ́run máa ṣíji bò ọ́. Nítorí náà, Ọmọ Ọlọ́run ni a óò máa pe ọmọ náà.’ Lẹ́yìn náà, ó sọ fún Màríà pé: ‘Rántí Èlísábẹ́tì ìbátan rẹ. Àwọn èèyàn sọ pé ó ti darúgbó jù, pé kò lè bímọ. Ṣùgbọ́n láìpẹ́ báyìí ó máa bí ọmọkùnrin kan. Nítorí náà, ṣé o rí i pé kò sí ohun tí Ọlọ́run kò lè ṣe.’

Lójú ẹsẹ̀, Màríà wí pé: ‘Ẹrúbìnrin Jèhófà ni mí! Kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣẹ sí mi lára.’ Lẹ́yìn náà ni áńgẹ́lì náà lọ.

Màríà sáré lọ bẹ Èlísábẹ́tì wò. Nígbà tí Èlísábẹ́tì gbọ́ ohùn Màríà, ayọ̀ mú kí ọmọ tó wà nínú Èlísábẹ́tì tọ kúlú. Èlísábẹ́tì kún fún ẹ̀mí Ọlọ́run, ó sì wí fún Màríà pé: ‘Alábùkún fún ni ìwọ láàárín àwọn obìnrin.’ Màríà lo bí oṣù mẹ́ta lọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì kó tó padà lọ sí ilé rẹ̀ ní Násárétì.

Màríà ń múra láti di ìyàwó ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jósẹ́fù gbọ́ pé Màríà máa bí ọmọ kan, ó rò pé kò yẹ kí òun gbé e níyàwó mọ́. Ìgbà náà ni áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ fún Jósẹ́fù pé: ‘Má ṣe bẹ̀rù láti fi Màríà ṣe aya rẹ. Nítorí pé Ọlọ́run ló fún un lọ́mọ.’ Torí náà, Màríà àti Jósẹ́fù fẹ́ ara wọn, wọ́n sì ń dúró de ìgbà tí Màríà máa bí Jésù.