Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

APÁ 6

Ìgbà Ìbí Jésù sí Àkókò Ikú Rẹ̀

Ìgbà Ìbí Jésù sí Àkókò Ikú Rẹ̀

Ọlọ́run rán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sí ọmọbìnrin arẹwà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Màríà. Ó sọ fún un pé ó máa bí ọmọ kan tó máa jọba títí láé. Ibùso ẹran ló bí ọmọ náà tó ń jẹ́ Jésù sí. Ibẹ̀ ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn ti lọ bẹ̀ ẹ́ wò. Lẹ́yìn náà, ìràwọ̀ kan ṣamọ̀nà àwọn èèyàn kan láti Ìlà Oòrùn wá sí ọ̀dọ́ ọmọ náà. A máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹni tó mú kí wọ́n rí ìràwọ̀ náà àti bí Jèhófà ò ṣe jẹ́ káwọn tó fẹ́ pa Jésù rí i pa.

Síwájú sí i, nígbà tí Jésù pé ọmọ ọdún méjìlá, a rí i tó ti ń bá àwọn olùkọ́ni jíròrò nínú tẹ́ńpìlì. Ọdún méjìdínlógún lẹ́yìn náà, Jésù ṣèrìbọmi, lẹ́yìn náà ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù àti ti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí Ọlọ́run rán an wá sáyé láti ṣe. Láti ràn án lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí, Jésù yan àwọn ọkùnrin méjìlá ó sì sọ wọ́n di àpọ́sítélì rẹ̀.

Jésù tún ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu. Ó fi àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ àti àkàrà díẹ̀ bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn. Ó wo àwọn aláìsàn sàn, àní ó tiẹ̀ jí àwọn òkú dìde. Níkẹyìn, a máa kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù nígbà ọjọ́ ìkẹyìn ìgbésí ayé rẹ̀ àti bí wọ́n ṣe pa á. Jésù wàásù fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ nítorí náà APÁ 6 kárí àkókò tó fi díẹ̀ lé ní ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34].

 

NÍ APÁ YÌÍ

ÌTÀN 84

Áńgẹ́lì Kan Bẹ Màríà Wò

Ó wá jíṣẹ́ kan fún Màríà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé ó máa bí ọmọ kan tó máa jẹ́ ọba títí láé..

ÌTÀN 86

Àwọn Ọkùnrin Tí Ìràwọ̀ Kan Darí

Ta ló darí àwọn amòye náà sọ́dọ̀ Jésù? Ìdáhùn náà lè yà ọ́ lẹ́nu.

ÌTÀN 87

Jésù Ọ̀dọ́mọdé Nínú Tẹ́ńpìlì

Ó ní ohun kan tó ya àwọn àgbà ọkùnrin tó ń kọ́ni ní tẹ́ńpìlì pàápàá lẹ́nu.

ÌTÀN 88

Jòhánù Batisí Jésù

Jòhánù ti máa ń ri àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bọmi, àmọ́ nígbà tí Jésù kò dẹ́ṣẹ̀ rí, kí ló dé tí Jòhánù fi rì í bọmi?

ÌTÀN 89

Jésù Fọ Tẹ́ńpìlì Mọ́

Ìfẹ́ tí Jésù ní ló mú kó bínú.

ÌTÀN 90

Pẹ̀lú Obìnrin Kan Lẹ́bàá Kànga

Báwo ni omi tí Jésù ṣe fẹ́ fún un á ṣe jẹ́ kí òùngbẹ má gbẹ ẹ́ mọ́ láé?

ÌTÀN 91

Jésù Kọ́ Àwọn Èèyàn Lórí Òkè

Kọ́ nípa àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó máa ń wúlò ní gbogbo ìgbà tó wà nínú Ìwáású Orí Òkè.

ÌTÀN 92

Jésù Jí Òkú Dìde

Ọ̀rọ̀ méjì péré ni Jésù sọ tó fi fi agbára Ọlọ́run jí ọmọbìnrin Jáírù dìde.

ÌTÀN 93

Jésù Bọ́ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Èèyàn

Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni iṣẹ́ ìyanu tí Jésù fi bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn kọ́ wa?

ÌTÀN 94

Jésù Fẹ́ràn Àwọn Ọmọdé

Jésù kọ́ àwọn àpọ́sítélì pé kì í ṣe pé kí wọ́n máa wo bí àwọn ọmọdé ṣe ń ṣe nìkan ní, àmọ́ kí wọ́n tún máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn dáadáa.

ÌTÀN 95

Ọ̀nà Tí Jésù Gbà Ń Kọ́ni

Jésù sábà máa ń lo irú àkàwé bíi ti ará Samáríà tó jẹ́ aláàánú yìí láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.

ÌTÀN 96

Jésù Wo Àwọn Aláìsàn Sàn

Kí ni gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀?

ÌTÀN 97

Jésù Dé Gẹ́gẹ́ Bí Ọba

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló kí i káàbọ̀, àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ni inú wọn dùn nípa rẹ̀.

ÌTÀN 98

Lórí Òkè Ólífì

Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mẹ́rin nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àsìkò tá a wà yìí.

ÌTÀN 99

Nínú Yàrá Kan Lórí Òkè Pẹ̀tẹ́ẹ̀sì

Kí ló dé tí Jésù fi sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa jẹ oúnjẹ pàtàkì yìí lọ́dọọdún?

ÌTÀN 100

Jésù Nínú Ọgbà

Kí ló dé tí Júdásì fi fi ìfẹnukonu da Jésù?

ÌTÀN 101

Wọ́n Pa Jésù

Nígbà tó ń kú lọ lórí òpó igi oró, o ṣèlérí párádísè.

Mọ Púpọ̀ Sí I

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Kọ Ìtàn Jésù?

Báwo ló ṣe pẹ́ tó lẹ́yìn tí Jésù kú kí wọ́n tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere?

ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!

Ta Ni Jésù Kristi?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdí tí Jésù fi kú, ohun tí ìràpadà jẹ́ àti ohun tí Jésù ń ṣe nísinsìnyí.