Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

 ÌTÀN 78

Ìkọ̀wé Lára Ògiri

Ìkọ̀wé Lára Ògiri

KÍ LÓ ń ṣẹlẹ̀ níbí yìí ná? Ọba àtàwọn èèyàn rẹ̀ ń jàsè ni. Ọba Bábílónì pe ẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn pàtàkì pé kí wọ́n wá bá òun jàsè. Àwọn ife wúrà àti ife fàdákà àti àwo tí wọ́n kó látinú tẹ́ńpìlì Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù ní wọ́n ń lò. Àmọ́, ìka ọwọ́ èèyàn ṣàdédé fara hàn lófuurufú ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ̀wé sára ògiri. Ẹ̀rù ba gbogbo àwọn tó ń jàsè.

Bẹliṣásárì, ọmọ ọmọ Nebukadinésárì ni ọba nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé. Ó ní kí wọ́n lọ pe àwọn ọlọ́gbọ́n Bábílónì wá fóun. Ó sì ṣèlérí pé: ‘Ẹnikẹ́ni tó bá lè ka ohun tí ìka kọ yìí kó sì sọ ohun tó túmọ̀ sí fún mi, olúwa rẹ̀ yóò rí ẹ̀bùn púpọ̀ gbà, màá sì sọ ọ́ di igbá kẹta nínú ìjọba mi.’ Ṣùgbọ́n kò sí ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n náà tó lè ka ohun tí ìka náà kọ sára ògiri, wọn ò sì lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀.

Ìyá ọba gbọ́ ariwo tí wọ́n ń pa ó sì wá sínú iyàrá ńlá níbi tí wọ́n ti ń jàsè. Ó wí fún ọba pé: ‘Jọ̀wọ́ má ṣe jẹ́ kẹ́rù bà ọ́ jù. Ọkùnrin kan ń bẹ nínú ìjọba rẹ tó mọ àwọn ọlọ́run mímọ́. Nígbà tí Nebukadinésárì baba ńlá rẹ jẹ́ ọba, ó sọ ọ́ di olórí gbogbo àwọn ọlọgbọ́n rẹ̀. Dáníẹ́lì ni orúkọ rẹ̀. Ní kí wọ́n lọ pè é wá, yóò sì sọ gbogbo ohun tí èyí túmọ̀ sí fún ọ.’

Ní wàrà-ǹ-ṣeṣà, wọ́n ti lọ mú Dáníẹ́lì wá. Lẹ́yìn ti Dáníẹ́lì ti kọ̀ láti gba ẹ̀bùn èyíkéyìí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ìdí rẹ̀ tí Jèhófà fi mú Nebukadinésárì baba ńlá Bẹliṣásárì kúrò lórí ìtẹ́ ọba nígbà kan rí. Dáníẹ́lì sọ pé: ‘Ó gbéra ga púpọ̀. Jèhófà sì fìyà jẹ ẹ́.’

Dáníẹ́lì wá sọ fún Bẹliṣásárì pé: ‘Ṣùgbọ́n ìwọ mọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i, síbẹ̀ o sì tún ń gbéra ga bíi ti Nebukadinésárì. O kó àwọn ife àti àwo láti inú tẹ́ńpìlì Jèhófà, o sì ń fi wọ́n mutí. O ti yin àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi igi àti òkúta gbẹ́, o ò sì bọlá fún Ẹlẹ́dàá wa Ọlọ́lá Ńlá. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Ọlọ́run fi rán ọwọ́ láti kọ̀wé sára ògiri.’

Dáníẹ́lì wí pé: ‘Ohun tó kọ nìyí: MÉNÈ, MÉNÈ, TÉKÉLÌ àti PÁRÁSÍNÌ.’

‘MÉNÈ túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ti ka iye ọjọ́ ìjọba rẹ, ó sì ti parí rẹ̀. TÉKÉLÌ túmọ̀ sí pé a ti wọ̀n ọ́ lórí ìwọ̀n, o kò kájú ìwọ̀n. PÉRÉSÌ túmọ̀ sí pé a ti fún àwọn ará Mídíà àti Páṣíà ní ìjọba rẹ.’

Dáníẹ́lì ò tiẹ̀ tíì sọ̀rọ̀ tán, táwọn ará Mídíà àti Páṣíà fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lu Bábílónì. Wọ́n kó ìlú náà, wọ́n sì pa Bẹliṣásárì. Òru ọjọ́ yẹn gan-an ni ọ̀rọ̀ tí ìka kọ sára ògiri ní ìmúṣẹ! Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì báyìí o? A máa tóó mọ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáníẹ́lì ná.