Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

APÁ 5

Láti Ìgbà Ìkólẹ́rúlọ-sí-Bábílónì Títí Di Àkókò Títún Odi Jerúsálẹ́mù Kọ́

Láti Ìgbà Ìkólẹ́rúlọ-sí-Bábílónì Títí Di Àkókò Títún Odi Jerúsálẹ́mù Kọ́

Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní ìgbèkùn, ọ̀pọ̀ nǹkan ló dán ìgbàgbọ́ wọn wò. Ọba Bábílónì pàṣẹ pé kí wọ́n ju Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò sínú iná ìléru, àmọ́ Ọlọ́run mú wọn jáde láàyè. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ará Mídíà àti Páṣíà ṣẹ́gun Bábílónì, wọ́n sì ju Dáníẹ́lì sínú ihò kìnnìún, àmọ́ Ọlọ́run tún dáàbò bò ó nípa pípa àwọn kìnnìún lẹ́nu mọ́.

Níkẹyìn, Kírúsì ọba Páṣíà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè. Wọ́n padà sí ìlú wọn lẹ́yìn àádọ́rin [70] ọdún géérégé táwọn ará Bábílónì ti kó wọn nígbèkùn. Ọ̀kan lára ohun tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe nígbà tí wọ́n padà sí Jerúsálẹ́mù ni pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà. Àmọ́, kò pẹ́ káwọn ọ̀tá tó dá wọn dúró lẹ́nu iṣẹ́. Nítorí náà, ní nǹkan bí ọdún méjìlélógún [22] lẹ́yìn tí wọ́n dé Jerúsálẹ́mù ni wọ́n tó kọ́ tẹ́ńpìlì náà parí pátápátá.

Síwájú sí i, a kọ́ nípa ìrìn àjò Ẹ́sírà lọ sí ìlú Jerúsálẹ́mù láti ṣe tẹ́ńpìlì náà lọ́ṣọ̀ọ́. Èyí jẹ́ ní nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta [47] lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ́ tẹ́ńpìlì náà parí. Nígbà tó sì di ọdún mẹ́tàlá lẹ́yìn ìrìn àjò Ẹ́sírà, Nehemáyà ṣèrànwọ́ láti tún odi Jerúsálẹ́mù tó ti wó lulẹ̀ kọ́. Apá KARÙN-ÚN yìí kárí ìtàn ohun tó wáyé láàárín ọdún méjìléláàádọ́jọ [152] títí di àkókó tá a wà yìí.

 

NÍ APÁ YÌÍ

ÌTÀN 77

Wọ́n Kọ̀ Láti Tẹrí Ba

Ṣé Ọlọ́run máa gba àwọn ọkùnrin olóòótọ́ mẹ́ta yìí nínú iná tó ń jó?

ÌTÀN 78

Ìkọ̀wé Lára Ògiri

Wòlíì Dáníẹ́lì túmọ̀ ọ̀rọ̀ mẹ́rin kan tó jẹ́ àdììtú.

ÌTÀN 79

Dáníẹ́lì Nínú Ihò Kìnnìún

Dáníẹ́lì gba ìdájọ́ ikú, àmọ́ ṣé ó ní ohun tó lè ṣe tí kò fi ní kú?

ÌTÀN 80

Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Kúrò Ní Bábílónì

Nígbà tí Ọba Kírúsì ṣẹ́gun ìlú Bábílónì, ó mú àsọtẹ́lẹ̀ kan ṣẹ, ó tún mú òmíràn ṣẹ báyìí.

ÌTÀN 81

Gbígbẹ́kẹ̀lé Ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rú òfin èèyàn kí wọ́n lè ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Ṣé Ọlọ́run á bù kún wọn?

ÌTÀN 82

Módékáì àti Ẹ́sítérì

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ayaba Fáṣítì rẹwà, kí ló dé tí Ọba Ahasuwérúsì fi fi Ẹ́sítérì rọ́pò rẹ̀ bí ayaba?

ÌTÀN 83

Odi Jerúsálẹ́mù

Níbi tí wọ́n ti ń tún ògiri náà kọ́, àfi kí àwọn òṣìṣẹ́ náà máa mú idà àti ọ̀kọ̀ dání tọ̀sántòru.