Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

 ÌTÀN 68

Àwọn Ọmọkùnrin Méjì Tó Jí Dìde

Àwọn Ọmọkùnrin Méjì Tó Jí Dìde

BÓ O bá kú, báwo ló ṣe máa rí lára ìyá rẹ bí ẹnì kan bá tún mú ọ padà bọ̀ sí ìyè? Inú rẹ̀ á mà dùn o! Ṣùgbọ́n ṣé ẹnì kan tó ti kú tún lè wà láàyè bí? Ǹjẹ́ irú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ rí?

Wo ọkùnrin tó wà nínú àwòrán yìí. Tún wo obìnrin àti ọmọdékùnrin yìí. Wòlíì Èlíjà ni ọkùnrin tó ò ń wò yẹn. Obìnrin yẹn ni opó ìlú Sáréfátì, ọmọ rẹ̀ sì ni ọmọdékùnrin yẹn. Ní ọjọ́ kan, ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn. Àìsàn yìí le gan-an débi pé ó kú. Ìgbà náà ni Èlíjà wá sọ fún obìnrin náà pé: ‘Gbé ọmọ náà fún mi.’

Èlíjà gbé òkú ọmọ náà lọ sí òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì ó sì tẹ́ ẹ sórí ibùsùn. Ó gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, jọ̀wọ́, jẹ́ kí ọmọ yìí jí dìde.’ Ọmọ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í mí! Èlíjà wá gbé e sọ̀ kalẹ̀ lọ ó sì wí fún obìnrin náà pé: ‘Wò ó, ọmọ rẹ ń bẹ láàyè!’ Ìdí rèé tí inú ìyá náà fi dùn jọjọ.

Wòlíì pàtàkì míì tí Jèhófà ní ni Èlíṣà. Ó ti ṣe olùrànlọ́wọ́ Èlíjà rí. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá Jèhófà lo Èlíṣà láti ṣe iṣẹ́ ìyanu. Ní ọjọ́ kan, Èlíṣà lọ sí ìlú Ṣúnémù, níbi tí obìnrin kan ti máa ń ṣe dáadáa sí i. Nígbà tó yá, obìnrin yìí bí ọmọkùnrin kan.

Láàárọ̀ ọjọ́ kan, nígbà tí ọmọ yẹn ti dàgbà, ó lọ bá bàbá rẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́ ní oko. Òjijì ni ọmọ yẹn kígbe pé: ‘Orí mi!’ Lẹ́yìn tí wọ́n gbé ọmọ náà dé ilé, ó kú. Wo bí inú ìyá rẹ̀ á ti bà jẹ́ tó! Kíá ló lọ pe Èlíṣà wá.

Nígbà tí Èlíṣà débẹ̀, ó lọ sí iyàrá ibi tí òkú ọmọ náà wà. Ó gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì sùn lé ọmọ náà. Láìpẹ́ ara ọmọkùnrin náà gbóná, ó sì sín ní ìgbà méje. Àbí o ò rí bí inú ìyá rẹ̀ á ti dùn tó nígbà tó wọlé wá tó sì rí ọmọ rẹ̀ láàyè!

Àìmọye èèyàn ló ti kú. Èyí ti ba àwọn ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ wọn nínú jẹ́ gidigidi. Àwa ò lágbára láti jí òkú dìde. Ṣùgbọ́n Jèhófà lágbára rẹ̀. Nígbà tó bá yá, a máa kọ́ nípa bó ṣe máa mú àìmọye ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn padà bọ̀ sí ìyè.