Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

 ÌTÀN 63

Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì

Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì

SÓLÓMỌ́NÌ kò tíì pé ọmọ ogún ọdún nígbà tó di ọba. Ó fẹ́ràn Jèhófà, ó sì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rere tí Dáfídì bàbá rẹ̀ fún un. Inú Jèhófà dùn sí Sólómọ́nì ó sì sọ fún un lóru ọjọ́ kan lójú àlá pé: ‘Sólómọ́nì, kí ni wàá fẹ́ kí n fún ọ?’

Sólómọ́nì bá dáhùn pé: ‘Jèhófà Ọlọ́run mi, ọmọdé ni mí, mi ò sì mọ bí màá ṣeé ṣàkóso. Nítorí náà fún mi ní ọgbọ́n láti ṣàkóso àwọn èèyàn rẹ lọ́nà tó tọ́.’

Inú Jèhófà dùn sí ohun tí Sólómọ́nì béèrè yìí. Nítorí náà, Ó wí pé: ‘Torí pó o béèrè ọgbọ́n, tó ò béèrè fún ẹ̀mí gígùn àti ọrọ̀, màá fún ọ ní ọgbọ́n ju ti ẹnikẹ́ni mìíràn tó tíì gbé láyé. Ṣùgbọ́n màá sì tún fún ọ ní ohun tí o ò béèrè, ìyẹn ọrọ̀ àti ògo.’

Kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn obìnrin méjì kan mú ìṣòro ńlá kan tọ Sólómọ́nì wá. Ọ̀kan nínú wọn ṣàlàyé pé: ‘Èmi àtobìnrin yìí la jọ ń gbénú ilé kan náà. Mo bí ọmọkùnrin kan, òun náà sì bí ọmọkùnrin kan ní ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà. Àmọ́ ọmọ tirẹ̀ kú lóru ọjọ́ kan. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo wà lójú oorun, ó gbé òkú ọmọ tiẹ̀ sọ́dọ̀ mi ó sì gbé ọmọ tèmi. Nígbà tí mo jí tí mo sì wo òkú ọmọ náà, mo rí i pé kì í ṣe ọmọ tèmi.’

Bó ti sọ èyí tán ni obìnrin kejì wí pé: ‘Rárá o! Alààyè ọmọ ni tèmi, òun ló ni òkú ọmọ!’ Obìnrin àkọ́kọ́ náà ní: ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́! Ìwọ lo ni òkú ọmọ, tèmi sì ni alààyè ọmọ!’ Báwọn obìnrin náà ṣe ń jiyàn rèé. Kí ni kí Sólómọ́nì ṣe?

Ó ní kí wọ́n mú idà wá, ìgbà tí wọ́n sì mú un dé, ó sọ pé: ‘Ẹ la alààyè ọmọ náà sí méjì, kó o sì fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn obìnrin náà ní ìdajì rẹ̀.’

Ẹni tó jẹ́ ìyá ọmọ gan-an kígbe pé: ‘Rárá o! Ẹ jọ̀ọ́, ẹ má pa ọmọ yìí. Ẹ gbé e fún un!’ Ṣùgbọ́n obìnrin kejì sọ pé: ‘Ẹ má ṣe gbé e fún ẹnikẹ́ni nínú wa; ó yá, ẹ là á sí méjì.’

Níkẹyìn, Sólómọ́nì sọ pé: ‘Má ṣe pa ọmọ náà! Gbé e fún obìnrin kìíní. Òun ni ìyá ọmọ náà ní tòótọ́.’ Ohun tó mú kí Sólómọ́nì mọ ìyẹn ni pé ó rí i bí ìyá ọmọ náà ṣe fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ tó débi tó fi fẹ́ kí wọ́n gbé e fún obìnrin míì kí wọ́n má bàa pa á. Nígbà táwọn èèyàn gbọ́ bí Sólómọ́nì ṣe yanjú ìṣòro náà, inú wọn dùn láti ní irú ọlọgbọ́n ọba bẹ́ẹ̀.

Nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì, Ọlọ́run bù kún àwọn èèyàn nípa jíjẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà àti báálì, àwọn àjàrà àti ọ̀pọ̀tọ́ àtàwọn oúnjẹ mìíràn hù. Àwọn èèyàn ń wọ aṣọ tó dára, wọ́n sì ń gbé inú ilé tó dára. Oríṣiríṣi ohun rere ló wà fún gbogbo èèyàn ní ànító àti ní àníṣẹ́kù.

Mọ Púpọ̀ Sí I

KÁÀDÌ ERÉ BÍBÉLÌ

Káàdì Eré Bíbélì Nípa Sólómọ́nì

Wa káàdì eré Bíbélì yìí jáde, kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa Sólómọ́nì Ọba.