Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÌTÀN 75

Ọmọkùnrin Mẹ́rin Ní Bábílónì

Ọmọkùnrin Mẹ́rin Ní Bábílónì

NEBUKADINÉSÁRÌ ọba kó gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kàwé jù lọ sí Bábílónì. Lẹ́yìn náà, ọba yan àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tó lẹ́wà tó sì já fáfá jù lọ lára wọn. Mẹ́rin lára wọn ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tó ò ń wò nínú àwòrán yìí. Orúkọ ọ̀kan ni Dáníẹ́lì, àwọn mẹ́ta tó kù ni àwọn ará Bábílónì pè ní Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò.

Nebukadinésárì ṣètò láti kọ́ àwọn ọmọkùnrin yẹn láti máa ṣiṣẹ́ ní ààfin rẹ̀. Lẹ́yìn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọdún mẹ́ta, á wá yan kìkì àwọn tó bá já fáfá jù lọ láti máa ràn án lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro. Ọba fẹ́ káwọn ọmọkùnrin yìí lókun kára wọn sì le ní àkókò tí wọ́n ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Nítorí náà, ó pàṣẹ pé kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ máa fún gbogbo wọn lóúnjẹ tó dọ́ṣọ̀ àti wáìnì tí òun àti ìdílé rẹ̀ ń gbádùn.

Wo Dáníẹ́lì ọ̀dọ́. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ń sọ fún Áṣípénásì, olórí àwọn ìránṣẹ́ Nebukadinésárì? Dáníẹ́lì ń sọ fún un pé òun kò fẹ́ láti jẹ àwọn nǹkan tó dọ́ṣọ̀ tó ti orí tábìlì ọba wá yẹn. Àmọ́ ọ̀ràn yẹn ń dààmú Áṣípénásì. Ó wí pé: ‘Ọba ti pinnu ohun tẹ́ ẹ ní láti jẹ àti ohun tẹ́ ẹ ní láti mu. Bí ara yín ò bá sì dá ṣáṣá bíi tàwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yòókù, ọba lè pa mí.’

Nítorí náà, Dáníẹ́lì lọ sí ọ̀dọ̀ olùtọ́jú tí Áṣípénásì ní kó máa tọ́jú òun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta. Ó wí pé: ‘Jọ̀wọ́ dán wa wò fún ọjọ́ mẹ́wàá. Fún wa ní àwọn oúnjẹ ewébẹ̀ láti jẹ àti omi láti mu. Lẹ́yìn náà fi wá wéra pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yòókù tó ń jẹ oúnjẹ ọba, kó o sì wo ẹni tó máa sanra tó sì máa dán jù.’

Olùtọ́jú yẹn gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ọjọ́ mẹ́wàá sì pé, ara Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta ló dá ṣáṣá ju ti gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yòókù lọ. Nítorí náà, olùtọ́jú yẹn gbà fún wọn láti máa jẹ àwọn oúnjẹ ewébẹ̀ dípò ohun tí ọba pèsè.

Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, wọ́n kó gbogbo wọn lọ sọ́dọ̀ Nebukadinésárì. Lẹ́yìn tí ọba bá gbogbo wọn sọ̀rọ̀, ó rí i pé Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta ló já fáfá jù lọ. Nítorí náà, ó dá wọn dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ láti máa ràn án lọ́wọ́, ní ààfin. Nígbàkigbà tí ọba bá sì béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Dáníẹ́lì, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò tàbí tó fún wọn ní ìṣòro líle koko, wọ́n mọ ojútùú rẹ̀ ní ìlọ́po mẹ́wàá ju èyíkéyìí lọ nínú àwọn àlùfáà tàbí àwọn ọlọgbọ́n rẹ̀.