Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÌTÀN 67

Jèhóṣáfátì Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

Jèhóṣáfátì Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

ǸJẸ́ o mọ ẹni táwọn èèyàn wọ̀nyí jẹ́, ṣó o sì mọ ohun tí wọ́n ń ṣe? Ojú ogun ni wọ́n ń lọ yẹn o, táwọn ọkùnrin tó wà níwájú wọn sì ń kọrin. Ṣùgbọ́n ìwọ lè béèrè pé: ‘Kí ló dé táwọn akọrin náà ò fi ní idà àti ọ̀kọ̀ tí wọ́n á fi jà?’ Jẹ́ ká wò ó ná.

Jèhóṣáfátì ni ọba ìjọba ẹ̀yà méjì Ísírẹ́lì. Ó gbé ayé ní àkókò kan náà tí Áhábù Ọba àti Jésíbẹ́lì fi jọba lórí ẹ̀yà mẹ́wàá ní àríwá. Ṣùgbọ́n ọba rere ni Jèhóṣáfátì, bàbá rẹ̀ Ásà sì jẹ́ ọba rere pẹ̀lú. Nítorí náà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún làwọn èèyàn tó wà nínú ìjọba ẹ̀yà méjì ní gúúsù fi gbádùn ìgbésí ayé rere.

Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú káwọn èèyàn bẹ̀rù. Àwọn oníṣẹ́ ròyìn fún Jèhóṣáfátì pé: ‘Ẹgbẹ́ ogun ńlá láti orílẹ̀-èdè Móábù, Ámónì àti Òkè Séírì ń bọ̀ wá láti bá yín jà.’ Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé jọ ní Jerúsálẹ́mù láti wá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà. Wọ́n lọ sí tẹ́ńpìlì, ibẹ̀ ni Jèhóṣáfátì sì ti gbàdúrà pé: ‘Jèhófà Ọlọ́run wa, àwa ò mọ ohun tá a lè ṣe. A ò ní agbára láti dojú kọ ẹgbẹ́ ogun ńlá yìí. A ń wojú rẹ fún ìrànlọ́wọ́.’

Jèhófà gbọ́ àdúrà rẹ̀, ó mú kí ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ fún àwọn èèyàn yẹn pé: ‘Ogun náà kì í ṣe tiyín, ti Ọlọ́run ni. Ẹ ò ní ìjà láti jà. Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kẹ́ ẹ sì rí bí Jèhófà ṣe máa gbà yín là.’

Nítorí náà, nígbà tó di àárọ̀ ọjọ́ kejì, Jèhóṣáfátì sọ fáwọn èèyàn náà pé: ‘Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà!’ Ó wá fi àwọn akọrin sí iwájú àwọn ọmọ ogun rẹ̀, bí wọ́n sì ṣe ń rìn lọ wọ́n ń kọ orin ìyìn sí Jèhófà. Ṣé o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n sún mọ́ ojú ogun? Jèhófà mú kí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn jà. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì débẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ ogun ọ̀tá ti kú!

Ṣé Jèhóṣáfátì ò gbọ́n bó ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? Àwa pẹ̀lú á jẹ́ ọlọgbọ́n bá a bá gbẹ́kẹ́ lé Jèhófà.