Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÌTÀN 69

Ọmọbìnrin Kan Ran Ọkùnrin Alágbára Kan Lọ́wọ́

Ọmọbìnrin Kan Ran Ọkùnrin Alágbára Kan Lọ́wọ́

ÌWỌ ha mọ ohun tí ọmọbìnrin kékeré yìí ń sọ? Ó ń sọ fún obìnrin yìí nípa Èlíṣà wòlíì Jèhófà, àti àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jèhófà ti ràn án lọ́wọ́ láti ṣe. Obìnrin náà kò mọ̀ nípa Jèhófà nítorí pé kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì. Ó dáa, jẹ́ ká wá wo ìdí rẹ̀ tí ọmọbìnrin náà fi wà nínú ilé obìnrin yìí.

Ará Síríà ni obìnrin náà. Náámánì, olórí ogun Síríà ni ọkọ rẹ̀. Àwọn ará Síríà ló mú ọmọbìnrin Ísírẹ́lì yìí ní ìgbèkùn, wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ ìyàwó Náámánì láti máa ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀.

Náámánì ní àrùn burúkú kan tó ń jẹ́ ẹ̀tẹ̀. Àrùn yìí tiẹ̀ lè mú kí díẹ̀ nínú ẹ̀yà ara èèyàn gé dà nù. Nítorí náà, ọmọbìnrin yìí sọ fún ìyàwó Náámánì pé: ‘Ì bá mà dára o, ká ní olúwa mi lè lọ sọ́dọ̀ wòlíì Jèhófà ní Ísírẹ́lì. Ó máa wo ẹ̀tẹ̀ wọn sàn.’ Lẹ́yìn náà, obìnrin yẹn sọ ohun tí ọmọbìnrin kékeré yìí sọ fún ọkọ rẹ̀.

Náámánì ń fẹ́ ìwòsàn lójú méjèèjì; nítorí náà, ó pinnu láti lọ sí Ísírẹ́lì. Nígbà tó dé ọ̀hún, ó lọ sí ilé Èlíṣà. Èlíṣà rán ìránṣẹ́ rẹ̀ láti sọ fún Náámánì pé kó lọ wẹ̀ ní Odò Jọ́dánì nígbà méje. Èyí bí Náámánì nínú gan-an ni, ó sọ pé: ‘Àwọn odò ìlú wa lọ́hùn-ún dára ju odò èyíkéyìí ní Ísírẹ́lì lọ!’ Bí Náámánì ṣe sọ̀rọ̀ yẹn tán báyìí ló yí padà tó fẹ́ máa lọ.

Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ̀ kan wí fún un pé: ‘Ọ̀gá mi, bí Èlíṣà bá wí fún yín pé kẹ́ ẹ ṣe ohun tó ṣòro, ẹ mà máa ṣe é. Kí ló wá dé tí ẹ ò fi lè wẹ ara yín lásán kẹ́ ẹ sì mọ́ bó ṣe sọ?’ Náámánì gbọ́ ọ̀rọ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu ó sì lọ ri ara rẹ̀ bọ inú Odò Jọ́dánì ní ìgbà méje. Nígbà tó ṣe bẹ́ẹ̀, àrùn ara rẹ̀ lọ, ó sì mọ́ tónítóní!

Inú Náámánì dùn púpọ̀. Ó padà lọ sọ́dọ̀ Èlíṣà, ó sì sọ fún un pé: ‘Nísinsìnyí, mo gbà dájúdájú pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo ní gbogbo ayé. Nítorí náà, jọ̀wọ́, gba ẹ̀bùn yìí lọ́wọ́ mi.’ Ṣùgbọ́n Èlíṣà dáhùn pé: ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, mi ò ní gbà á.’ Èlíṣà mọ̀ pé ó lòdì fún òun láti gba ẹ̀bùn, nítorí pé Jèhófà ló wo Náámánì sàn. Ṣùgbọ́n Géhásì ìránṣẹ́ Èlíṣà fẹ́ ẹ̀bùn náà fún ara rẹ̀.

Nítorí náà, ohun tí Géhásì ṣe nìyí. Lẹ́yìn tí Náámánì ti lọ, Géhásì sáré láti lè bá Náámánì lọ́nà. Ó wí fún Náámánì pé: ‘Èlíṣà rán mi láti sọ fún ọ pé òun fẹ́ ẹ̀bùn díẹ̀ lára ẹ̀bùn rẹ láti fún àwọn ọ̀rẹ́ òun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá kí òun!’ Ṣùgbọ́n, irọ́ ni èyí. Náámánì kò kúkú mọ̀ pé irọ́ ni; nítorí náà, ó fún Géhásì ní díẹ̀ nínú àwọn ẹ̀bùn náà.

Nígbà tí Géhásì dé ilé, Èlíṣà ti mọ ohun tó ṣe. Jèhófà ló sọ ọ́ fún un. Nítorí náà, ó wí pé: ‘Nítorí pé o ṣe ohun búburú yìí, ẹ̀tẹ̀ Náámánì máa lẹ̀ mọ́ ọ.’ Ó sì rí bẹ́ẹ̀ lójú ẹsẹ̀!

Kí la lè rí kọ́ nínú gbogbo èyí? Èkíní, pé a ní láti dà bí ọmọbìnrin kékeré náà ká sì máa sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Ohun rere tó pọ̀ ló lè tẹ̀yìn ẹ̀ wá. Èkejì, a ò gbọ́dọ̀ gbéra ga gẹ́gẹ́ bí Náámánì ti ṣe ní àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ máa gbọ́ràn sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́nu. Ẹ̀kẹta sì ni pé a kò gbọ́dọ̀ purọ́ bíi ti Géhásì. Ǹjẹ́ o ò rí i pé a lè rí ẹ̀kọ́ tó pọ̀ kọ́ látinú kíka Bíbélì?