Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

APÁ 4

Láti Ìgbà Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì sí Ìgbà Ìgbèkùn ní Bábílónì

Láti Ìgbà Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì sí Ìgbà Ìgbèkùn ní Bábílónì

Sọ́ọ̀lù di ọba àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì. Ṣùgbọ́n Jèhófà kọ̀ ọ́, ó sì yan Dáfídì ní ọba dípò rẹ̀. A ó mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Dáfídì. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó bá Gòláyátì òmìrán jà. Nígbà tó yá, ó sá lọ fún Sọ́ọ̀lù Ọba òjòwú. Lẹ́yìn náà, Ábígẹ́lì arẹwà kò jẹ́ kó hùwà búburú kan.

Lẹ́yìn èyí, a ó mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan nípa Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì, ẹni tó gba ipò Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba Ísírẹ́lì. Ogójì ọdún ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọba mẹ́ta àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì fi jọba. Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì kú, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pín sí ìjọba méjì, ìjọba àríwá àti ìjọba gúúsù.

Igba ọdún ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [257] ni Ìjọba àríwá, tó ní ẹ̀yà mẹ́wàá, fi wà kí àwọn ará Ásíríà tó pa á run. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún ó lé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [133] lẹ́yìn náà ni Ìjọba ìhà gúúsù tó ní ẹ̀yà méjì pẹ̀lú pa run. Àkókò yìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì. Nítorí náà, ìtàn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ó lé mẹ́wàá [510] ló wà ní Apá KẸRIN. Lákòókò yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣẹlẹ̀.

 

NÍ APÁ YÌÍ

ÌTÀN 56

Sọ́ọ̀lù—Ọba Àkọ́kọ́ Ní Ísírẹ́lì

Ọlọ́run ló yan Sọ́ọ̀lù ní ìbẹ̀rẹ̀, àmọ́ ó kọ̀ ọ́ nígbà tó yá. A lè kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì látinú ọ̀rọ̀ Sọ́ọ̀lù.

ÌTÀN 57

Ọlọ́run Yan Dáfídì

Kí ni Ọlọ́run rí lára Dáfídì tí wòlíì Sámúẹ́lì ò rí?

ÌTÀN 58

Dáfídì àti Gòláyátì

Kì í ṣe kànnàkànnà nìkan ni Dáfídì fi bá Gòláyátì jà, agbára ńlá kan ló lò.

ÌTÀN 59

Ìdí Tí Dáfídì Fi Gbọ́dọ̀ Sá Lọ

Inú Sọ́ọ̀lù kọ́kọ́ dùn sí Dáfídì, àmọ́ nígbà tó yá ó bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Sọ́ọ̀lù débi pé ó fẹ́ pa á. Kí ló dé?

ÌTÀN 60

Ábígẹ́lì àti Dáfídì

Ábígẹ́lì pe ọkọ rẹ̀ ní aláìmọ̀kan, àmọ́ ìyẹn ni kò jẹ́ kí wọ́n gbẹ̀míí ọkọ rẹ̀ lọ́jọ́ náà.

ÌTÀN 61

Wọ́n Fi Dáfídì Jọba

Àwọn ohun tí Dáfídì ṣe àti àwọn ohun tí kò ṣe fi hàn pé ó kúnjú ìwọ̀n láti di ọba Ísírẹ́lì.

ÌTÀN 62

Wàhálà Nínú Ilé Dáfídì

Àṣìṣe kan ṣoṣo péré ni Dáfídì ṣe tó fi kó wàhálà bá òun àti ìdílé rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún.

ÌTÀN 63

Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì

Ṣé Sólómọ́nì máa gé ọmọ ìkókó yìí sí méjì lóòótọ́?

ÌTÀN 64

Sólómọ́nì Kọ́ Tẹ́ńpìlì

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́gbọ́n ní Sólómọ́nì, wọ́n tì í ṣe ohun tí kò mọ́gbọ́n dání, tó sì burú.

ÌTÀN 65

Ìjọba Náà Pín sí Méjì

Gbàrà tí Jèróbóámù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ló ti mú kí àwọn èèyàn náà máa rú òfin Ọlọ́run.

ÌTÀN 66

Jésíbẹ́lì—Ayaba Búburú

Kò sí nǹkan tí kò ní ṣe kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ ohunkóhun tó bá fẹ́.

ÌTÀN 67

Jèhóṣáfátì Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

Kí ló dé tó ṣe jẹ́ pé àwọn akọrin tí kò ní ohun ìjà kankan ló ṣáájú àwọn ọmọ ogun lọ sójú ogun?

ÌTÀN 68

Àwọn Ọmọkùnrin Méjì Tó Jí Dìde

Ṣé ẹni tó ti kú lé jíǹde? Ó ti ṣẹlẹ̀ rí!

ÌTÀN 69

Ọmọbìnrin Kan Ran Ọkùnrin Alágbára Kan Lọ́wọ́

Ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀, ìyẹn sì mú kí iṣẹ́ ìyanu kan ṣẹlẹ̀.

ÌTÀN 70

Jónà àti Ẹja Ńlá Náà

Jónà kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì, pé kí èèyàn máa ṣe ohun tí Jèhófà bá sọ.

ÌTÀN 71

Ọlọ́run Ṣèlérí Párádísè

Párádisè àkọ́kọ́ kéré, èyí tó ń bọ̀ yìí máa bo gbogbo ayé.

ÌTÀN 72

Ọlọ́run Ran Hesekáyà Ọba Lọ́wọ́

Ní òrú ọjọ́ kan, áńgẹ́lì kan pa 185,000 ọmọ ogun Ásíríà.

ÌTÀN 73

Ọba Rere Tó Jẹ Kẹ́yìn ní Ísírẹ́lì

Jòsáyà kò tíì pé ọmọ ogun ọdún nígbà tó ṣe nǹkan kan tó gba ìgboyà.

ÌTÀN 73

Ọba Rere Tó Jẹ Kẹ́yìn ní Ísírẹ́lì

Jòsáyà kò tíì pé ọmọ ogun ọdún nígbà tó ṣe nǹkan kan tó gba ìgboyà.

ÌTÀN 75

Ọmọkùnrin Mẹ́rin Ní Bábílónì

Wọ́n ṣe ohun tó tọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kó wọn kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn.

ÌTÀN 76

Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Run

Kí ló dé tí Ọlọ́run ṣe jẹ́ kí àwọn ará Bábílónì tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá Ísírẹ́lì pa Jerúsálẹ́mù run?