Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

 ÌTÀN 55

Ọmọkùnrin Kékeré Kan Sin Ọlọ́run

Ọmọkùnrin Kékeré Kan Sin Ọlọ́run

O Ò RÍ i pé arẹwà ọmọ ni ọmọkùnrin yìí? Sámúẹ́lì ni orúkọ rẹ̀. Ọkùnrin tó sì gbé ọwọ́ lé orí Sámúẹ́lì yìí ni Élì, olórí àlùfáà Ísírẹ́lì. Ẹlikénà bàbá Sámúẹ́lì àti Hánà ìyá rẹ̀ nìyẹn, àwọn ló mú Sámúẹ́lì wá sọ́dọ̀ Élì.

Sámúẹ́lì ò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́rin sí márùn-ún péré lọ nígbà yẹn. Ṣùgbọ́n òun yóò máa gbé inú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà pẹ̀lú Élì àtàwọn àlùfáà mìíràn. Kí ló dé tí Ẹlikénà àti Hánà fi gbà kí irú Sámúẹ́lì kékeré yìí máa sin Jèhófà nínú àgọ́ ìjọsìn rẹ̀? Jẹ́ ká wo ìdí rẹ̀.

Ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni inú Hánà bà jẹ́ gidigidi. Ìdí ni pé kò lè bímọ, ó sì ń wù ú lójú méjèèjì pé kí òun bí ọmọ. Nítorí náà, ní ọjọ́ kan tí Hánà lọ sínú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà, ó gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, má ṣe gbàgbé mi! Bó o bá fún mi ní ọmọkùnrin kan, mo ṣèlérí pé màá fi í fún ọ kó lè máa sìn ọ́ ní gbogbo ayé rẹ̀.’

Jèhófà gbọ́ àdúrà Hánà, ní àwọn oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, ó bí Sámúẹ́lì. Hánà fẹ́ràn ọmọkùnrin rẹ̀ kékeré náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́ Jèhófà nígbà tó ṣì wà lọ́mọ ọwọ́. Ó wí fún ọkọ rẹ̀ pé: ‘Kété tí mo bá ti já ọmú lẹ́nu Sámúẹ́lì ni màá mú un lọ sí àgọ́ ìjọsìn láti máa sin Jèhófà níbẹ̀.’

Ohun la rí tí Hánà àti Ẹlikénà ń ṣe nínú àwòrán yìí. Nítorí pé àwọn òbí Sámúẹ́lì sì ti kọ́ ọ dáadáa, inú rẹ̀ dùn láti máa sin Jèhófà nínú àgọ́ Jèhófà. Ọdọọdún ni Hánà àti Ẹlikénà máa ń wá láti jọ́sìn nínú àgọ́ pàtàkì yìí kí wọ́n sì bẹ ọmọkùnrin wọn kékeré wò. Ọdọọdún sì ni Hánà máa ń mú ẹ̀wù kòlápá tuntun kan tó máa ń hun fúnra rẹ̀ wá fún Sámúẹ́lì.

Bí ọdún ti ń gorí ọdún, Sámúẹ́lì ń sìn nìṣó nínú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà, Jèhófà àtàwọn èèyàn sì fẹ́ràn rẹ̀. Ṣùgbọ́n Hófínì àti Fíníhásì, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Élì olórí àlùfáà, kì í ṣe ọmọ dáadáa. Ọ̀pọ̀ ohun búburú ni wọ́n máa ń ṣe, wọ́n sì máa ń mú kí àwọn ẹlòmíràn ṣàìgbọràn sí Jèhófà pẹ̀lú. Ńṣe ló yẹ kí Élì yọ wọ́n kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà, ṣùgbọ́n kò ṣe bẹ́ẹ̀.

Sámúẹ́lì ọ̀dọ́ kò jẹ́ kí èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan búburú tí wọ́n ń ṣe nínú àgọ́ ìjọsìn náà sún òun láti má sin Jèhófà mọ́. Ṣùgbọ́n nítorí pé iye àwọn èèyàn tó fẹ́ràn Jèhófà ní tòótọ́ ò pọ̀, ó pẹ́ púpọ̀ sẹ́yìn tí Jèhófà ti bá ẹ̀dá èèyàn kankan sọ̀rọ̀. Nígbà tí Sámúẹ́lì dàgbà díẹ̀ sí i ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyí:

Ojú oorun ni Sámúẹ́lì wà nínú àgọ́ ìjọsìn nígbà tí ohùn kan jí i dìde. Ó dáhùn pé: ‘Èmi nìyí.’ Ó sì dìde, ó sáré tọ Élì lọ, ó wí pé: ‘Ẹ pè mí, èmi nìyí.’

Ṣùgbọ́n Élì dáhùn pé: ‘Mi ò pè ọ́; padà lọ sùn.’ Nítorí náà, Sámúẹ́lì padà lọ sùn.

Nígbà tó ṣe ó tún gbọ́ ìpè náà lẹ́ẹ̀kejì pé: ‘Sámúẹ́lì!’ Nítorí náà, Sámúẹ́lì dìde ó sì tún sáré tọ Élì lọ. Ó wí pé: ‘Ẹ pè mi, èmi nìyí.’ Ṣùgbọ́n Élì dá a lóhùn pé: ‘Mi ò pè ọ́ ọmọ mi. Padà lọ sùn.’ Nítorí náà, Sámúẹ́lì padà lọ sùn.

Ohùn náà tún pè ní ìgbà kẹta pé: ‘Sámúẹ́lì!’ Nítorí náà, Sámúẹ́lì tún sáré tọ Élì lọ. Ó wí pé: ‘Èmi nìyí, nítorí ó ní láti jẹ́ pé ẹ̀yin lẹ̀ ń pè mí lọ́tẹ̀ yìí.’ Élì wá mọ̀ nísinsìnyí pé ó ní láti jẹ́ pé Jèhófà ló ń pe ọmọ náà. Nítorí náà, ó wí fún Sámúẹ́lì pé: ‘Tún padà lọ sùn, bó o bá sì tún gbọ́ tó pè ọ́, kó o dáhùn pé: “Máa wí, Jèhófà, nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.”’

Sámúẹ́lì wí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ nígbà tí Jèhófà tún pè é. Ni Jèhófà bá wí fún Sámúẹ́lì pé òun á fi ìyà jẹ Élì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Nígbà tó yá, Hófínì àti Fíníhásì kú nínú ogun kan tí wọ́n bá àwọn Filísínì jà, nígbà tí Élì sì gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ṣubú sẹ́yìn, ọrùn rẹ̀ sì ṣẹ́, ó sì kú. Báyìí ni ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe ṣẹ.

Sámúẹ́lì dàgbà, ó sì di onídàájọ́ tó kẹ́yìn ní Ísírẹ́lì. Nígbà tó darúgbó, àwọn èèyàn náà wí fún un pé: ‘Yan ọba kan fún wa tí yóò máa ṣàkóso wa.’ Sámúẹ́lì kò fẹ́ ṣe èyí, nítorí pé ní tòótọ́, Jèhófà ni ọba wọn. Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún un pé kó gbọ́ tiwọn.