Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÌTÀN 51

Rúùtù Àti Náómì

Rúùtù Àti Náómì

NÍNÚ Bíbélì, wàá rí ìwé kan tó ń jẹ́ Rúùtù. Ìtàn nípa ìdílé kan tí wọ́n gbé ayé nígbà tí Ísírẹ́lì ní àwọn onídàájọ́ ló wà nínú ìwé náà. Rúùtù jẹ́ omidan kan láti ilẹ̀ Móábù; òun kì í ṣe ará Ísírẹ́lì tí í ṣe orílẹ̀-èdè Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n nígbà tí Rúùtù kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, ó fẹ́ràn rẹ̀ gidigidi. Náómì ni àgbà obìnrin tó ran Rúùtù lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa Jèhófà.

Ará Ísírẹ́lì ni Náómì. Òun àti ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjì ṣí lọ sí ilẹ̀ Móábù ní àkókò tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí oúnjẹ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Nígbà tó yá, ní ọjọ́ kan, ọkọ Náómì kú. Ẹ̀yìn ìgbà náà ni àwọn ọmọkùnrin Náómì gbé àwọn ọmọbìnrin Móábù méjì, ìyẹn Rúùtù àti Ópà, níyàwó. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́wàá, àwọn ọmọkùnrin Náómì méjèèjì kú. Ẹ ò rí i bí inú Náómì àtàwọn ọmọbìnrin méjèèjì náà á ti bà jẹ́ tó! Kí ni Náómì á wá ṣe báyìí o?

Ní ọjọ́ kan, Náómì pinnu pé òun á rin ìrìn àjò padà sí ìlú òun sọ́dọ̀ àwọn èèyàn òun. Rúùtù àti Ópà fẹ́ láti máa bá a gbé, nítorí náà àwọn náà tẹ̀ lé e. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n ti rìn jìnnà díẹ̀, Náómì kọjú sí àwọn ọmọbìnrin náà ó sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ padà sí ilé kẹ́ ẹ sì lọ máa bá ìyá yín gbé.’

Náómì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu pé ó dàbọ̀. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún nìyẹn nítorí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Náómì gidigidi. Wọ́n wí pé: ‘Rárá! A óò bá ọ lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ.’ Ṣùgbọ́n Náómì dáhùn pé: ‘Ńṣe ni kẹ́ ẹ padà, ẹ̀yin ọmọbìnrin mi. Nǹkan á sàn fún yín ní ilé yín.’ Nítorí náà, Ópà yí padà láti lọ sí ilé. Ṣùgbọ́n Rúùtù kọ̀ kò padà ní tiẹ̀.

Náómì kọjú sí i, ó sì wí pé: ‘Ópà ti padà. Ìwọ náà bá a padà sílé.’ Ṣùgbọ́n Rúùtù dáhùn pé: ‘Má ṣe gbìyànjú láti mú kí n fi ọ́ sílẹ̀! Jẹ́ kí n máa bá ọ lọ. Ibi tó o bá lọ ni màá lọ, ibi tó o bá sì ń gbé ni màá máa gbé. Àwọn èèyàn rẹ ló máa jẹ́ èèyàn mi, Ọlọ́run rẹ sì ló máa jẹ́ Ọlọ́run mi. Ibi tó o bá kú sí ni màá kú sí, ibẹ̀ ni wọ́n sì máa sin mí sí.’ Ìgbà tí Rúùtù sọ báyìí tán, Náómì ò tún gbìyànjú láti sọ pé kó padà sílé mọ́.

Níkẹyìn, Náómì àti Rúùtù dé ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Ibẹ̀ ni wọ́n fìdí kalẹ̀ sí tí wọ́n ń gbé. Nítorí pé àkókò ìkórè ọkà báálì ni, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Rúùtù ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ nínú oko. Ọkùnrin kan báyìí tó ń jẹ́ Bóásì jẹ́ kó máa ṣa ọkà báálì nínú oko òun. Ǹjẹ́ o mọ ìyá Bóásì? Ráhábù ará ìlú Jẹ́ríkò ni.

Ní ọjọ́ kan Bóásì sọ fún Rúùtù pé: ‘Mo ti gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ nípa rẹ àti bó o ṣe jẹ́ onínúure sí Náómì tó. Mo gbọ́ nípa bó o ṣe fi bàbá àti ìyá àti orílẹ̀-èdè rẹ sílẹ̀ tó o sì wá ń gbé láàárín àwọn èèyàn tó ò mọ̀ rí. Kí Jèhófà ṣàánú fún ọ!’

Rúùtù dáhùn pé: ‘Ọ̀gá, ẹ ti ṣàánú fún mi gan-an. Ẹ ti mú kí ara tù mí nípa ọ̀nà tẹ́ ẹ gbà bá mi sọ̀rọ̀ yìí.’ Bóásì fẹ́ràn Rúùtù gidigidi, kò sì pẹ́ lẹ́yìn èyí tí wọ́n fi di tọkọtaya. Wo bí èyí ti mú inú Náómì dùn tó! Ṣùgbọ́n inú Náómì wá túbọ̀ dùn gan-an nígbà tí Rúùtù àti Bóásì bí ọmọkùnrin wọn àkọ́kọ́ tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Óbédì. Nígbà tó yá, Óbédì di bàbá bàbá Dáfídì, ẹni tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ nípa rẹ̀ níwájú.

Ìwé Rúùtù nínú Bíbélì.