ÀWỌN ọkùnrin wọ̀nyí wà nínú ìṣòro. Wọ́n gbọ́dọ̀ wá ọ̀nà sá jáde, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ wọ́n máa pa wọ́n. Amí ni wọ́n láti Ísírẹ́lì, obìnrin tó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ ni Ráhábù. Ibí yìí ni Ráhábù ń gbé nínú ilé kan tí wọ́n kọ́ mọ́ ara odi ìlú Jẹ́ríkò. Jẹ́ ká wo ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi wà nínú ìṣòro.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fẹ́ ré Odò Jọ́dánì kọjá sí ilẹ̀ Kénáánì. Ṣùgbọ́n kí wọ́n tó ṣe bẹ́ẹ̀, Jóṣúà rán àwọn amí méjì jáde. Ó wí fún wọn pé: ‘Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà àti ìlú Jẹ́ríkò.’

Nígbà tí àwọn amí náà wọ Jẹ́ríkò, wọ́n lọ sí ilé Ráhábù. Ṣùgbọ́n ẹnì kan ti lọ sọ fún ọba Jẹ́ríkò pé: ‘Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì ti wọ ìlú yìí lálẹ́ yìí láti ṣe amí ilẹ̀ wa.’ Nígbà tí ọba gbọ́, ó rán àwọn èèyàn sí Ráhábù, wọ́n sì pàṣẹ fún un pé: ‘Mú àwọn ẹni tó o fi pa mọ́ sínú ilé ẹ jáde!’ Ṣùgbọ́n Ráhábù ti fi àwọn amí náà pa mọ́ sí orí òrùlé rẹ̀. Nítorí náà, ó wí pé: ‘Òótọ́ ni àwọn ọkùnrin kan wá sí ilé mi, ṣùgbọ́n èmi ò mọ ibi tí wọ́n ti wá. Bí ilẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣú, gẹ́rẹ́ kí wọ́n tó ti ẹnubodè ìlú ni wọ́n ti lọ. Bẹ́ ẹ bá yára, ọwọ́ yín lè tẹ̀ wọ́n!’ Ni àwọn èèyàn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í lépa wọn.

Lẹ́yìn tí wọ́n ti lọ, Ráhábù yára lọ sí orí òrùlé. Ó sọ fún àwọn amí náà pé: ‘Mo mọ̀ pé Jèhófà máa fi ìlú yìí lé yín lọ́wọ́. A ti gbọ́ bó ṣe mú kí Òkun Pupa gbẹ nígbà tẹ́ ẹ kúrò ní Íjíbítì, àti bẹ́ ẹ ṣe pa àwọn Síhónì àti Ógù tí wọ́n jẹ́ ọba. Mo ti ṣe yín lóore, nítorí náà, ẹ̀yin náà, ẹ jọ̀wọ́ ṣèlérí pé ẹ máa ṣe mí lóore. Ẹ dá bàbá mi àti ìyá mi sí, àtàwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin mi.’

Àwọn amí náà ṣèlérí pé àwọn yóò ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ pé Ráhábù gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan. Àwọn amí náà sọ fún un pé: ‘Gba okùn pupa yìí kí o sì so ó mọ́ ojú fèrèsé rẹ, kó o sì kó gbogbo ẹbí rẹ sínú ilé rẹ pẹ̀lú rẹ. Nígbà tí gbogbo wa bá sì padà wá láti gba Jẹ́ríkò, a máa rí òwú yìí ní ojú fèrèsé rẹ a kì yóò sì pa ẹnikẹ́ni ní ilé rẹ.’ Nígbà tí àwọn amí náà padà dé ọ̀dọ̀ Jóṣúà, wọ́n ro gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un.