Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

 ÌTÀN 11

Òṣùmàrè Àkọ́kọ́

Òṣùmàrè Àkọ́kọ́

ǸJẸ́ o mọ ohun tí Nóà kọ́kọ́ ṣe nígbà tí òun àti ìdílé rẹ̀ jáde kúrò nínú ọkọ̀? Ẹbọ tàbí ọrẹ ló kọ́kọ́ mú wá fún Ọlọ́run. Bó ṣe ṣe é lò ń wò nínú àwòrán tó wà ní ìsàlẹ̀ yìí. Ẹbọ ẹran wọ̀nyí ni Nóà rú láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé Ó gba ìdílé òun là nínú Ìkún-omi ńlá náà.

Ǹjẹ́ o rò pé inú Jèhófà dùn sí ẹbọ náà? Bẹ́ẹ̀ ni, inú rẹ̀ dùn sí i. Ìdí ni pé Ọlọ́run ṣèlérí fún Nóà pé òun ò tún ní fi Ìkún-omi pa ayé rẹ́ mọ́.

Láìpẹ́, omi gbẹ pátápátá kúrò lórí ilẹ̀, Nóà àti ìdílé rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun nígbà tí wọ́n jáde kúrò nínú ọkọ̀ áàkì náà. Ọlọ́run súre fún wọn ó sì wí fún wọn pé: ‘Kẹ́ ẹ bí ọmọ púpọ̀. Kẹ́ ẹ pọ̀ sí i ní iye títí àwọn èèyàn yóò fi kún gbogbo ilẹ̀ ayé.’

Ṣùgbọ́n tó bá yá, tí àwọn èèyàn bá gbọ́ nípa Ìkún-omi ńlá náà, ẹ̀rù lè máa bà wọ́n pé irú Ìkún-omi bẹ́ẹ̀ tún lè ṣẹlẹ̀. Nítorí náà, Ọlọ́run fún wọn ní ohun kan tí yóò máa rán àwọn èèyàn létí ìlérí tí òun ṣe pé òun kò tún ní jẹ́ kí omi kún bo gbogbo ayé mọ́. Ǹjẹ́ o mọ àmì tó fún àwọn èèyàn láti máa rán wọn létí? Òṣùmàrè ni.

Ìgbà tí oòrùn bá yọ lẹ́yìn tí òjò bá ti rọ̀ darí ni òṣùmàrè má ń yọ lójú sánmà. Òṣùmàrè lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọ̀ mèremère. Ṣé ìwọ ti rí ọ̀kan rí? Ṣó o rí èyí tó wà nínú àwòrán yìí?

Ohun tí Ọlọ́run sọ rèé: ‘Mo ṣe ìlérí pé Ìkún-omi kì yóò tún pa gbogbo èèyàn àti ẹran mọ́ láé. Màá fi òṣùmàrè mi sí ojú sánmà. Nígbà tí òṣùmàrè bá sì yọ, màá rí i màá sì rántí ìlérí tí mo ṣe yìí.’

Nítorí náà, nígbà tó o bá rí òṣùmàrè, kí ló yẹ kó o rántí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kó rán ọ létí ìlérí Ọlọ́run pé òun ò tún ní fi Ìkún-omi ńlá pa ayé run mọ́.

Mọ Púpọ̀ Sí I

ILÉ ÌṢỌ́

Ọlọ́run Pa Nóà “Mọ́ Láìséwu Pẹ̀lú Àwọn Méje Mìíràn”

Báwo ni Ọlọ́run ṣe dáàbò bo Nóà àti ìdílé rẹ̀ ní àkókò tó tíì le jù nínú ìtàn ẹ̀dá?