Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

 ÌTÀN 33

Líla Òkun Pupa Kọjá

Líla Òkun Pupa Kọjá

WO OHUN tó ń ṣẹlẹ̀ yìí! Mósè nìyẹn tó na ọ̀pá rẹ̀ sórí Òkun Pupa. Àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ tí nǹkan kan ò ṣe ní bèbè odò yẹn ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ṣùgbọ́n Fáráò àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ti rì sínú òkun. Jẹ́ ká wo bó ṣe ṣẹlẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bá a ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, Fáráò sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n jáde kúrò ní Íjíbítì lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti mú ìyọnu kẹwàá wá sórí àwọn ará Íjíbítì. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600,000] ọkùnrin ló lọ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin àti ọmọdé. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn mìíràn tí wọ́n ti gba Jèhófà gbọ́, bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde lọ. Gbogbo wọ́n kó àgùntàn àti ewúrẹ́ àti màlúù wọn lọ pẹ̀lú wọn.

Kí wọ́n tó lọ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tọrọ ẹ̀wù àti àwọn nǹkan tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì. Ẹ̀rù ba àwọn ará Íjíbítì gidigidi nítorí ìyọnu ìkẹyìn tó dé bá wọn yẹn. Nítorí náà, gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì béèrè ni wọ́n fún wọn.

Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé etí Òkun Pupa. Wọ́n sinmi níbẹ̀. Ní àkókò yìí, Fáráò àti àwọn èèyàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kábàámọ̀ pé àwọn jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. Wọ́n wí pé: ‘A ti jẹ́ kí àwọn ẹrú wa lọ!’

Nítorí náà, Fáráò tún yí ọkàn rẹ̀ padà. Kíá ló ti ṣètò ẹṣin ogun rẹ̀ àti ẹgbẹ́ ogun rẹ̀. Ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] kẹ̀kẹ́ ogun àkànṣe, àti gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yòókù ní Íjíbítì.

Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí Fáráò àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tó ń lé wọn bọ̀, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Kò síbi tí wọ́n máa sá gbà. Òkun Pupa wà ní iwájú, àwọn ará Íjíbítì sì ń lé wọn bọ̀ lẹyìn. Ṣùgbọ́n Jèhófà fi ìkùukùu sáàárín àwọn èèyàn rẹ̀ àti àwọn ará Íjíbítì. Nítorí náà, àwọn ará Íjíbítì ò lè kọ lu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítorí pé wọn ò rí wọn.

Jèhófà wá sọ fún Mósè pé kó na ọ̀pá rẹ̀ sórí Òkun Pupa. Nígbà tó ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà mú kí afẹ́fẹ́ líle fẹ́ wá láti ìlà oòrùn. Omi òkun náà pín sí méjì, omi náà sì dúró bíi bèbè sí apá ọ̀tún àti apá òsì.

Ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá bẹ̀rẹ̀ sí í rìn lórí ilẹ̀ gbígbẹ la òkun náà kọjá. Ó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn náà àti gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn tó la òkun náà kọjá sí òdìkejì. Níkẹyìn, ó ṣeé ṣe fún àwọn ará Íjíbítì láti tún rí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àwọn ẹrú wọn ló mà ń lọ mọ́ wọn lọ́wọ́ yìí! Bí wọ́n ṣe rọ́ wọnú òkun láti lépa wọn nìyẹn.

Nígbà tí wọ́n rọ́ wọnú òkun tán, Ọlọ́run mú kí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn máa fò yọ. Ẹ̀rù wá ba àwọn ará Íjíbítì gan-an débi tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: ‘Jèhófà ló ń bá wa jà nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹ jẹ́ ká sá jáde kúrò níhìn-ín!’ Ṣùgbọ́n ó ti pẹ́ jù.

Ìgbà yìí ni Jèhófà sọ fún Mósè pé kó na ọ̀pá rẹ̀ sórí Òkun Pupa, gẹ́gẹ́ bí o ti rí i nínú àwòrán yìí. Nígbà tí Mósè sì ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn omi tó dà bí ògiri náà bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ padà bo àwọn ará Íjíbítì àti kẹ̀kẹ́ wọn mọ́lẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun náà pátá ló lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọnú òkun. Kò sì sí ọ̀kan nínú wọn tó yè!

Wo bí inú gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run ti dùn tó pé àwọn yè bọ́! Àwọn ọkùnrin kọ orin ọpẹ́ sí Jèhófà pé: ‘Jèhófà ti ja àjàṣẹ́gun ológo. Ó sì da àwọn ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin wọn sínú òkun.’ Míríámù arábìnrin Mósè mú ohun èèlò ìkọrin rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin sì bá a gbé orin pẹ̀lú ohun èèlò ìkọrin tiwọn. Bí wọ́n sì ti ń fi ayọ̀ jó, wọ́n kọ orin kan náà tí àwọn ọkùnrin ń kọ pé: ‘Jèhófà ti ja àjàṣẹ́gun ológo. Ó ti da àwọn ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin wọn sínú òkun.’