WO MÓSÈ bó ṣe ń sá lọ kúrò ní Íjíbítì. Ǹjẹ́ o ráwọn tó ń lé e? Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí wọ́n fẹ́ fi pa Mósè? Jẹ́ ká wò ó bóyá a lè mọ̀ ọ́n.

Ilé Fáráò, alákòóso Íjíbítì ni Mósè dàgbà sí. Ó di ọlọ́gbọ́n èèyàn àti ẹni ńlá. Mósè mọ̀ pé òun kì í ṣe ará Íjíbítì. Ó mọ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹrú ni òbí òun gan-an.

Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Mósè pé ọmọ ogójì [40] ọdún, ó pinnu láti lọ wo bí nǹkan ṣe ń lọ sí fáwọn èèyàn rẹ̀. Ọ̀nà tí wọ́n gbà ń lò wọ́n ò dáa rárá. Ó rí ará Íjíbítì kan tó ń lu ọmọ Ísírẹ́lì ẹrú kan. Mósè wò ọ̀tún, ó wo òsì, nígbà tó rí i pé kò sẹ́nì kankan tó ń wò òun, ó lu ará Íjíbítì náà, ará Íjíbítì náà sì kú. Mósè wá kó erùpẹ̀ bo òkú rẹ̀.

Ní ọjọ́ kejì, Mósè tún jáde lọ wo àwọn èèyàn rẹ̀. Ó rò pé òun lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa jẹ́ ẹrú mọ́. Ṣùgbọ́n ó rí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì tó ń bá ara wọn jà. Ni Mósè bá sọ fún ẹni tó jẹ̀bi pé: ‘Kí ló dé tó o fi ń lu arákùnrin ẹ?’

Ọkùnrin náà bá fèsì pé: ‘Ta ló fi ọ́ ṣe alákòóso àti onídàájọ́ wa? Ṣó o fẹ́ pa mí bó o ṣe pa ará Íjíbítì yẹn ni?’

Ẹ̀rù wá ba Mósè wàyí. Ó rí i pé àwọn èèyàn ti mọ ohun tí òun ṣe fún ará Íjíbítì yẹn. Kódà Fáráò pàápàá ti gbọ́ nípa ẹ̀, ó sì ti rán àwọn èèyàn pé kí wọ́n lọ pa Mósè. Ìdí rẹ̀ nìyí tí Mósè fi ní láti sá kúrò ní Íjíbítì.

Nígbà tí Mósè kúrò ní Íjíbítì, ilẹ̀ Mídíánì tó jìnnà réré ló lọ. Ibẹ̀ ló ti ṣe alábàápàdé ìdílé Jẹ́tírò, ó sì gbé ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Jẹ́tírò tó ń jẹ́ Sípórà níyàwó. Mósè di olùṣọ́ àgùntàn, ó sì ń tọ́jú agbo àgùntàn Jẹ́tírò. Ó gbé ní ilẹ̀ àwọn ará Mídíánì fún ogójì [40] ọdún. Ó ti di ẹni ọgọ́rin [80] ọdún báyìí. Nígbà tó yá, lọ́jọ́ kan, tí Mósè ń tọ́jú agbo àgùntàn Jẹ́tírò, ohun ìyanu kan ṣẹlẹ̀ tó yí ìgbésí ayé Mósè padà. Ṣí ìwé yìí sí ojú ìwé tó kàn, kó o sì jẹ́ ká wo ohun ìyanu yìí.