Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

 ÌTÀN 21

Àwọn Ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù Kórìíra Rẹ̀

Àwọn Ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù Kórìíra Rẹ̀

WO BÍ inú ọmọkùnrin yìí ṣe bà jẹ́ tó tí kò sì nírètí kankan mọ́! Jósẹ́fù lò ń wò yẹn. Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ tà á fáwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí wọ́n ń lọ sí Íjíbítì ni. Ẹrú ni Jósẹ́fù máa dà tó bá dé ọ̀hún. Kí nìdí táwọn ọmọ bàbá rẹ̀ fi hùwà búburú yìí? Torí pé wọ́n ń jowú Jósẹ́fù ni.

Jékọ́bù bàbá wọn fẹ́ràn Jósẹ́fù gan-an. Ó ṣe ojú rere sí i nípa dídá ẹ̀wù àwọ̀lékè aláràbarà kan fún un. Nígbà táwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin mẹ́wàá rí bí bàbá wọn ṣe fẹ́ràn rẹ̀ tó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jowú rẹ̀ wọ́n sì ń kórìíra rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ìdí mìíràn tún wà tí wọ́n fi kórìíra rẹ̀.

Jósẹ́fù lá àlá méjì kan. Nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àlá náà, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ forí balẹ̀ fún un. Nígbà tí Jósẹ́fù rọ́ àlá wọ̀nyí fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ṣe ni ìkórìíra wọn túbọ̀ pọ̀ sí i.

Lọ́jọ́ kan, nígbà táwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ń tọ́jú agbo àgùntàn bàbá wọn, Jékọ́bù sọ fún Jósẹ́fù pé kó lọ wo àlàáfíà wọn. Báwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ṣe rí i tó ń bọ̀ lọ́ọ̀ọ́kán báyìí, àwọn kan nínú wọn wí pé: ‘Ẹ jẹ́ ká pa á!’ Ṣùgbọ́n Rúbẹ́nì tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n gbogbo wọn wí pé: ‘Rárá, ẹ máà jẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀!’ Dípò kí wọ́n pa á, wọ́n gbá Jósẹ́fù mú, wọ́n sì jù ú sínú ihò kan tí kò sí omi nínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n jókòó láti pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe fún un.

Ibi tí wọ́n ti ń ro èyí lọ́wọ́ ni àwọn ará Íṣímáẹ́lì kan ti yọ lọ́ọ̀ọ́kán. Júdà sọ fun àwọn ọmọ bàbá rẹ̀ pé: ‘Ẹ jẹ́ ká tà á fún àwọn ará Íṣímáẹ́lì.’ Ohun tí wọ́n sì ṣe gan-an nìyẹn. Wọ́n ta Jósẹ́fù ní ogún [20] owó fàdákà. O ò rí i pé ìwà ìkà àti ìwà àìláàánú nìyẹn!

Kí wá ni wọ́n máa sọ fún bàbá wọn? Wọ́n dá ọgbọ́n, wọ́n pa ewúrẹ́ kan, wọ́n sì fi ẹ̀wù àwọ̀lékè dáradára tí wọ́n bọ́ lọ́rùn Jósẹ́fù yí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà. Wọ́n wá mú ẹ̀wù náà lọ fún Jékọ́bù bàbá wọn ní ilé, wọ́n sì wí pé: ‘A rí èyí lójú ọ̀nà. Ẹ wò ó, kó má lọ jẹ́ pé ẹ̀wù Jósẹ́fù ni.’

Jékọ́bù rí i pé ẹ̀wù Jósẹ́fù ni. Ó kígbe pé ‘Ó ní láti jẹ́ pé ẹranko búburú kan ti pa Jósẹ́fù jẹ.’ Ohun tí àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù sì fẹ́ kí bàbá wọn rò nìyẹn. Inú Jékọ́bù bà jẹ́ gidigidi. Ó sunkún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́. Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù ò kú o. Jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i níbi tí wọ́n mú un lọ.