ǸJẸ́ o mọ àwọn tí Jékọ́bù ń bá sọ̀rọ̀ yìí? Lẹ́yìn tí Jékọ́bù ti rin ìrìn àjò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, ó pàdé àwọn èèyàn wọ̀nyí lẹ́bàá kànga kan. Wọ́n ń tọ́jú àgùntàn wọn. Jékọ́bù béèrè lọ́wọ́ wọn pé: ‘Ibo lẹ ti wá?’

Wọ́n dáhùn pé: ‘Ìlú Háránì ni.’

Jékọ́bù béèrè pé: ‘Ǹjẹ́ ẹ mọ Lábánì?’

Wọ́n dáhùn pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni. Wò ó, Rákélì, ọmọbìnrin rẹ̀, ló ń da agbo àgùntàn bàbá rẹ̀ bọ̀ yìí.’ Ṣé o rí Rákélì tó ń bọ̀ lọ́ọ̀ọ́kán?

Nígbà tí Jékọ́bù rí Rákélì pẹ̀lú àwọn àgùntàn Lábánì ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, ó lọ yí òkúta kúrò lẹ́nu kànga kí àwọn àgùntàn náà lè mu omi. Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù fẹnu ko Rákélì lẹ́nu ó sì sọ ẹni tí òun jẹ́ fún un. Inú Rákélì dùn gidigidi, ó sáré lọ sí ilé ó sì sọ fún Lábánì bàbá rẹ̀.

Inú Lábánì dùn sí i pé kí Jékọ́bù máa bá òun gbé. Nígbà tí Jékọ́bù sọ pé òun fẹ́ fẹ́ Rákélì, inú Lábánì dùn gan-an. Ṣùgbọ́n, ó sọ pé kí Jékọ́bù ṣiṣẹ́ nínú oko òun fún ọdún méje kó tó lè fẹ́ Rákélì. Jékọ́bù gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó fẹ́ràn Rákélì gan-an. Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò ìgbéyàwó tó, ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀?

Ṣe ni Lábánì fi Léà ọmọbìnrin rẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Jékọ́bù dípò Rákélì. Nígbà tí Jékọ́bù gbà láti ṣiṣẹ́ sin Lábánì fún ọdún méje mìíràn sí i, Lábánì tún fún un ní Rákélì láti fi ṣe aya. Ní ìgbà yẹn lọ́hùn-ún, Ọlọ́run gbà káwọn ọkùnrin máa ní ju ìyàwó kan lọ. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe fi hàn, ìyàwó kan ṣoṣo ni ọkùnrin kan gbọ́dọ̀ ní.