LỌ́Ọ̀TÌ àti ìdílé rẹ̀ ń gbé pa pọ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù ní ilẹ̀ Kénáánì. Lọ́jọ́ kan Ábúráhámù sọ fún Lọ́ọ̀tì pé: ‘Ilẹ̀ yìí kò gba gbogbo ẹran wa mọ́. Jọ̀wọ́, jẹ́ ká pínyà. Bí ìwọ bá gba apá ọ̀tún lọ, èmi á forí lé apá òsì.’

Lọ́ọ̀tì bojú wo gbogbo ilẹ̀ náà. Ó rí apá ibi tó dára púpọ̀, tó ní omi àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ koríko tútù fún àwọn ẹran ẹ̀. Àgbègbè Jọ́dánì ni ibẹ̀. Nítorí náà, Lọ́ọ̀tì kó ìdílé ẹ̀ àtàwọn ẹran ẹ̀ lọ síbẹ̀. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n sọ ìlú Sódómù di ilé wọn.

Àwọn èèyàn ìlú Sódómù burú gan-an. Èyí ò dùn mọ́ Lọ́ọ̀tì nínú rárá nítorí pé ẹni rere ni. Inú Ọlọ́run pẹ̀lú ò dùn sí ohun táwọn ará ìlú yẹn ń ṣe. Nígbà tó yá, Ọlọ́run rán áńgẹ́lì méjì láti lọ kìlọ̀ fún Lọ́ọ̀tì pé òun á pa Sódómù àti ìlú Gòmórà tó wà nítòsí ẹ̀ run nítorí ìwà búburú wọn.

Àwọn áńgẹ́lì náà sọ fún Lọ́ọ̀tì pé: ‘Ṣe kíá! Mú ìyàwó rẹ àtàwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì jáde kúrò níhìn-ín!’ Nígbà tí Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ ò tètè fẹ́ jáde, àwọn áńgẹ́lì náà di ọwọ́ wọn mú wọ́n sì mú wọn jáde kúrò ní ìlú náà. Ni ọ̀kan nínú àwọn áńgẹ́lì náà bá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí yín! Ẹ má ṣe bojú wẹ̀yìn. Ẹ sá lọ sórí àwọn òkè, kẹ́ ẹ má bàa kú.’

Lọ́ọ̀tì àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ṣe ìgbọràn, wọ́n sá jáde kúrò ní Sódómù. Wọn ò dúró fún ìṣẹ́jú kan, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò bojú wẹ̀yìn. Ṣùgbọ́n ìyàwó Lọ́ọ̀tì ṣàìgbọràn. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn díẹ̀ kúrò ní Sódómù, ìyàwó Lọ́ọ̀tì dúró, ó sì bojú wẹ̀yìn. Ló bá di ọwọ̀n iyọ̀. Ṣó o rí i nínú àwòrán yìí?

A lè rí ẹ̀kọ́ gidi kọ́ nínú èyí. Ó fi hàn wá pé Ọlọ́run máa ń gba àwọn tó bá gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu là, ṣùgbọ́n àwọn tó bá ṣàìgbọràn sí i yóò pàdánù ẹ̀mí wọn.