Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÌTÀN 32

Àwọn Ìyọnu Mẹ́wàá

Àwọn Ìyọnu Mẹ́wàá

WO ÀWÒRÁN wọ̀nyí. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn fi ìyọnu tí Jèhófà mú wá sórí Íjíbítì hàn. Nínú àwòrán àkọ́kọ́, bí Áárónì ṣe fi ọ̀pá rẹ̀ lu Odò Náílì lò ń wò yẹn. Nígbà tó ṣe bẹ́ẹ̀, omi odò náà di ẹ̀jẹ̀. Àwọn ẹja ibẹ̀ kú, odò náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í rùn.

Lẹ́yìn náà, Jèhófà mú káwọn àkèré jáde láti inú Odò Náílì. Kò sí ibi tí wọn ò kó wọ̀ tán—wọ́n kó wọnú ààrò, inú agolo tí wọ́n fi ń ṣe búrẹ́dì, orí ibi táwọn èèyàn ń sùn—ibi gbogbo ni wọ́n wà. Nígbà táwọn àkèré náà kú, àwọn ará Íjíbítì kó wọn jọ pelemọ-pelemọ káàkiri, gbogbo ilẹ̀ náà sì ń rùn.

Lẹ́yìn èyí, Áárónì fi ọ̀pá rẹ̀ lu ilẹ̀, ekuru ilẹ̀ sì yí padà di kòkòrò kantíkantí. Àwọn kantíkantí wọ̀nyí jẹ́ kòkòrò kéékèèké tó ń fò tó sì máa ń jáni jẹ. Kòkòrò kantíkantí ni ìyọnu kẹta tó wá sórí ilẹ̀ Íjíbítì.

Àwọn ará Íjíbítì nìkan ni àwọn ìyọnu tó kù dà láàmú, kò kan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àwọn eṣinṣin ńlá tó ṣù bo ilé gbogbo àwọn ará Íjíbítì ni ìyọnu kẹrin. Ìyọnu karùn-ún wá sórí àwọn ẹranko. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ àwọn ará Íjíbítì ló kú.

Lẹ́yìn èyí, Mósè àti Áárónì bu eérú díẹ̀ wọ́n sì dà á sínú afẹ́fẹ́. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í dá egbò kíkẹ̀ sára àwọn èèyàn àti ẹranko. Èyí ni ìyọnu kẹfà.

Lẹ́yìn èyí, Mósè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ọ̀run, Jèhófà sì rán ààrá àti òjò yìnyín sí ilẹ̀. Òun ni òjò yìnyín tó burú jù lọ tí Íjíbítì tíì rí rí.

Àwọn eéṣú tó bo ilẹ̀ ni ìyọnu kẹjọ. Kò tíì sí ìgbà tí eéṣú pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí ṣáájú àkókò yẹn kò sì tún sírú rẹ̀ láti ìgbà yẹn. Gbogbo ohun tó kù tí òjò yìnyín kò pa run ni wọ́n jẹ.

Òkùnkùn biribiri ni ìyọnu kẹsàn-án. Odindi ọjọ́ mẹ́ta ni òkùnkùn biribiri fi bo ilẹ̀, ṣùgbọ́n ìmọ́lẹ̀ wà ní ibi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé.

Níkẹyìn, Ọlọ́run sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n fi ẹ̀jẹ̀ ọmọ ewúrẹ́ tàbí ti ọmọ àgùntàn wọ́n ara òpó ilẹ̀kùn àbáwọlé wọn. Ìgbà náà ni áńgẹ́lì Ọlọ́run la Íjíbítì kọjá. Bí áńgẹ́lì náà bá ti rí ẹ̀jẹ̀, kò ní pa ẹnì kankan nínú ilé yẹn. Ṣùgbọ́n inú gbogbo ilé tí kò bá sí ẹ̀jẹ̀ ní ara òpó ilẹ̀kùn àbáwọlé wọn ni áńgẹ́lì Ọlọ́run ti pa gbogbo àkọ́bí èèyàn àti àkọ́bí ẹran ọ̀sìn tó bá wà níbẹ̀. Èyí ni ìyọnu kẹwàá.

Lẹ́yìn ìyọnu tó kẹ́yìn yìí, Fáráò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa lọ. Gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run ti ṣe tán láti lọ, òru ọjọ́ náà gan-an ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn wọn jáde kúrò ní Íjíbítì.