Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÌTÀN 23

Àwọn Àlá Fáráò

Àwọn Àlá Fáráò

ỌDÚN méjì kọjá, Jósẹ́fù ṣì wà lẹ́wọ̀n. Agbọ́tí náà ò rántí Jósẹ́fù mọ́. Ní òru ọjọ́ kan, Fáráò lá àlá méjì kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó sì fẹ́ mọ ohun tí wọ́n túmọ̀ sí. Ṣó o rí i bó ṣe sùn nínú àwòrán yìí? Ní ọjọ́ kejì, Fáráò pe àwọn amòye rẹ̀ ó sì rọ́ àlá rẹ̀ fún wọn. Ṣùgbọ́n wọn ò lè sọ ìtumọ̀ àwọn àlá náà fún un.

Ìgbà yìí gan-an ni agbọ́tí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rántí Jósẹ́fù. Ó sọ fún Fáráò pé: ‘Nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n ọkùnrin kan wà níbẹ̀ tó máa ń sọ ìtumọ̀ àlá.’ Fáráò pàṣẹ pé kí wọ́n mú Jósẹ́fù jáde wá láti inú ẹ̀wọ̀n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Fáráò rọ́ àlá rẹ̀ fún Jósẹ́fù báyìí pé: ‘Mo rí màlúù méje tó sanra tó sì lẹ́wà. Ẹ̀yìn ìgbà náà ni mo tún rí màlúù méje mìíràn tó rù kan eegun. Àwọn màlúù tó rù náà sì gbé àwọn màlúù tó sanra mì.

‘Nínú àlá mi kejì mo rí ṣírí ọkà méje tó jáde lára igi ọkà kan; ọkà pọ̀ lára rẹ̀ dáadáa, ó sì dára. Ẹ̀yìn ìgbà náà ni mo tún rí ṣírí ọkà méje tó gbẹ, tó sì tín-ín-rín. Àwọn ṣírí ọkà tó tín-ín-rín náà sì gbé àwọn ṣírí ọkà tó sanra mì.’

Jósẹ́fù sọ fún Fáráò pé: ‘Ìtumọ̀ kan náà ni àlá méjèèjì ní. Àwọn màlúù méje sísanra àti àwọn ṣírí ọkà dídára túmọ̀ sí ọdún méje, àwọn màlúù méje tó rù àti àwọn ṣírí ọkà méje tó tín-ín-rín pẹ̀lú túmọ̀ sí ọdún méje mìíràn. Ọdún méje ni ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ yóò fi wà ní Íjíbítì. Lẹ́yìn náà, ọdún méje mìíràn yóò wà tí oúnjẹ tó máa hù kò ní tó.’

Nítorí náà, Jósẹ́fù sọ fún Fáráò pé: ‘Yan ọkùnrin ọlọgbọ́n kan kí o sì fi í ṣe olórí fún kíkó oúnjẹ jọ nígbà ọdún méje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ á fi wà. Nípa báyìí, ebi ò ní pa àwọn èèyàn kú ní ọdún méje ìyàn tí yóò tẹ̀ lé e nígbà tí oúnjẹ kò ní hù púpọ̀.’

Èrò náà dára lójú Fáráò. Ó yan Jósẹ́fù pé kó máa kó oúnjẹ jọ, kó sì máa tọ́jú rẹ̀. Jósẹ́fù di èèyàn ńlá ní Íjíbítì. Tá a bá yọwọ́ Fáráò, Jósẹ́fù ló tún ṣe pàtàkì jù lọ.

Lọ́dún mẹ́jọ lẹ́yìn náà, ní àkókò ìyàn, Jósẹ́fù ráwọn ọkùnrin kan tí wọ́n ń bọ̀. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí wọ́n jẹ́? O jẹ́ mọ̀ pé àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mẹ́wàá ni! Jékọ́bù bàbá wọn ló rán wọn wá sí Íjíbítì nítorí kò sí oúnjẹ fún wọn mọ́ ní ìlú wọn ní Kénáánì. Jósẹ́fù dá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mọ̀, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kò dá a mọ̀. Ǹjẹ́ o mọ ìdí rẹ̀? Ìdí ni pé, Jósẹ́fù ti dàgbà, ó sì wọ aṣọ tó yàtọ̀.

Jósẹ́fù rántí pé nígbà tí òun wà lọ́mọdé òun lá àlá pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun wá láti forí balẹ̀ fún òun. Ǹjẹ́ o rántí pé o ti kà nípa èyí? Nítorí náà, Jósẹ́fù rí i pé Ọlọ́run ni ẹni tó rán òun wá sí Íjíbítì, fún ìdí rere sì ni. Kí lo rò pé Jósẹ́fù ṣe? Jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀.