Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

 ÌTÀN 8

Àwọn Òmìrán ní Ayé

Àwọn Òmìrán ní Ayé

KÁ SỌ pé ẹnì kan ń rìn bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, tí ẹni náà sì ga débi pé orí rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ lè máa kan àjà ilé yín, kí lo máa rò nípa ẹni náà? Dájúdájú, èrò tó máa wá sọ́kàn rẹ ni pé, ẹni náà ní láti jẹ́ òmìrán! Ìgbà kan wà tí àwọn òmìrán wà láyé lóòọ́tọ́. Bíbélì sọ pé àwọn áńgẹ́lì tó wá láti ọ̀run ni bàbá wọn. Àmọ́, báwo ló ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?

Má gbàgbé pé Sátánì, áńgẹ́lì búburú yẹn, kò jáwọ́ nínú dídá wàhálà sílẹ̀. Ó tiẹ̀ ń gbìyànjú láti mú kí àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run dẹni búburú. Nígbà tó sì yá, díẹ̀ nínú àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ti Sátánì. Wọ́n ṣíwọ́ iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn lọ́run. Wọ́n sì sọ̀ kalẹ̀ wá sáyé, wọ́n da àwọ̀ èèyàn bora. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fà á?

Bíbélì sọ pé ohun tó fà á ni pé àwọn ọmọ Ọlọ́run wọ̀nyí rí àwọn arẹwà obìnrin lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì fẹ́ láti máa bá wọn gbé. Ni wọ́n bá wá sí ayé, wọ́n sì gbé àwọn obìnrin wọ̀nyí níyàwó. Bíbélì sọ pé ohun tí wọ́n ṣe yìí kò tọ̀nà, torí ọ̀run ni Ọlọ́run dá àwọn áńgẹ́lì sí láti máa gbé.

Nígbà tí àwọn áńgẹ́lì náà àti àwọn aya wọn bí ọmọ, àwọn ọmọ wọ̀nyí yàtọ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, ó ṣeé ṣe kó dà bíi pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ lójú. Ṣùgbọ́n, ńṣe ni wọ́n ń tóbi sí i, tí wọ́n sì ń lágbára sí i, títí wọ́n fi di òmìrán.

Àwọn òmìrán wọ̀nyí burú. Nítorí pé wọ́n tóbi, wọ́n sì lágbára gan-an, wọ́n máa ń ṣe àwọn èèyàn léṣe. Wọ́n gbìyànjú láti fi ipá mú gbogbo èèyàn láti dẹni búburú bíi tiwọn.

Énọ́kù ti kú, ṣùgbọ́n ẹnì kan ṣì wà láyé tó jẹ́ ẹni rere. Nóà ni orúkọ ẹni náà. Ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ló máa ń ṣe nígbà gbogbo.

Ní ọjọ́ kan Ọlọ́run sọ fún Nóà pé àkókò tó tí Òun máa pa gbogbo àwọn èèyàn búburú run. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ pé òun máa gba Nóà àti ìdílé rẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹranko là. Jẹ́ ká wo bí Ọlọ́run ṣe gbà wọ́n là.