Ọ̀DỌ̀ Ọlọ́run ni gbogbo nǹkan rere tá a ní ti wá. Ó dá oòrùn láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ lọ́sàn-án, ó tún dá òṣùpá àti ìràwọ̀ ká lè ní ìmọ́lẹ̀ díẹ̀ ní òru. Ó sì dá ilẹ̀ ayé ká lè máa gbé ibẹ̀.

Àmọ́ kì í ṣe oòrùn, òṣùpá, ìràwọ̀ àti ilẹ̀ ayé ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá o. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá? Ó kọ́kọ́ dá àwọn ẹ̀dá tó dà bí òun fúnra rẹ̀. A ò lè rí àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bá ò ṣe lè rí Ọlọ́run. Bíbélì pe àwọn ẹ̀dá náà ní Áńgẹ́lì. Ọlọ́run dá wọn pé kí wọ́n máa bá òun gbé ní ọ̀run.

Áńgẹ́lì tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá yàtọ̀ pátápátá sí àwọn tó kù. Òun ni àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run, ó sì bá Bàbá rẹ̀ ṣiṣẹ́. Ó ran Ọlọ́run lọ́wọ́ láti dá gbogbo nǹkan mìíràn. Ó ran Ọlọ́run lọ́wọ́ láti dá oòrùn, òṣùpá, ìràwọ̀ àti ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.

Báwo ni ilẹ̀ ayé ṣe rí nígbà náà? Ní ìbẹ̀rẹ̀, kò sí ibi téèyàn lè gbé lórí ilẹ̀ ayé. Kìkì alagbalúgbú omi òkun ńlá kan ló wà tó bo gbogbo ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn máa gbé lórí ilẹ̀ ayé. Fún ìdí yìí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò àwọn nǹkan sílẹ̀ fún wa. Kí ló ṣe?

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Ọlọ́run rí i pé ilẹ̀ ayé nílò ìmọ́lẹ̀. Nítorí náà, Ó mú kí ìmọ́lẹ̀ oòrùn tàn sórí ilẹ̀ ayé. Ó mú kí òru àti ọ̀sán wà. Lẹ́yìn náà, Ó mú kí ilẹ̀ yọ jáde látinú omi òkun.

Lákọ̀ọ́kọ́, kò sí ohunkóhun lórí ilẹ̀. Ńṣe ló dà bí àwòrán tó ò ń wò lójú ìwé yìí. Kò sí òdòdó tàbí igi tàbí ẹranko kankan. Kò tiẹ̀ sí ẹja kankan nínú omi òkun pàápàá. Iṣẹ́ ṣì pọ̀ gan-an tí Ọlọ́run máa ṣe láti mú kí ilẹ̀ ayé ṣeé gbé fáwọn ẹranko àti èèyàn.