NÍ ÒDE ọgbà Édẹ́nì, Ádámù àti Éfà ní ọ̀pọ̀ ìṣòro. Wọ́n ní láti ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n tó rí oúnjẹ jẹ. Dípò àwọn èso igi tó dára, ọ̀pọ̀ ẹ̀gún òun òṣùṣú tó ń hù ni wọ́n ń rí ní àyíká wọn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyí nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run tí wọn kò sì jẹ́ ọ̀rẹ́ Rẹ̀ mọ́.

Ṣùgbọ́n, èyí tó tiẹ̀ tún burú jùyẹn lọ ni pé, Ádámù àti Éfà bẹ̀rẹ̀ sí í kú. Ṣó o rántí pé Ọlọ́run kìlọ̀ fún wọn pé bí wọ́n bá jẹ nínú èso igi kan báyìí, wọn á kú. Bí Ọlọ́run ṣe sọ, ọjọ́ tí wọ́n jẹ ẹ́ gan-an ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í kú. O ò rí i pé ìwà òmùgọ̀ ni wọ́n hù bí wọ́n ṣe ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run!

Ẹ̀yìn tí Ọlọ́run lé Ádámù àti Éfà jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì ni wọ́n tó bí gbogbo ọmọ wọn. Èyí túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ náà pẹ̀lú ní láti dàgbà di arúgbó kí wọ́n sì kú.

Ká ní Ádámù àti Éfà ti gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu ni, ìgbésí ayé ì bá dùn bí oyin fún àwọn àtàwọn ọmọ wọn. Gbogbo wọn ni ì bá wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé tí wọn ì bá sì ní ayọ̀. Kò sí ẹnì tí ì bá di arúgbó, kò sí ẹni tí ì bá ṣàìsàn kó sì kú.

Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn wà láàyè títí láé kí wọ́n sì máa yọ̀, Ó sì ṣèlérí pé ní ọjọ́ kan èyí yóò rí bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ sí pé gbogbo ilẹ̀ ayé á jẹ́ ibi ẹlẹ́wà, ẹnì kankan ò ní ṣàìsàn mọ́. Gbogbo àwọn tó wà lórí ilẹ̀ ayé á jẹ́ ọ̀rẹ́ rere sí ara wọn, wọn á tún jẹ́ ọ̀rẹ́ rere sí Ọlọ́run.

Ṣùgbọ́n Éfà kì í tún ṣe ọ̀rẹ́ Ọlọ́run mọ́. Nítorí náà, nígbà tó bí àwọn ọmọ rẹ̀, kò rọrùn fún un. Ó ní ìrora. Àìgbọràn tó ṣe sí Jèhófà mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbànújẹ́ bá a, àbí ìwọ ò gbà bẹ́ẹ̀?

Ádámù àti Éfà bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Nígbà tí wọ́n bí ọmọ wọn kìíní, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Kéènì. Wọ́n pe orúkọ ọmọ wọn kejì ní Ébẹ́lì. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ náà? Ǹjẹ́ o mọ̀ ọ́n?