Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ìtàn Bíbélì

 ÌTÀN 7

Ọkùnrin Onígboyà

Ọkùnrin Onígboyà

BÍ ÀWỌN èèyàn ṣe ń pọ̀ sí i láyé, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló ń ṣe ohun búburú bíi ti Kéènì. Ṣùgbọ́n ti ọkùnrin kan báyìí yàtọ̀. Orúkọ ọkùnrin náà ni Énọ́kù. Ó jẹ́ onígboyà. Gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ ló ń hùwà búburú, àmọ́ òun ò ṣíwọ́ sísin Ọlọ́run.

Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí àwọn èèyàn ayé ìgbà yẹn fi ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan búburú bẹ́ẹ̀? Ó dára, ṣó o rántí, Ta ló mú kí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run tí wọ́n sì jẹ èso tí Ọlọ́run sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ? Áńgẹ́lì búburú kan ni, àbí? Bíbélì pe áńgẹ́lì náà ní Sátánì. Sátánì ń gbìyànjú láti sọ gbogbo èèyàn dẹni búburú.

Ní ọjọ́ kan Jèhófà Ọlọ́run rán Énọ́kù pé kó lọ sọ ohun táwọn èèyàn ò fẹ́ gbọ́ fún wọn. Ohun tí Ọlọ́run ní kó sọ ni pé: ‘Ní ọjọ́ kan, Ọlọ́run yóò pa gbogbo àwọn èèyàn búburú run.’ Ó ṣeé ṣe kí inú ti bí àwọn èèyàn gidigidi nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí. Bóyá wọ́n tiẹ̀ gbìyànjú láti pa Énọ́kù pàápàá. Nítorí náà, Énọ́kù ní láti nígboyà gan-an kó tó lè sọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fáwọn èèyàn náà.

Ọlọ́run ò jẹ́ kí Énọ́kù pẹ́ láàárín àwọn èèyàn búburú wọ̀nyẹn. Ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ ló lò láyé, èyí sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta, ọgọ́ta ó lé márùn-ún [365] ọdún. Kí nìdí tá a fi sọ pé ìwọ̀nba díẹ̀ ni iye ọdún tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ẹ̀mí àwọn èèyàn ayé ọjọ́un máa ń gùn ju ti àwa èèyàn òde òní lọ nítorí pé ara wọ́n dá ṣáṣá ju tiwa lọ. Àní, Mètúsélà ọmọ Énọ́kù lo ẹgbẹ̀rún dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n [969] ọdún láyé!

Lẹ́nu kan ṣá, lẹ́yìn tí Énọ́kù kú, ńṣe làwọn èèyàn náà túbọ̀ ń burú sí i. Bíbélì sọ pé ‘gbogbo èrò wọn kìkì ibi ni lójoojúmọ́,’ àti pé ‘ayé kún fún ìjàngbọ̀n.’

Ǹjẹ́ o mọ ọ̀kan nínú àwọn ìdí tí wàhálà fi pọ̀ láyé tó bẹ́ẹ̀ láyé ìgbà yẹn? Ó jẹ́ nítorí pé Sátánì mọ ọ̀nà tuntun kan tó fi ń mú káwọn èèyàn ṣe ohun búburú.  Ìtàn yìí la ó sọ tẹ̀ lé e.