KÍ NI àwòrán yìí fi yàtọ̀ sí àwòrán ìtàn tá a kà kọjá? Àwọn èèyàn tó wà nínú rẹ̀ ni. Àwọn ni ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́. Ta ló dá wọn? Ọlọ́run ni. Ǹjẹ́ o mọ orúkọ Ọlọ́run tó dá wọn? Jèhófà ni. Orúkọ ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ náà sì ni Ádámù àti Éfà.

Bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe dá Ádámù nìyí. Ó bu erùpẹ̀ díẹ̀ látinú ilẹ̀, ó sì fi mọ ara èèyàn pípé kan tó jẹ́ ọkùnrin. Ó wá mí sí ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà tí í ṣe Ádámù sì di alààyè.

Jèhófà Ọlọ́run gbé iṣẹ́ kan fún Ádámù. Ó sọ fún Ádámù pé kó sọ gbogbo ẹranko ní orúkọ. Ádámù ti ní láti kíyè sí àwọn ẹranko wọ̀nyí fún àkókò tó gùn kó tó lè sọ orúkọ tó yẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Nígbà tí Ádámù ń sọ àwọn ẹranko náà lórúkọ, ó ṣàkíyèsí nǹkan kan. Ǹjẹ́ o mọ nǹkan náà?

Gbogbo àwọn ẹranko ló ní akọ àti abo. Bàbá erin àti ìyá erin wà, bàbá kìnnìún àti ìyá kìnnìún sì wà pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n Ádámù ò lẹ́nì kankan tó máa jẹ́ ẹnì kejì rẹ̀. Nítorí náà, Jèhófà mú kí Ádámù sun oorun àsùnwọra, ó sì yọ egungun ìhà kan ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Jèhófà fi egungun ìhà yìí dá obìnrin kan fún Ádámù, obìnrin náà sì di ìyàwó rẹ̀.

Inú Ádámù dùn gan-an nígbà tó rí obìnrin náà! Ó sì dájú pé inú Éfà dùn púpọ̀ láti máa gbé nínú irú ọgbà mèremère bẹ́ẹ̀! Ní báyìí, ó ṣeé ṣe fún wọn láti bí ọmọ kí wọ́n sì máa gbé ní ayọ̀.

Jèhófà fẹ́ kí Ádámù àti Éfà wà láàyè títí láé. Ó fẹ́ kí wọ́n sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di ẹlẹ́wà bí ọgbà Édẹ́nì. Ó dájú pé inú Ádámù àti Éfà ti ní láti dùn púpọ̀ nígbà tí wọ́n ronú nípa ṣíṣe èyí! Ká sọ pé o wà níbẹ̀ nígbà yẹn, ṣé ì bá wu ìwọ náà láti bá wọn lọ́wọ́ sí sísọ ilẹ̀ ayé di ọgbà ẹlẹ́wà? Ṣùgbọ́n, ayọ̀ Ádámù àti Éfà kò wà pẹ́. Jẹ́ ká wo ohun tó fà á.