1. Kí nìdí tó fi yẹ ká sin Ọlọ́run?

Ọlọ́run tòótọ́ ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. Kò ní ìbẹ̀rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò lè ní òpin láé. (Sáàmù 90:2) Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìròyìn ayọ̀ tó wà nínú Bíbélì ti wá. (1 Tímótì 1:11) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló jẹ́ ká wà láàyè, òun nìkan ló yẹ ká máa jọ́sìn.Ka Ìṣípayá 4:11.

2. Irú ẹni wo ni Ọlọ́run?

Kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó tíì rí Ọlọ́run rí torí pé Ẹ̀mí ni, èyí tó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ga ju gbogbo àwọn nǹkan tó dá sí ayé. (Jòhánù 1:18; 4:24) Àmọ́, a lè mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ látinú àwọn nǹkan tó dá. Bí àpẹẹrẹ, onírúurú èso àti òdòdó tí Ọlọ́run dá jẹ́ ká mọ̀ pé ó ní ìfẹ́ àti ọgbọ́n. Bí àgbáyé yìí ṣe tóbi àti bí ojú ọ̀run ṣe lọ salalu jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ní agbára.Ka Róòmù 1:20.

A tún lè mọ púpọ̀ sí i nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ nípa kíka Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ àtàwọn ohun tí kò fẹ́, bó ṣe máa ń ṣe sí àwọn èèyàn àti bó ṣe máa ń ṣe nínú àwọn ipò tó yàtọ̀ síra.Ka Sáàmù 103:7-10.

3. Ṣé Ọlọ́run ní orúkọ?

Jésù sọ pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ orúkọ oyè, orúkọ kan ṣoṣo ló ní. Bí àwọn èèyàn ṣe máa ń pe orúkọ yìí yàtọ̀ láti èdè kan sí òmíràn. Ní èdè Yorùbá, Jèhófà ni a máa ń pè é. Àmọ́ àwọn míì máa ń pè é ní “Yahweh.”Ka Sáàmù 83:18.

Àwọn èèyàn ti yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì, wọ́n sì fi àwọn orúkọ oyè bí Olúwa tàbí Ọlọ́run rọ́pò rẹ̀. Àmọ́, nígbà tí wọ́n kọ Bíbélì, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà ni orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú Bíbélì. Jésù jẹ́  kí àwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run nígbà tó kọ́ wọn nípa Ọlọ́run.Ka Jòhánù 17:26

4. Ǹjẹ́ Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa?

Bíi bàbá onífẹ̀ẹ́ yìí, ohun tó máa ṣe wá láǹfààní títí ayé wa ni Ọlọ́run máa ṣe

Ǹjẹ́ bí ìyà ṣe ń jẹ aráyé fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn? Àwọn kan sọ pé Ọlọ́run ń fi ìyà tó ń jẹ wá dán wa wò ni, àmọ́ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá.Ka Jákọ́bù 1:13.

Ọlọ́run pọ́n àwa èèyàn lé, ó gbà wá láyè pé ká pinnu ohun tó wù wá. Ǹjẹ́ inú wa ò dùn pé Ọlọ́run fún wa láǹfààní pé kí á yàn bóyá a máa sin òun tàbí a ò ní sìn òun? (Jóṣúà 24:15) Àmọ́, ọ̀pọ̀ ló yàn láti máa ṣe ohun tó burú sí àwọn ẹlòmíì, ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń jìyà. Inú Jèhófà kò dùn sí irú ìwà àìtọ́ bẹ́ẹ̀ rárá. Ka Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 6..

Jèhófà Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an ni. Ó fẹ́ ká gbádùn ìgbésí ayé wa dáadáa. Láìpẹ́, ó máa gbà wá lọ́wọ́ ìyà, ó sì máa pa àwọn tó ń fìyà jẹ aráyé run. Àmọ́, ó ní ìdí pàtàkì tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ́ aráyé ní báyìí. A máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó fà á ní Ẹ̀kọ́ 8.Ka 2 Pétérù 2:9; 3:7, 13.

5. Báwo ni a ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run?

Jèhófà ní ká máa gbàdúrà sí òun ká lè sún mọ́ òun. Ó nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. (Sáàmù 65:2; 145:18) Ó ṣe tán láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Ó rí gbogbo bá a sè ń sapá kí á lè ṣe ohun tó wu òun, kódà ó kíyè sí àwọn ìgbà tó bá kù díẹ̀ káàtó fún wa. Torí náà, láìka ti àìpé wa sí, a ṣì lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run.Ka Sáàmù 103:12-14; Jákọ́bù 4:8.

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ló jẹ́ ká wà láàyè, òun ló yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ju ẹnikẹ́ni míì lọ. (Máàkù 12:30) Bó o ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tó o sì ń ṣe ohun tó fẹ́, ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, wàá sì túbọ̀ sún mọ́ ọn.Ka 1 Tímótì 2:4; 1 Jòhánù 5:3.