1. Ibo ni Jésù ti wá?

Àwọn ànímọ́ wo ló jẹ́ kí Jésù ṣe é sún mọ́?MÁTÍÙ 11:29; MÁÀKÙ 10:13-16.

Jésù yàtọ̀ sí ẹ̀dà èèyàn èyíkéyìí, ọ̀run ló ń gbé gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì kó tó di pé ó wá sáyé. (Jòhánù 8:23) Òun ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run láti ṣẹ̀dá àwọn nǹkan yòókù. Òun nìkan ni Jèhófà fọwọ́ ara rẹ̀ dá, torí náà ó bá a mu pé Jésù jẹ́ Ọmọ “bíbí kan ṣoṣo” Ọlọ́run. (Jòhánù 1:14) Jésù tún jẹ́ Agbọ̀rọ̀sọ fún Ọlọ́run, torí bẹ́ẹ̀ ni a ṣe pè é ní “Ọ̀rọ̀ náà.”Ka Òwe 8:22, 23, 30; Kólósè 1:15, 16.

2. Kí nìdí tí Jésù fi wá sáyé?

Bí Ọlọ́run ṣe rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti ọ̀run ni pé, ó fi ìwàláàyè ọmọ náà sínú ilé ọlẹ̀ wúńdíá ọmọbìnrin Júù kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Màríà. Torí náà, Jésù kò ní bàbá tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn. (Lúùkù 1:30-35) Jésù wá sí ayé (1) kí ó lè kọ́ wa ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run, (2) kí ó lè fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa nípa bá a ṣe lè máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kódà nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro, àti pé (3) kí ó lè fi ìwàláàyè rẹ̀ pípé fún wa gẹ́gẹ́ bí “ìràpadà.”Ka Mátíù 20:28.

3. Kí nìdí tá a fi nílò ìràpadà?

Ìràpadà ni ohun téèyàn san láti gba ẹnì kan sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú. (Ẹ́kísódù 21:29, 30) Ọjọ́ ogbó àti ikú kò sí lára ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Ọlọ́run sọ fún ọkùnrin àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù, pé tí ó bá dá “ẹ̀ṣẹ̀,” ó máa kú. Torí náà, ká sọ pé Ádámù kò dẹ́ṣẹ̀ ni, kò ní kú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 5:5) Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ipasẹ̀ Ádámù ni ikú gbà “wọ” ayé. Nípa bẹ́ẹ̀, ogún tí Ádámù fún gbogbo ọmọ rẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tó jẹ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀. Torí  náà, a nílò ìràpadà, ká lè bọ́ lọ́wọ́ ikú tá a jogún lọ́dọ̀ Ádámù.Ka Róòmù 5:12; 6:23.

Ta ló lè san ìràpadà tó máa jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ ikú? Tá a bá ti kú, ìyà tó tọ́ sí wa fún ẹ̀ṣẹ̀ wa la san yẹn. Kò sí èèyàn aláìpé kan tó lè san ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíì.Ka Sáàmù 49:7-9.

4. Kí nìdí tí Jésù fi kú?

Ẹni pípé ni Jésù, kò dà bí àwa èèyàn. Kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan, torí náà kò sídìí tó fi yẹ kí ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jésù kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn míì. Ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tí Ọlọ́run ní fún aráyé ló mú kí ó rán Ọmọ rẹ̀ pé kí ó wá kú nítorí wa. Jésù pẹ̀lú fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa bó ṣe ṣègbọràn sí Baba rẹ̀ tó sì wá kú nítorí wa.Ka Jòhánù 3:16; Róòmù 5:18, 19.

5. Kí ni Jésù ń ṣe báyìí?

Nígbà tí Jésù wà láyé, ó wo àwọn aláìsàn sàn, ó jí òkú dìde, ó sì dá àwọn tó wà nínú ìṣòro nídè. Ó tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí á mọ ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú fún gbogbo èèyàn tó bá jẹ́ onígbọràn. (Mátíù 15:30, 31; Jòhánù 5:28) Lẹ́yìn tí Jésù kú, Ọlọ́run jí i dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí, ó sì pa dà sí ọ̀run. (1 Pétérù 3:18) Jésù wá wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run títí Jèhófà fi fún un ní àṣẹ pé kí ó máa ṣàkóso gbogbo ayé. (Hébérù 10:12, 13) Ní báyìí, Jésù jẹ́ Ọba tó ń ṣàkóso ní ọ̀run, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń kéde ìròyìn ayọ̀ yìí kárí ayé.Ka Dáníẹ́lì 7:13, 14; Mátíù 24:14.

Láìpẹ́, Jésù yóò lo ọlá àṣẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba láti fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé yóò sì pa àwọn ẹni ibi run. Gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù nípa ṣíṣègbọràn sí i yóò rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.Ka Sáàmù 37:9-11.