Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!

 Ẹ̀kọ́ 12

Báwo Lo Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run?

Báwo Lo Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run?

1. Ǹjẹ́ gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń gbọ́?

Ọlọ́run ń pe àwọn èèyàn láti orílẹ̀-èdè gbogbo pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí òun kí wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ sún mọ́ òun. (Sáàmù 65:2) Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run kò ní gbọ́ àdúrà ọkùnrin tó bá ń hùwà tí kò dára sí ìyàwó rẹ̀. (1 Pétérù 3:7) Bákan náà, Ọlọ́run kọ̀ láti gbọ́ àdúrà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí ìwà búburú tí wọ́n ń hù. Ó ṣe kedere nígbà náà pé àǹfààní ńlá ni àdúrà jẹ́. Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì pàápàá bí wọ́n bá ronú pìwà dà. Ka Aísáyà 1:15; 55:7.

2. Báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà?

Ara ìjọsìn wa ni àdúrà jẹ́, torí náà Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa nìkan ló yẹ kí á máa gbàdúrà sí. (Mátíù 4:10; 6:9) Bákan náà, níwọ̀n bá a ti jẹ́ aláìpé, ó yẹ ká máa gbàdúrà ní orúkọ Jésù nítorí pé ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa. (Jòhánù 14:6) Jèhófà kò fẹ́ ká máa lo àwọn ọ̀rọ̀ àkọ́sórí nínú àdúrà wa tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sínú ìwé. Ọlọ́run fẹ́ kí á máa gbàdúrà látọkàn wá. Ka Mátíù 6:7; Fílípì 4:6, 7.

Ẹlẹ́dàá wa lè gbọ́ àwọn àdúrà tá a gbà nínú ọkàn wa pàápàá. (1 Sámúẹ́lì 1:12, 13) Ó rọ̀ wá pé ká máa gbàdúrà nígbàkigbà, bí àpẹẹrẹ láàárọ̀ àti lálẹ́, nígbà tá a bá fẹ́ jẹun àti nígbà tá a bá dojú kọ ìṣòro. Ka Sáàmù 55:22; Mátíù 15:36.

3. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni fi máa ń lọ sípàdé?

Kò rọrùn rárá láti sún mọ́ Ọlọ́run torí pé àárín àwọn èèyàn tí kò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run là ń gbé, wọn ò sì gbà pé òótọ́ ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé àlàáfíà ń bọ̀ wá jọba láyé.  (2 Tímótì 3:1, 4; 2 Pétérù 3:3, 13) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, ìyẹn á sì jẹ́ kí tọ̀tún tòsì wa lè fún ara wa níṣìírí. Ka Hébérù 10:24, 25.

Tá a bá ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, èyí á mú ká lè sún mọ́ Ọlọ́run. Àwọn tó ń wá sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń jàǹfààní látinú ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíì. Ka Róòmù 1:11, 12.

4. Báwo lo ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run?

O lè sún mọ́ Jèhófà nípa ṣíṣe àṣàrò lórí àwọn ohun tó o kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ronú lórí àwọn ohun tó ṣe, ìmọ̀ràn rẹ̀ àti àwọn ìlérí rẹ̀. Tá a bá ń gbàdúrà tá a sì ń ṣe àṣàrò, èyí á mú ká mọyì ìfẹ́ àti ọgbọ́n Ọlọ́run. Ka Jóṣúà 1:8; Sáàmù 1:1-3.

Àyàfi tó o bá gbọ́kàn lé Ọlọ́run, tó o sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ nìkan lo tó lè sún mọ́ ọn. Àmọ́, ńṣe ni ìgbàgbọ́ dà bí irúgbìn tó jẹ́ pé èèyàn gbọ́dọ̀ máa bomi rin déédéé kí ó lè máa dàgbà. Bákan náà, o gbọ́dọ̀ máa bomi rin ìgbàgbọ́ rẹ nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé kó o sì máa ronú lórí ìdí tó o fi gbà pé òótọ́ ni àwọn ohun tó o gbà gbọ́. Ka Mátíù 4:4; Hébérù 11:1, 6.

5. Àǹfààní wo ni wàá rí tó o bá sún mọ́ Ọlọ́run?

Jèhófà máa ń bójú tó àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó lè dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ohunkóhun tó lè jin ìgbàgbọ́ wọn lẹ́sẹ̀ tó sì lè mú kí wọ́n pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun. (Sáàmù 91:1, 2, 7-10) Ó kìlọ̀ fún wa pé kí á ṣọ́ra fún àwọn ìwà àti ìṣe tó lè ṣàkóbá fún ìlera wa àti èyí tó lè mú ká pàdánù ayọ̀ wa. Jèhófà ń kọ́ wa ní ọ̀nà tó dára jù láti lo ìgbésí ayé wa. Ka Sáàmù 73:27, 28; Jákọ́bù 4:4, 8.