Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!

 Ẹ̀kọ́ 10

Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ẹ̀sìn Tòótọ́?

Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ẹ̀sìn Tòótọ́?

1. Ǹjẹ́ ẹ̀sìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà?

“Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké.”MÁTÍÙ 7:15.

Ẹ̀sìn kan ṣoṣo ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ìyẹn sì ni ẹ̀sìn tòótọ́. Ó dà bí ọ̀nà téèyàn lè tọ̀ láti rí ìyè àìnípẹ̀kun. Jésù sọ pé: “Díẹ̀ . . . ni àwọn tí ń rí” ọ̀nà náà. (Mátíù 7:14) Ìjọsìn tó bá Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu nìkan ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. Ìgbàgbọ́ kan ṣoṣo tí gbogbo àwọn olùjọsìn tòótọ́ ní mú kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan.Ka Jòhánù 4:23, 24; 14:6; Éfésù 4:4, 5.

2. Kí ni Jésù sọ nípa àwọn èké Kristẹni?

“Wọ́n polongo ní gbangba pé àwọn mọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ wọn.”TÍTÙ 1:16.

Jésù kìlọ̀ pé àwọn wòlíì èké máa sọ ẹ̀sìn Kristẹni dìbàjẹ́. Wọ́n máa ń fara hàn lóde bíi pé olùjọsìn tòótọ́ ni wọ́n. Àwọn tó ń lọ ṣọ́ọ̀ṣì wọn máa ń sọ pé Kristẹni ni àwọn. Àmọ́, ohun tí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ gan-an ni wàá fi dá wọn mọ̀. Lọ́nà wo? Ìjọsìn tòótọ́ nìkan ló máa ń mú kéèyàn jẹ́ Kristẹni tòótọ́ tí àwọn èèyàn á sì rí i nínú ìwà àti ìṣe ẹni.Ka Mátíù 7:13-23.

3. Báwo lo ṣe lè dá àwọn olùjọsìn tòótọ́ mọ̀?

Wo àwọn kókó márùn-ún yìí téèyàn lè fi dá wọn mọ̀:

  • Àwọn olùjọsìn tòótọ́ gbà gbọ́ pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n máa ń sapá láti fi àwọn ìlànà inú rẹ̀ sílò. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀sìn tòótọ́ yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀sìn tó jẹ́ pé ọgbọ́n orí àwọn èèyàn ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé. (Mátíù 15:7-9)  Àwọn olùjọsìn tòótọ́ kì í sọ ohun kan kí wọ́n wá máa ṣe ohun mìíràn.Ka Jòhánù 17:17; 2 Tímótì 3:16, 17.

  • Àwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ Jèhófà. Jésù bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run ni tí pé ó jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ náà. Ó jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run, ó sì kọ́ wọn pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. (Mátíù 6:9) Ní àdúgbò rẹ, ẹ̀sìn wo ló ń jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run? Ka Jòhánù 17:26; Róòmù 10:13, 14.

  • Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ọlọ́run rán Jésù pé kí ó wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ìjọba Ọlọ́run nìkan ni ìrètí tí aráyé ní. Títí dé ojú ikú ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Lúùkù 4:43; 8:1; 23:42, 43) Ó sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun náà máa wàásù Ìjọba yìí. Tí ẹnì kan bá pàdé rẹ tó sì ń bá ọ sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ẹ̀sìn wo ni wàá sọ pé onítọ̀hún ń ṣe?Ka Mátíù 24:14.

  • Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kì í ṣe apá kan ayé búburú yìí. Ara ohun tó o lè fi dá wọn mọ̀ ni pé wọn kì í dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú tàbí rúkèrúdò tó ń lọ láàárín àwọn èèyàn. (Jòhánù 17:16; 18:36) Bákan náà, wọn kì í lọ́wọ́ sí àwọn àṣàkaṣà àti ìwàkiwà tó kún inú ayé yìí.Ka Jákọ́bù 4:4.

  • Àwọn Kristẹni tòótọ́ ní ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ fún ara wọn. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún gbogbo èèyàn láìka ẹ̀yà tí wọ́n ti wá sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé torí tọrùn ni àwọn ẹ̀sìn èké fi máa ń ti àwọn orílẹ̀-èdè tó ń jagun lẹ́yìn, àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ní tiwọn. (Míkà 4:1-3) Kàkà bẹ́ẹ̀, tinútinú ni àwọn Kristẹni tòótọ́ fi máa ń lo àkókò wọn àti ohun ìní wọn láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n sì fún wọn lókun.Ka Jòhánù 13:34, 35; 1 Jòhánù 4:20.

4. Ǹjẹ́ o lè dá ẹ̀sìn tòótọ́ mọ̀?

Ẹ̀sìn wo ló jẹ́ pé inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni gbogbo ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni ti wá? Ẹ̀sìn wo ló ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run, tó sì ń kéde pé Ìjọba Ọlọ́run ni ìrètí kan ṣoṣo tí aráyé ní? Àwọn onísìn wo ló nífẹ̀ẹ́ ara wọn tí wọn kì í sì í lọ́wọ́ nínú ogun? Kí ni ìwọ rò? Ka 1 Jòhánù 3:10-12.

 

Mọ Púpọ̀ Sí I

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

Ìjọsìn Tó Ní Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run

Wo ohun mẹ́fà téèyàn lè fi dá àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ mọ̀.